I. A. Ọba 19:3-18
I. A. Ọba 19:3-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si bẹ̀ru, o si dide, o si lọ fun ẹmi rẹ̀, o si de Beerṣeba ti Juda, o si fi ọmọ-ọdọ rẹ̀ silẹ nibẹ. Ṣugbọn on tikararẹ̀ lọ ni irin ọjọ kan si aginju, o si wá, o si joko labẹ igi juniperi kan, o si tọrọ fun ara rẹ̀ ki on ba le kú; o si wipe, O to; nisisiyi, Oluwa, gba ẹmi mi kuro nitori emi kò sàn jù awọn baba mi lọ! Bi o si ti dùbulẹ ti o si sùn labẹ igi juniperi kan, si wò o, angeli fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wi fun u pe, Dide, jẹun. O si wò, si kiyesi i, àkara ti a din lori ẹyin iná, ati orù-omi lẹba ori rẹ̀: o si jẹ, o si mu, o si tun dùbulẹ. Angeli Oluwa si tun pada wá lẹrinkeji, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wipe, Dide, jẹun; nitoriti ọ̀na na jìn fun ọ. O si dide, o si jẹ, o mu, o si lọ li agbara onjẹ yi li ogoji ọsan ati ogoji oru si Horebu, oke Ọlọrun. O si de ibẹ̀, si ibi ihò okuta, o si wọ̀ sibẹ, si kiyesi i, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ nṣe nihinyi, Elijah? On si wipe, Ni jijowu emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ: ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù, nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. O si wipe, Jade lọ, ki o si duro lori oke niwaju Oluwa. Si kiyesi i, Oluwa kọja, ìji nla ati lile si fà awọn oke nla ya, o si fọ́ awọn apata tũtu niwaju Oluwa; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iji na: ati lẹhin iji na, isẹlẹ; ṣugbọn Oluwa kò si ninu isẹlẹ na. Ati lẹhin isẹlẹ na, iná; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iná na, ati lẹhin iná na, ohùn kẹ́lẹ kekere. O si ṣe, nigbati Elijah gbọ́, o si fi agbáda rẹ̀ bo oju rẹ̀, o si jade lọ, o duro li ẹnu iho okuta na. Si kiyesi i, ohùn kan tọ̀ ọ wá wipe, Kini iwọ nṣe nihinyi Elijah? On si wipe, Ni jijowu, emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ; ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù; nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro. Oluwa si wi fun u pe, Lọ, pada li ọ̀na rẹ, kọja li aginju si Damasku: nigbati iwọ ba de ibẹ, ki o si fi ororo yan Hasaeli li ọba lori Siria. Ati Jehu, ọmọ Nimṣi ni iwọ o fi ororo yàn li ọba lori Israeli: ati Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ara Abel-Mehola ni iwọ o fi ororo yan ni woli ni ipò rẹ. Yio si ṣe, ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Hasaeli ni Jehu yio pa, ati ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Jehu ni Eliṣa yio pa. Ṣugbọn emi ti kù ẹ̃dẹgbarin enia silẹ fun ara mi ni Israeli, gbogbo ẽkun ti kò tii kunlẹ fun Baali, ati gbogbo ẹnu ti kò iti fi ẹnu kò o li ẹnu.
