I. A. Ọba 18:16-40
I. A. Ọba 18:16-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni Obadiah lọ lati pade Ahabu, o si sọ fun u: Ahabu si lọ lati pade Elijah. O si ṣe, bi Ahabu ti ri Elijah, Ahabu si wi fun u pe, Iwọ li ẹniti nyọ Israeli li ẹnu! On sì dahùn pe, Emi kò yọ Israeli li ẹnu; bikoṣe iwọ ati ile baba rẹ, ninu eyiti ẹnyin ti kọ̀ ofin Oluwa silẹ, ti iwọ si ti ntọ̀ Baalimu lẹhin. Nitorina, ranṣẹ nisisiyi, ki o si kó gbogbo Israeli jọ sọdọ mi si oke Karmeli ati awọn woli Baali ãdọtalenirinwo, ati awọn woli ere-oriṣa irinwo, ti njẹun ni tabili Jesebeli. Bẹ̃ni Ahabu ranṣẹ si gbogbo awọn ọmọ Israeli, o si kó awọn woli jọ si oke Karmeli. Elijah si tọ gbogbo awọn enia na wá, o si wipe, Yio ti pẹ to ti ẹnyin o ma ṣiyemeji? Bi Oluwa ba ni Ọlọrun, ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin: ṣugbọn bi Baali ba ni ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin! Awọn enia na kò si da a li ohùn ọ̀rọ kan. Elijah si wi fun awọn enia na pe, Emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù ni woli Oluwa; ṣugbọn awọn woli Baali ãdọta-lenirinwo ọkunrin, Nitorina jẹ ki nwọn ki o fun wa li ẹgbọrọ akọ-malu meji; ki nwọn ki o si yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara wọn, ki nwọn ki o si ke e, ki nwọn ki o si tò o si ori igi, ki nwọn ki o má ṣe fi iná si i: emi o si tun ẹgbọrọ akọ-malu keji ṣe, emi o si tò o sori igi, emi kì o si fi iná si i. Ki ẹ si kepe orukọ awọn ọlọrun nyin, emi o si kepè orukọ Oluwa: Ọlọrun na ti o ba fi iná dahùn on na li Ọlọrun. Gbogbo awọn enia na si dahùn, nwọn si wipe, O wi i re. Elijah si wi fun awọn woli Baali pe, Ẹ yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara nyin, ki ẹ si tètekọ ṣe e: nitori ẹnyin pọ̀: ki ẹ si kepè orukọ awọn ọlọrun nyin, ṣugbọn ẹ máṣe fi iná si i, Nwọn si mu ẹgbọrọ akọ-malu na ti a fi fun wọn, nwọn si ṣe e, nwọn si kepè orukọ Baali lati owurọ titi di ọ̀sangangan wipe, Baali! da wa lohùn. Ṣugbọn kò si ohùn, bẹ̃ni kò si idahùn. Nwọn si jó yi pẹpẹ na ka, eyiti nwọn tẹ́. O si ṣe, li ọ̀sangangan ni Elijah fi wọn ṣe ẹlẹya o si wipe, Ẹ kigbe lohùn rara, ọlọrun sa li on; bọya o nṣe àṣaro, tabi on nlepa, tabi o re àjo, bọya o sùn, o yẹ ki a ji i. Nwọn si kigbe lohùn rara, nwọn si fi ọbẹ ati ọ̀kọ ya ara wọn gẹgẹ bi iṣe wọn, titi ẹ̀jẹ fi tu jade li ara wọn. O si ṣe, nigbati ọjọ kan atarí, nwọn si nfi were sọtẹlẹ titi di akoko irubọ aṣalẹ, kò si ohùn, bẹ̃ni kò si idahùn, tabi ẹniti o kà a si. Njẹ Elijah wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹ sunmọ mi. Gbogbo awọn enia na si sunmọ ọ. On si tun pẹpẹ Oluwa ti o ti wo lulẹ ṣe. Elijah si mu okuta mejila, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya ọmọ Jakobu, ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá, wipe, Israeli li orukọ rẹ yio ma jẹ: Okuta wọnyi li o fi tẹ́ pẹpẹ kan li orukọ Oluwa, o si wà kòtò yi pẹpẹ na ka, ti o le gba iwọn oṣùwọn irugbin meji. O si to igi na daradara, o si ke ẹgbọrọ akọ-malu na, o si tò o sori igi, o si wipe, fi omi kún ikoko mẹrin, ki ẹ si tú u sori ẹbọ sisun ati sori igi na. O si wipe, Ṣe e nigba keji. Nwọn si ṣe e nigba keji. O si wipe, Ṣe e nigba kẹta. Nwọn si ṣe e nigba kẹta. Omi na si ṣàn yi pẹpẹ na ka, o si fi omi kún kòtò na pẹlu. O si ṣe, ni irubọ aṣalẹ, ni Elijah woli sunmọ tòsi, o si wipe, Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, jẹ ki o di mimọ̀ loni pe, iwọ li Ọlọrun ni Israeli, emi si ni iranṣẹ rẹ, ati pe mo ṣe gbogbo nkan wọnyi nipa ọ̀rọ rẹ. Gbọ́ ti emi, Oluwa, gbọ́ ti emi, ki awọn enia yi ki o le mọ̀ pe, Iwọ Oluwa li Ọlọrun, ati pe, Iwọ tún yi ọkàn wọn pada. Nigbana ni iná Oluwa bọ́ silẹ, o si sun ẹbọsisun na ati igi, ati okuta wọnnì, ati erupẹ o si lá omi ti mbẹ ninu yàra na. Nigbati gbogbo awọn enia ri i, nwọn da oju wọn bolẹ: nwọn si wipe, Oluwa, on li Ọlọrun; Oluwa, on li Ọlọrun! Elijah si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn woli Baali; máṣe jẹ ki ọkan ninu wọn ki o salà. Nwọn si mu wọn: Elijah si mu wọn sọkalẹ si odò Kiṣoni, o si pa wọn nibẹ.
I. A. Ọba 18:16-40 Yoruba Bible (YCE)
Ọbadaya bá lọ sọ fún ọba, ọba sì lọ pàdé Elija. Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó wí fún un pé, “Ojú rẹ nìyí ìwọ tí ò ń yọ Israẹli lẹ́nu!” Elija dáhùn pé, “Èmi kọ́ ni mò ń yọ Israẹli lẹ́nu, ìwọ gan-an ni. Ìwọ ati ilé baba rẹ; nítorí ẹ ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, ẹ sì ń sin oriṣa Baali. Nítorí náà, pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, kí wọ́n pàdé mi ní orí òkè Kamẹli. Kí aadọtalenirinwo (450) àwọn wolii oriṣa Baali ati àwọn irinwo (400) wolii oriṣa Aṣera, tí ayaba Jesebẹli ń bọ náà bá wọn wá.” Ahabu bá ranṣẹ pé gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ati àwọn wolii oriṣa Baali, pé kí wọ́n pàdé òun ní orí òkè Kamẹli. Elija bá súnmọ́ gbogbo àwọn eniyan, ó wí fún wọn pé, “Yóo ti pẹ́ tó, tí ẹ óo fi máa ṣe iyèméjì? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni Ọlọrun, ẹ máa sìn ín. Bí ó bá sì jẹ́ pé oriṣa Baali ni ẹ máa bọ ọ́.” Ṣugbọn àwọn eniyan náà kò sọ ohunkohun. Elija tún sọ fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni wolii OLUWA tí ó ṣẹ́kù, ṣugbọn àwọn wolii oriṣa Baali tí wọ́n wà jẹ́ aadọtalenirinwo (450). Ẹ fún wa ní akọ mààlúù meji, kí àwọn wolii Baali mú ọ̀kan, kí wọ́n pa á, kí wọ́n sì gé e kéékèèké. Kí wọ́n kó o sórí igi, ṣugbọn kí wọ́n má fi iná sí i. Èmi náà yóo pa akọ mààlúù keji, n óo kó o sórí igi, n kò sì ní fi iná sí i. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin ẹ ké pe oriṣa Baali, Ọlọrun yín, èmi náà yóo sì ké pe OLUWA. Èyíkéyìí ninu wọn tí ó bá dáhùn, tí ó bá mú kí iná ṣẹ́, òun ni Ọlọrun.” Àwọn eniyan náà bá pariwo pé, “A gbà bẹ́ẹ̀.” Elija bá sọ fún àwọn wolii Baali pé, “Ẹ̀yin ni ẹ pọ̀, ẹ̀yin ẹ kọ́kọ́ mú akọ mààlúù kan, kí ẹ tọ́jú rẹ̀. Ẹ gbadura sí oriṣa yín ṣugbọn ẹ má fi iná sí igi ẹbọ yín.” Wọ́n mú akọ mààlúù tí wọ́n fún wọn, wọ́n pa á, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké pe oriṣa Baali láti àárọ̀ títí di ọ̀sán. Wọ́n ń wí pé, “Baali, dá wa lóhùn!” