ÀWỌN ỌBA KINNI 19

19
Elija, lórí Òkè Sinai
1Ahabu ọba sọ gbogbo ohun tí Elija ṣe fún Jesebẹli, aya rẹ̀, ati bí ó ti pa gbogbo wolii oriṣa Baali. 2Jesebẹli bá rán oníṣẹ́ kan sí Elija pẹlu ìbúra pé, “Kí àwọn oriṣa pa mí, bí n kò bá pa ọ́ ní ìwòyí ọ̀la, bí o ti pa àwọn wolii Baali.” 3Ẹ̀rù ba Elija, ó sì sá fún ikú. Ó lọ sí Beeriṣeba, ní ilẹ̀ Juda.
Ó fi iranṣẹ rẹ̀ sibẹ, 4ṣugbọn òun alára wọ inú ijù lọ ní ìrìn odidi ọjọ́ kan kí ó tó dúró. Ó bá jókòó lábẹ́ ìbòòji igi kan, ó wo ara rẹ̀ bíi kí òun kú. Ó sì gbadura sí OLUWA pé, “OLUWA, ó tó gẹ́ẹ́ báyìí! Kúkú pa mí. Kí ni mo fi sàn ju àwọn baba mi lọ?”#Jona 4:3
5Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi náà, ó sì sùn. Lójijì, angẹli kan fi ọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun.” 6Ó wò yíká, ó sì rí ìṣù àkàrà kan, ati ìkòkò omi kan lẹ́bàá ìgbèrí rẹ̀. Ó jẹun, ó mu omi, ó sì tún dùbúlẹ̀. 7Angẹli OLUWA náà pada wa, ó jí i, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun, kí ìrìn àjò náà má baà pọ̀jù fún ọ.” 8Elija dìde, ó jẹun, ó sì tún mu omi. Oúnjẹ náà sì fún un ní agbára láti rìn fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru títí tí ó fi dé orí òkè Horebu, òkè Ọlọrun. 9Ó dé ibi ihò àpáta kan, ó sì sùn níbẹ̀ mọ́jú ọjọ́ keji.
OLUWA bá a sọ̀rọ̀, ó bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?”
10Elija dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí ìwọ OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti kọ majẹmu rẹ tì, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.”#Rom 11:3
11OLUWA wí fún un pé, “Lọ dúró níwájú mi ní orí òkè yìí.” OLUWA ba kọjá lọ, ẹ̀fúùfù líle kán fẹ́, ó la òkè náà, ó sì fọ́ àwọn òkúta rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ níwájú OLUWA. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ẹ̀fúùfù líle náà. Lẹ́yìn ẹ̀fúùfù náà, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹ̀, gbogbo ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ìṣẹ̀lẹ̀ náà. 12Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, iná ńlá kan bẹ̀rẹ̀ sí jó. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu iná náà. Lẹ́yìn iná náà, ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan rọra sọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́.
13Nígbà tí Elija gbọ́ ohùn náà, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ bojú, ó jáde, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ihò àpáta náà. Ohùn kan bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?”
14Ó bá dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti da majẹmu rẹ̀, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ̀. Èmi nìkan ṣoṣo, ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.”
15OLUWA dá a lóhùn pé, “Pada lọ sinu aṣálẹ̀ ẹ̀bá Damasku. Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, fi àmì òróró yan Hasaeli ní ọba Siria.#2A. Ọba 8:7-13 16Yan Jehu, ọmọ Nimṣi, ní ọba Israẹli, kí o sì yan Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ará Abeli Mehola, ní wolii dípò ara rẹ.#2A. Ọba 9:1-6 17Ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ lọ́wọ́ idà Hasaeli, Jehu ni yóo pa á, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì bọ́ lọ́wọ́ idà Jehu, Eliṣa ni yóo pa á. 18Sibẹsibẹ n óo dá ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan sí, ní ilẹ̀ Israẹli: àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí mi, tí wọn kò tíì kúnlẹ̀ fún oriṣa Baali, tabi kí wọ́n fi ẹnu wọn kò ó lẹ́nu.”#Rom 11:4
Ìpè Eliṣa
19Nígbà tí ó yá, Elija bá kúrò níbẹ̀, bí ó ti ń lọ ó bá Eliṣa ọmọ Ṣafati níbi tí ó tí ń fi àjàgà mààlúù mejila kọ ilẹ̀. Àjàgà mààlúù mọkanla wà níwájú rẹ̀, bí wọ́n ti ń kọ ilẹ̀ lọ. Òun alára wà pẹlu àjàgà mààlúù tí ó kẹ́yìn, ó ń fi í kọ ilẹ̀. Elija kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó bọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó gbé e wọ Eliṣa. 20Eliṣa fi àjàgà mààlúù rẹ̀ sílẹ̀, ó sáré tẹ̀lé Elija, o wí fún un pé, “Jẹ́ kí n lọ dágbére fún baba ati ìyá mi, kí n fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, kí n tó máa tẹ̀lé ọ.”
Elija dá a lóhùn pé, “Pada lọ, àbí, kí ni mo ṣe fún ọ?”
21Eliṣa bá pada lẹ́yìn rẹ̀ sí ibi tí àwọn akọ mààlúù rẹ̀ wà, ó pa wọ́n. Ó fi igi tí ó fi ṣe àjàgà wọn ṣe igi ìdáná, ó bá se ẹran wọn. Ó pín ẹran náà fún àwọn eniyan, wọ́n sì jẹ ẹ́. Ó bá pada lọ sọ́dọ̀ Elija, ó ń tẹ̀lé e, ó sì ń ṣe iranṣẹ fún un.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KINNI 19: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa