ÀWỌN ỌBA KINNI 2

2
Ìkìlọ̀ Ìkẹyìn Tí Dafidi ṣe fún Solomoni
1Nígbà tí ó kù dẹ̀dẹ̀ kí Dafidi jáde láyé, ó pe Solomoni, ọmọ rẹ̀, ó sì kìlọ̀ fún un pé, 2“Ó tó àkókò fún mi, láti lọ sí ibi tí àgbà ń rè. Mú ọkàn gírí kí o sì ṣe bí ọkunrin. 3Ṣe gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun rẹ pa láṣẹ fún ọ pé kí o ṣe, máa tẹ̀lé ọ̀nà rẹ̀, sì pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ sinu ìwé òfin Mose, kí gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lè máa yọrí sí rere, níbikíbi tí o bá n lọ. 4Bí o bá ń gbọ́ ti OLUWA, OLUWA yóo pa ìlérí tí ó ṣe nípa mi mọ́, pé arọmọdọmọ mi ni yóo máa jọba ní Israẹli níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá pa òfin òun mọ tọkàntọkàn, pẹlu òtítọ́ inú.
5“Siwaju sí i, ranti ohun tí Joabu ọmọ Seruaya ṣe sí mi, tí ó pa àwọn ọ̀gágun Israẹli meji: Abineri ọmọ Neri ati Amasa ọmọ Jeteri. Ranti pé ní àkókò tí kò sí ogun ni ó pa wọ́n; tí ó fi gbẹ̀san ikú ẹni tí wọ́n pa ní àkókò ogun. Pípa tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀ wọnyi, ọrùn mi ni ó pa wọ́n sí, ẹrù ẹ̀bi wọn sì wà lórí mi.#a 2Sam 3:27 b 2Sam 20:10 6Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú.
7“Ṣugbọn òtítọ́ inú ni kí o máa fi bá àwọn ọmọ Basilai ará Gileadi lò. Jẹ́ kí wọ́n wà lára àwọn tí yóo máa bá ọ jẹun pọ̀, nítorí pé òótọ́ inú ni wọ́n fi wá pàdé mi ní àkókò tí mò ń sá lọ fún Absalomu, arakunrin rẹ.#2Sam 17:27-29
8“Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ṣimei ọmọ Gera ará Bahurimu láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, èpè burúkú ni ó ń gbé mi ṣẹ́ lemọ́lemọ́ ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Ṣugbọn nígbà tí ó wá pàdé mi létí odò Jọdani, mo jẹ́jẹ̀ẹ́ fún un ní orúkọ OLUWA pé, n kò ní pa á.#2Sam 16:5-13; 19:16-23 9Ṣugbọn o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó lọ láìjìyà. Ìwọ náà mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n ọmọ, o kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó fi ọwọ́ rọrí kú.”
Ikú Dafidi
10Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Dafidi, ọba kú, wọ́n sì sin ín sí ìlú Dafidi. 11Ogoji ọdún ni ó fi jọba Israẹli. Ó ṣe ọdún meje lórí oyè ní Heburoni, ó sì ṣe ọdún mẹtalelọgbọn ní Jerusalẹmu.#2Sam 5:4-5; 1Kron 3:4 12Solomoni gorí oyè lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọningbọnin.#1Kron 29:23
Ikú Adonija
13Ní ọjọ́ kan, Adonija ọmọ Hagiti, lọ sí ọ̀dọ̀ Batiṣeba, ìyá Solomoni. Batiṣeba bá bèèrè pé, “Ṣé alaafia ni o?”
Adonija dá a lóhùn pé, “Alaafia ni, 14kinní kan ni mo fẹ́ bá ọ sọ.”
Batiṣeba bi í pé, “Kí ni?”
15Ó bá dá Batiṣeba lóhùn pé, “Ṣé o mọ̀ pé èmi ni ó yẹ kí n jọba, ati pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n lérò pé èmi ni n óo jọba. Ṣugbọn kò rí bẹ́ẹ̀, arakunrin mi ló jọba, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó wu OLUWA. 16Kinní kan ni mo wá fẹ́ tọrọ, jọ̀wọ́, má fi kinní ọ̀hún dù mí.”