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fọhùn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jó yípo pẹpẹ tí wọ́n kọ́. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá wọn lóhùn. Nígbà tí ó di ọ̀sán, Elija bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ pé, “Ẹ kígbe sókè, nítorí pé Ọlọrun ṣá ni. Bóyá ó ronú lọ ni, bóyá ó sì wọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ lọ ni; tabi ó lè jẹ́ pé ó lọ sí ìrìn àjò ni. Bóyá ó sùn ni, ẹ sì níláti jí i.” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe sókè, wọ́n ń fi idà ati ọ̀kọ̀ ya ara wọn lára, gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi bò wọ́n. Nígbà tí ọ̀sán pọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń sáré kiri bíi wèrè, títí tí ó fi di àkókò ìrúbọ ọ̀sán, ṣugbọn Baali kò dá wọn lóhùn rárá. Kò tilẹ̀ fọhùn. Nígbà tó yá, Elija wí fún gbogbo àwọn eniyan náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi níhìn-ín.” Gbogbo wọn súnmọ́ ọn, wọ́n sì yí i ká. Ó bá tún pẹpẹ OLUWA tí ó ti wó ṣe. Ó kó òkúta mejila jọ, òkúta kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jakọbu, ẹni tí OLUWA sọ fún pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.” Ó fi òkúta mejeejila náà kọ́ pẹpẹ ní orúkọ OLUWA. Ó gbẹ́ kòtò kan yí pẹpẹ náà ká, kòtò náà tóbi tó láti gba òṣùnwọ̀n irúgbìn meji (nǹkan bíi lita mẹrinla). Lẹ́yìn náà, ó to igi sórí pẹpẹ, ó gé akọ mààlúù náà sí wẹ́wẹ́, ó sì tò wọ́n sórí igi. Ó ní kí wọ́n pọn ẹ̀kún ìkòkò omi ńlá mẹrin, kí wọ́n dà á sórí ẹbọ ati igi náà, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní kí wọ́n tún da mẹrin mìíràn, wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní kí wọ́n tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹẹkẹta, wọ́n sì tún ṣe bẹ́ẹ̀. Omi náà ṣàn sílẹ̀ yí pẹpẹ ká, ó sì kún kòtò tí wọ́n gbẹ́ yípo. Nígbà tí ó di àkókò ìrúbọ ìrọ̀lẹ́, Elija súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó sì gbadura pé, “OLUWA, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Israẹli, fi hàn lónìí pé ìwọ ni Ọlọrun Israẹli, ati pé iranṣẹ rẹ ni mí, ati pé gbogbo ohun tí mò ń ṣe yìí, pẹlu àṣẹ rẹ ni. Dá mi lóhùn, OLUWA, dá mi lóhùn; kí àwọn eniyan wọnyi lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA ni Ọlọrun, ati pé ìwọ ni o fẹ́ yí ọkàn wọn pada sọ́dọ̀ ara rẹ.” OLUWA bá sọ iná sílẹ̀, iná náà sì jó ẹbọ náà ati igi, ati òkúta. Ó jó gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀, ó sì lá gbogbo omi tí ó wà ninu kòtò. Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n wí pé, “OLUWA ni Ọlọrun! OLUWA ni Ọlọrun!” Elija bá pàṣẹ pé, “Ẹ mú gbogbo àwọn wolii oriṣa Baali! Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wọn sá lọ.” Àwọn eniyan náà bá ki gbogbo wọn mọ́lẹ̀, Elija kó wọn lọ sí ibi odò Kiṣoni, ó sì pa wọ́n sibẹ.
I. A. Ọba 18:16-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni Ọbadiah sì lọ láti pàdé Ahabu, ó sì sọ fún un, Ahabu sì lọ láti pàdé Elijah. Nígbà tí Ahabu sì rí Elijah, ó sì wí fún un pé, “Ṣé ìwọ nìyìí, ìwọ tí ń yọ Israẹli lẹ́nu?” Elijah sì dá a lóhùn pé, “Èmi kò yọ Israẹli lẹ́nu, bí kò ṣe ìwọ àti ilé baba rẹ. Ẹ ti kọ òfin OLúWA sílẹ̀, ẹ sì ń tọ Baali lẹ́yìn. Nísinsin yìí kó gbogbo Israẹli jọ láti pàdé mi lórí òkè Karmeli. Àti kí o sì mú àádọ́ta-lé-ní-irínwó (450) àwọn wòlíì Baali àti irínwó (400) àwọn wòlíì òrìṣà Aṣerah tí wọ́n ń jẹun ní tábìlì Jesebeli.” Bẹ́ẹ̀ ni Ahabu ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, ó sì kó àwọn wòlíì jọ sí orí òkè Karmeli. Elijah sì lọ síwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin yóò máa ṣiyèméjì? Bí OLúWA bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ṣùgbọ́n bí Baali bá ni Ọlọ́run, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò sì wí ohun kan. Nígbà náà ni Elijah wí fún wọn pé, “Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù ní wòlíì OLúWA, ṣùgbọ́n, àádọ́ta-lé-ní-irínwó (450) ni wòlíì Baali. Ẹ fún wa ní ẹgbọrọ akọ màlúù méjì. Jẹ́ kí wọn kí ó sì yan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ara wọn, kí wọn kí ó sì gé e sí wẹ́wẹ́, kí wọn kí ó sì tò ó sí orí igi, kí wọn kí ó má ṣe fi iná sí i. Èmi yóò sì tún ẹgbọrọ akọ màlúù kejì ṣe, èmi yóò sì tò ó sórí igi, èmi kì yóò sì fi iná sí i. Nígbà náà ẹ ó sì ké pe orúkọ àwọn Ọlọ́run yín, èmi yóò sì ké pe orúkọ OLúWA. Ọlọ́run náà tí ó fi iná dáhùn, òun ni Ọlọ́run.” Nígbà náà ni gbogbo àwọn ènìyàn náà sì wí pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára.” Elijah sì wí fún àwọn wòlíì Baali wí pé, “Ẹ yan ẹgbọrọ akọ màlúù kan fún ara yín, kí ẹ sì tètè kọ́ ṣe é, nítorí ẹ̀yin pọ̀. Ẹ ké pe orúkọ àwọn ọlọ́run yín, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe fi iná sí i.” Nígbà náà ni wọ́n sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù náà, tí a ti fi fún wọn, wọ́n sì ṣe é. Nígbà náà ni wọ́n sì ké pe orúkọ Baali láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan wí pé, “Baali! Dá wa lóhùn!” Wọ́n sì ń kégbe. Ṣùgbọ́n kò sí ìdáhùn; kò sí ẹnìkan tí ó sì dáhùn. Wọ́n sì jó yí pẹpẹ náà ká, èyí tí wọ́n tẹ́. Ní ọ̀sán gangan, Elijah bẹ̀rẹ̀ sí ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà ó sì wí pé, “Ẹ kígbe lóhùn rara Ọlọ́run sá à ni òun! Bóyá ó ń ṣe àṣàrò, tàbí kò ráyè, tàbí ó re àjò. Bóyá ó sùn, ó yẹ kí a jí i.