I. A. Ọba 2:1-4
I. A. Ọba 2:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌJỌ Dafidi si sunmọ etile ti yio kú: o si paṣẹ fun Solomoni, ọmọ rẹ̀ pe: Emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: nitorina mu ara rẹ le, ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ọkunrin. Ki o si pa ilana Oluwa, Ọlọrun rẹ mọ, lati ma rin li ọ̀na rẹ̀, lati pa aṣẹ rẹ̀ mọ, ati ofin rẹ̀, ati idajọ, rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ gẹgẹ bi a ti kọ ọ ni ofin Mose, ki iwọ ki o lè ma pọ̀ si i ni ohun gbogbo ti iwọ o ṣe, ati nibikibi ti iwọ ba yi ara rẹ si. Ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ duro ti o ti sọ niti emi pe: Bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati mã fi gbogbo aiya wọn, ati gbogbo ọkàn wọn, rìn niwaju mi li otitọ, (o wipe), a kì yio fẹ ọkunrin kan kù fun ọ lori itẹ Israeli.
I. A. Ọba 2:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó kù dẹ̀dẹ̀ kí Dafidi jáde láyé, ó pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó sì kìlọ̀ fún un pé, “Ó tó àkókò fún mi, láti lọ sí ibi tí àgbà ń rè. Mú ọkàn gírí kí o sì ṣe bí ọkunrin. Ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ pé kí o ṣe, máa tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ sinu ìwé òfin Mose, kí gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lè máa yọrí sí rere, níbikíbi tí o bá n lọ. Bí o bá ń gbọ́ ti OLUWA, OLUWA yóo pa ìlérí tí ó ṣe nípa mi mọ́, pé arọmọdọmọ mi ni yóo máa jọba ní Israẹli níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá pa òfin òun mọ tọkàntọkàn, pẹlu òtítọ́ inú.
I. A. Ọba 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ọjọ́ ikú Dafidi súnmọ́ etílé, ó pàṣẹ fún Solomoni ọmọ rẹ̀. Ó sì wí pé, “Èmi ti fẹ́ lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé, nítorí náà jẹ́ alágbára kí o sì fi ara rẹ hàn bí ọkùnrin, kí o sì wòye ohun tí OLúWA Ọlọ́run rẹ béèrè, rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o sì pa àṣẹ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti ìdájọ́ rẹ, àti ẹ̀rí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé òfin Mose, nítorí kí ìwọ kí ó le è máa ṣe rere ní ohun gbogbo tí ìwọ ṣe, àti ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, kí OLúWA kí ó lè pa ìlérí rẹ̀ tí ó sọ nípa tèmi mọ́ pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá kíyèsi ọ̀nà wọn, tí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà wọn àti ọkàn wọn rìn níwájú mi ní òtítọ́, o kì yóò sì kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’