Batiṣeba bá bi í pé, “Kí ni nǹkan náà?”
17Ó bá dá Batiṣeba lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́ bá mi bẹ Solomoni ọba, kí ó fún mi ní Abiṣagi, ará Ṣunemu, kí n fi ṣe aya. Mo mọ̀ pé kò ní kọ̀ sí ọ lẹ́nu.”#1A. Ọba 1:3-4
18Batiṣeba bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọba sọ̀rọ̀.”
19Batiṣeba bá lọ sọ́dọ̀ ọba láti jíṣẹ́ Adonija fún un. Bí ó ti wọlé, ọba dìde, ó tẹríba fún ìyá rẹ̀, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó bá tún jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó ní kí wọ́n gbé ìjókòó kan wá, ìyá rẹ̀ sì jókòó ní apá ọ̀tún rẹ̀. 20Batiṣeba wí fún Solomoni pé, “Nǹkan kékeré kan ni mo fẹ́ tọrọ lọ́wọ́ rẹ, jọ̀wọ́, má fi ohun náà dù mi.”
Ọba bèèrè pé, “Kí ni, ìyá mi?” Ó sì fi kún un pé òun kò ní fi dù ú.
21Batiṣeba dá a lóhùn pé, “Fi Abiṣagi, ará Ṣunemu fún Adonija arakunrin rẹ, kí ó fi ṣe aya.”
22Ọba bá bi ìyá rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún un ní Abiṣagi nìkan? Ò bá kúkú ní kí n dìde fún un lórí ìtẹ́ tí mo wà yìí. Ṣebí òun ni ẹ̀gbọ́n mi, ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni Abiatari alufaa ati Joabu ọmọ Seruaya wà.” 23Solomoni bá búra lórúkọ OLUWA pé, kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá pa Adonija nítorí ọ̀rọ̀ yìí. 24Ó ní, “Mo fi orúkọ OLUWA alààyè búra, ẹni tí ó gbé mi ka orí ìtẹ́ Dafidi baba mi tí ó fi ìdí mi múlẹ̀, tí ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì fi ìjọba náà fún èmi ati arọmọdọmọ mi, lónìí olónìí ni Adonija yóo kú.”
25Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, pé kí ó lọ pa Adonija, ó bá jáde, ó sì lọ pa á.
Wọ́n Lé Abiatari kúrò ní Ìlú, Wọ́n Sì Pa Joabu
26Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba sọ fún Abiatari alufaa, pé, “Wá pada lọ sí orí ilẹ̀ rẹ ní Anatoti, pípa ni ó yẹ kí n pa ọ́, ṣugbọn n kò ní pa ọ́ nisinsinyii, nítorí pé ìwọ ni o jẹ́ alákòóso fún gbígbé Àpótí Ẹ̀rí káàkiri nígbà tí o wà pẹlu Dafidi, baba mi, o sì bá baba mi pín ninu gbogbo ìṣòro rẹ̀.”#a 2Sam 15:24 b 1 Sam 22:20-23 27Solomoni bá yọ Abiatari kúrò ninu iṣẹ́ alufaa OLUWA tí ó ń ṣe, ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ ní Ṣilo ṣẹ, nípa Eli alufaa ati arọmọdọmọ rẹ̀.#1 Sam 2:27-36
28Nígbà tí Joabu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó sì di ìwo pẹpẹ mú, nítorí pé lẹ́yìn Adonija ni ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí lẹ́yìn Absalomu. 29Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Joabu ti sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ati pé ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, Solomoni rán Bẹnaya kí ó lọ pa á. 30Bẹnaya bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó wí fún Joabu pé, “Ọba pàṣẹ pé kí o jáde.”
Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn, ó ní, “Rárá, níhìn-ín ni n óo kú sí.”
Bẹnaya bá pada lọ sọ ohun tí Joabu wí fún ọba.