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kígbe lóhùn rara, wọ́n sì fi ọ̀bẹ àti ọ̀kọ̀ ya ara wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, títí tí ẹ̀jẹ̀ fi tú jáde ní ara wọn. Nígbà tí ọjọ́ yẹ àtàrí, wọ́n sì ń fi òmùgọ̀ sọtẹ́lẹ̀ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ́, ṣùgbọ́n kò sí ohùn, kò sì ṣí ìdáhùn, kò sì ṣí ẹni tí ó kà á sí. Nígbà náà ni Elijah wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ súnmọ́ mi.” Wọ́n sì súnmọ́ ọn, ó sì tún pẹpẹ OLúWA tí ó ti wó lulẹ̀ ṣe. Elijah sì mú òkúta méjìlá, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà ọmọ Jakọbu kan, ẹni tí ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ wá wí pé, “Israẹli ni orúkọ rẹ̀ yóò máa jẹ́.” Ó sì tẹ́ pẹpẹ pẹ̀lú àwọn òkúta wọ̀nyí ní orúkọ OLúWA, ó sì wa yàrá yí pẹpẹ náà ká, tí ó lè gba ìwọ̀n òṣùwọ̀n irúgbìn méjì. Ó sì to igi náà dáradára, ó sì ké ẹgbọrọ akọ màlúù náà wẹ́wẹ́, ó sì tò ó sórí igi. Nígbà náà ni ó sì wí fún wọn wí pé, “Ẹ fi omi kún ìkòkò mẹ́rin, kí ẹ sì tu sórí ẹbọ sísun àti sórí igi náà.” Ó sì wí pe, “Ẹ ṣe é ní ìgbà kejì” Wọ́n sì ṣe é ní ìgbà kejì. Ó sì tún wí pé, “Ṣe é ní ìgbà kẹta.” Omi náà sì sàn yí pẹpẹ náà ká, ó sì fi omi kún yàrá náà pẹ̀lú. Ó sì ṣe, ní ìrúbọ àṣálẹ́, wòlíì Elijah sì súnmọ́ tòsí, ó sì gbàdúrà wí pé, “OLúWA, Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ lónìí pé ìwọ ni Ọlọ́run ní Israẹli àti pé èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa àṣẹ rẹ. Gbọ́ ti èmi, OLúWA, gbọ́ ti èmi, kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lè mọ̀ pé ìwọ OLúWA ni Ọlọ́run àti pé ìwọ tún yí ọkàn wọn padà.” Nígbà náà ni iná OLúWA bọ́ sílẹ̀, ó sì sun ẹbọ sísun náà àti igi, àti àwọn òkúta, àti erùpẹ̀, ó sì tún lá omi tí ń bẹ nínú yàrá náà. Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn sì rí èyí, wọ́n da ojú wọn bolẹ̀, wọ́n sì kígbe pé, “OLúWA, òun ni Ọlọ́run! OLúWA, òun ni Ọlọ́run!” Nígbà náà ni Elijah sì pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ mú àwọn wòlíì Baali. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú wọn kí ó sálọ!” Wọ́n sì mú wọn, Elijah sì mú wọn sọ̀kalẹ̀ sí Àfonífojì Kiṣoni, ó sì pa wọ́n níbẹ̀.