I. A. Ọba 19:1-9

I. A. Ọba 19:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Ahabu ọba sọ gbogbo ohun tí Elija ṣe fún Jesebẹli, aya rẹ̀, ati bí ó ti pa gbogbo wolii oriṣa Baali. Jesebẹli bá rán oníṣẹ́ kan sí Elija pẹlu ìbúra pé, “Kí àwọn oriṣa pa mí, bí n kò bá pa ọ́ ní ìwòyí ọ̀la, bí o ti pa àwọn wolii Baali.” Ẹ̀rù ba Elija, ó sì sá fún ikú. Ó lọ sí Beeriṣeba, ní ilẹ̀ Juda. Ó fi iranṣẹ rẹ̀ sibẹ, ṣugbọn òun alára wọ inú ijù lọ ní ìrìn odidi ọjọ́ kan kí ó tó dúró. Ó bá jókòó lábẹ́ ìbòòji igi kan, ó wo ara rẹ̀ bíi kí òun kú. Ó sì gbadura sí OLUWA pé, “OLUWA, ó tó gẹ́ẹ́ báyìí! Kúkú pa mí. Kí ni mo fi sàn ju àwọn baba mi lọ?” Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi náà, ó sì sùn. Lójijì, angẹli kan fi ọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun.” Ó wò yíká, ó sì rí ìṣù àkàrà kan, ati ìkòkò omi kan lẹ́bàá ìgbèrí rẹ̀. Ó jẹun, ó mu omi, ó sì tún dùbúlẹ̀. Angẹli OLUWA náà pada wa, ó jí i, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun, kí ìrìn àjò náà má baà pọ̀jù fún ọ.” Elija dìde, ó jẹun, ó sì tún mu omi. Oúnjẹ náà sì fún un ní agbára láti rìn fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru títí tí ó fi dé orí òkè Horebu, òkè Ọlọrun. Ó dé ibi ihò àpáta kan, ó sì sùn níbẹ̀ mọ́jú ọjọ́ keji. OLUWA bá a sọ̀rọ̀, ó bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?”

I. A. Ọba 19:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ahabu sì sọ gbogbo ohun tí Elijah ti ṣe fún Jesebeli àti bí ó ti fi idà pa gbogbo àwọn wòlíì. Nítorí náà Jesebeli rán oníṣẹ́ kan sí Elijah wí pé, “Kí àwọn òrìṣà kí ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí èmi kò bá ṣe ẹ̀mí rẹ bí ọ̀kan nínú wọn ní ìwòyí ọ̀la.” Elijah sì bẹ̀rù, ó sá fún ẹ̀mí rẹ̀. Nígbà tí ó sì dé Beerṣeba ti Juda, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀, nígbà tí òun tìkára rẹ̀ sì lọ ní ìrìn ọjọ́ kan sí aginjù, ó sì wá sí ibi igi ọwọ̀ kan, ó sì jókòó lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbàdúrà kí òun bá le kú, wí pé, “Mo ti ní tó, OLúWA, gba ẹ̀mí mi kúrò; nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba mi lọ” Nígbà náà ni ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi, ó sì sùn lọ. Sì wò ó, angẹli fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí o jẹun.” Ó sì wò ó yíká, àkàrà tí a dín lórí ẹ̀yín iná, àti orù-omi wà lẹ́bàá orí rẹ̀. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì tún dùbúlẹ̀. Angẹli OLúWA sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jì fún ọ.” Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run. Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀.