I. A. Ọba 18:36-37
I. A. Ọba 18:36-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, ni irubọ aṣalẹ, ni Elijah woli sunmọ tòsi, o si wipe, Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, jẹ ki o di mimọ̀ loni pe, iwọ li Ọlọrun ni Israeli, emi si ni iranṣẹ rẹ, ati pe mo ṣe gbogbo nkan wọnyi nipa ọ̀rọ rẹ. Gbọ́ ti emi, Oluwa, gbọ́ ti emi, ki awọn enia yi ki o le mọ̀ pe, Iwọ Oluwa li Ọlọrun, ati pe, Iwọ tún yi ọkàn wọn pada.
I. A. Ọba 18:36-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣálẹ́, wòlíì Elijah sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “OLúWA, Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Israẹli àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ. Gbọ́ ti èmi, OLúWA, gbọ́ ti èmi, kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lè mọ̀ pé ìwọ OLúWA ni Ọlọ́run àti pé ìwọ tún yí ọkàn wọn padà.”
I. A. Ọba 18:36-37 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó di àkókò ìrúbọ ìrọ̀lẹ́, Elija súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó sì gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Israẹli, fi hàn lónìí pé ìwọ ni Ọlọrun Israẹli, ati pé iranṣẹ rẹ ni mí, ati pé gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, pẹlu àṣẹ rẹ ni. Dá mi lóhùn, OLUWA, dá mi lóhùn; kí àwọn eniyan wọnyi lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA ni Ọlọrun, ati pé ìwọ ni o fẹ́ yí ọkàn wọn pada sọ́dọ̀ ara rẹ.”