31Ọba dá a lóhùn pé, “Ṣe bí Joabu ti ní kí o ṣe. Pa á, kí o sì sin ín. Nígbà náà ni ọrùn èmi, ati arọmọdọmọ Dafidi yóo tó mọ́ kúrò ninu ohun tí Joabu ṣe nígbà tí ó pa àwọn aláìṣẹ̀. 32OLUWA yóo jẹ Joabu níyà fún àwọn eniyan tí ó pa láìjẹ́ pé Dafidi baba mí mọ ohunkohun nípa rẹ̀. Ó pa Abineri, ọmọ Neri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Israẹli ati Amasa, ọmọ Jeteri, ọ̀gágun àwọn ọmọ ogun Juda. Àwọn mejeeji tí ó pa láìṣẹ̀ yìí ṣe olóòótọ́ ju òun pàápàá lọ. 33Ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ó pa yóo wà lórí rẹ̀ ati lórí àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ títí lae, ṣugbọn OLUWA yóo fún Dafidi ati àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ ati ilé rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀ ní alaafia títí lae.”
34Bẹnaya ọmọ Jehoiada bá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, ó pa Joabu, wọn sì sin ín sinu ilé rẹ̀ ninu aṣálẹ̀. 35Ọba fi Bẹnaya jẹ balogun rẹ̀ dípò Joabu, ó sì fi Sadoku jẹ alufaa dípò Abiatari.
Ikú Ṣimei
36Lẹ́yìn náà, ọba ranṣẹ pe Ṣimei, ó wí fún un pé, “Kọ́ ilé kan sí Jerusalẹmu níhìn-ín kí o sì máa gbé ibẹ̀. O kò gbọdọ̀ jáde lọ sí ibìkankan. 37Ọjọ́ tí o bá jáde kọjá odò Kidironi, pípa ni n óo pa ọ́, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóo sì wà lórí ara rẹ.”
38Ṣimei dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ ni ó dára, oluwa mi, bí o ti wí ni èmi iranṣẹ rẹ yóo sì ṣe.” Ṣimei sì wà ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́.
39Lẹ́yìn ọdún mẹta, àwọn ẹrú Ṣimei meji kan sá lọ sí ọ̀dọ̀ Akiṣi, ọmọ Maaka, ọba ìlú Gati. Nígbà tí Ṣimei gbọ́ pé àwọn ẹrú rẹ̀ yìí wà ní Gati, 40ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kan ní gàárì, ó sì tọ Akiṣi ọba lọ sí ìlú Gati láti lọ wá àwọn ẹrú rẹ̀. Ó rí wọn, ó sì mú àwọn mejeeji pada wá sí ilé. 41Nígbà tí Solomoni gbọ́ pé Ṣimei ti kúrò ní Jerusalẹmu, ó ti lọ sí Gati, ó sì ti pada, 42ó ranṣẹ pè é, ó bi í pé, “Ṣebí o búra fún mi ní orúkọ OLUWA pé o kò ní jáde kúrò ní Jerusalẹmu? Mo sì kìlọ̀ fún ọ pé, ní ọjọ́ tí o bá jáde, pípa ni n óo pa ọ́. O gbà bẹ́ẹ̀, o sì ṣèlérí fún mi pé o óo pa òfin náà mọ́. 43Kí ló dé tí o kò mú ìlérí rẹ fún OLUWA ṣẹ, tí o sì rú òfin mi?” 44Dájúdájú o mọ gbogbo ibi tí o ṣe sí Dafidi, baba mi; OLUWA yóo jẹ ọ́ níyà ohun tí o ṣe. 45Ṣugbọn OLUWA yóo bukun mi, yóo sì fi ẹsẹ̀ ìjọba Dafidi múlẹ̀ títí lae.
46Solomoni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, pé kí ó lọ pa Ṣimei; Bẹnaya bá jáde lọ, ó sì pa á. Lẹ́yìn náà ni gbogbo ìjọba Solomoni ọba wá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KINNI 2: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