I. A. Ọba 19:3-18 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀rù ba Elija, ó sì sá fún ikú. Ó lọ sí Beeriṣeba, ní ilẹ̀ Juda. Ó fi iranṣẹ rẹ̀ sibẹ, ṣugbọn òun alára wọ inú ijù lọ ní ìrìn odidi ọjọ́ kan kí ó tó dúró. Ó bá jókòó lábẹ́ ìbòòji igi kan, ó wo ara rẹ̀ bíi kí òun kú. Ó sì gbadura sí OLUWA pé, “OLUWA, ó tó gẹ́ẹ́ báyìí! Kúkú pa mí. Kí ni mo fi sàn ju àwọn baba mi lọ?” Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi náà, ó sì sùn. Lójijì, angẹli kan fi ọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun.” Ó wò yíká, ó sì rí ìṣù àkàrà kan, ati ìkòkò omi kan lẹ́bàá ìgbèrí rẹ̀. Ó jẹun, ó mu omi, ó sì tún dùbúlẹ̀. Angẹli OLUWA náà pada wa, ó jí i, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun, kí ìrìn àjò náà má baà pọ̀jù fún ọ.” Elija dìde, ó jẹun, ó sì tún mu omi. Oúnjẹ náà sì fún un ní agbára láti rìn fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru títí tí ó fi dé orí òkè Horebu, òkè Ọlọrun. Ó dé ibi ihò àpáta kan, ó sì sùn níbẹ̀ mọ́jú ọjọ́ keji. OLUWA bá a sọ̀rọ̀, ó bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?” Elija dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí ìwọ OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti kọ majẹmu rẹ tì, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.” OLUWA wí fún un pé, “Lọ dúró níwájú mi ní orí òkè yìí.” OLUWA ba kọjá lọ, ẹ̀fúùfù líle kán fẹ́, ó la òkè náà, ó sì fọ́ àwọn òkúta rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ níwájú OLUWA. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ẹ̀fúùfù líle náà. Lẹ́yìn ẹ̀fúùfù náà, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹ̀, gbogbo ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, iná ńlá kan bẹ̀rẹ̀ sí jó. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu iná náà. Lẹ́yìn iná náà, ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan rọra sọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́. Nígbà tí Elija gbọ́ ohùn náà, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ bojú, ó jáde, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ihò àpáta náà. Ohùn kan bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?” Ó bá dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti da majẹmu rẹ̀, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ̀. Èmi nìkan ṣoṣo, ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.” OLUWA dá a lóhùn pé, “Pada lọ sinu aṣálẹ̀ ẹ̀bá Damasku. Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, fi àmì òróró yan Hasaeli ní ọba Siria. Yan Jehu, ọmọ Nimṣi, ní ọba Israẹli, kí o sì yan Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ará Abeli Mehola, ní wolii dípò ara rẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ lọ́wọ́ idà Hasaeli, Jehu ni yóo pa á, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì bọ́ lọ́wọ́ idà Jehu, Eliṣa ni yóo pa á. Sibẹsibẹ n óo dá ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan sí, ní ilẹ̀ Israẹli: àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí mi, tí wọn kò tíì kúnlẹ̀ fún oriṣa Baali, tabi kí wọ́n fi ẹnu wọn kò ó lẹ́nu.”
I. A. Ọba 19:3-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Elijah sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Beerṣeba ti Juda, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, nígbà tí òun tìkára rẹ̀ sì lọ ní ìrìn ọjọ́ kan sí aginjù, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, OLúWA, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ” Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ. Sì wò ó, angẹli fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí o jẹun.” Ó sì wò ó yíká, àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yín iná, àti orù-omi wà lẹ́bàá orí rẹ̀. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì tún dùbúlẹ̀. Angẹli OLúWA sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jì fún ọ.” Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run. Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀. OLúWA Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Elijah wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Elijah?” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.” OLúWA sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú OLúWA, nítorí OLúWA fẹ́ rékọjá.” Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú OLúWA; ṣùgbọ́n OLúWA kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n OLúWA kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n OLúWA kò sí nínú iná náà. Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá. Nígbà tí Elijah sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà. Nígbà náà ni ohùn kan tọ̀ ọ́ wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín, Elijah?” Ó sì dáhùn pé, “Èmi ti ń jowú fún OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí.” OLúWA sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀nà tí ìwọ ti wá, kí o sì lọ sí aginjù Damasku. Nígbà tí ìwọ bá dé ibẹ̀, fi òróró yan Hasaeli ní ọba lórí Aramu. Tún fi òróró yan Jehu ọmọ Nimṣi ní ọba lórí Israẹli, àti kí o fi òróró yan Eliṣa ọmọ Ṣafati, ará Abeli-Mehola ní wòlíì ní ipò rẹ. Jehu yóò pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Hasaeli, Eliṣa yóò sì pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Jehu. Síbẹ̀, èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Israẹli, àní gbogbo eékún tí kò ì tí ì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Baali, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.”