I. A. Ọba 18:1-18

I. A. Ọba 18:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, lẹhin ọjọ pupọ, ọ̀rọ Oluwa tọ Elijah wá lọdun kẹta, wipe, Lọ, fi ara rẹ hàn Ahabu; emi o si rọ̀ òjo sori ilẹ. Elijah si lọ ifi ara rẹ̀ han Ahabu. Iyan nla si mu ni Samaria. Ahabu si pe Obadiah, ti iṣe olori ile rẹ̀. Njẹ Obadiah bẹ̀ru Oluwa gidigidi: O si ṣe, nigbati Jesebeli ke awọn woli Oluwa kuro, ni Obadiah mu ọgọrun woli, o si fi wọn pamọ li aradọta ni iho okuta; o si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn. Ahabu si wi fun Obadiah pe, Rin ilẹ lọ, si orisun omi gbogbo, ati si odò gbogbo: bọya awa le ri koriko lati gbà awọn ẹṣin ati awọn ibãka là, ki a má ba ṣòfo awọn ẹranko patapata. Nwọn si pin ilẹ na lãrin ara wọn, lati là a ja: Ahabu gba ọ̀na kan lọ fun ara rẹ̀, Obadiah si gba ọ̀na miran lọ fun ara rẹ̀. Nigbati Obadiah si wà li ọ̀na, kiyesi i, Elijah pade rẹ̀: nigbati o mọ̀ ọ, o si doju rẹ̀ bolẹ, o si wipe, Ṣé iwọ oluwa mi Elijah nìyí? O si da a lohùn pe, Emi ni: lọ, sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin. On si wipe, Ẹ̀ṣẹ kini mo ha dá, ti iwọ fẹ fi iranṣẹ rẹ le Ahabu lọwọ lati pa mi? Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, kò si orilẹ-ède tabi ijọba kan, nibiti oluwa mi kò ranṣẹ de lati wò ọ: nigbati nwọn ba si wipe, Kò si; on a mu ki ijọba tabi orilẹ-ède na bura pe: awọn kò ri ọ. Nisisiyi iwọ si wipe, Lọ, sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin; Yio si ṣe bi emi o ti lọ kuro li ọdọ rẹ, Ẹmi Oluwa yio si gbe ọ lọ si ibi ti emi kò mọ̀; nigbati mo ba si de, ti mo si wi fun Ahabu, ti kò ba si ri ọ, on o pa mi: ṣugbọn emi, iranṣẹ rẹ, bẹ̀ru Oluwa lati igba ewe mi wá. A kò ha sọ fun oluwa mi, ohun ti mo ṣe nigbati Jesebeli pa awọn woli Oluwa, bi mo ti pa ọgọrun enia mọ ninu awọn woli Oluwa li aradọta ninu ihò-okuta, ti mo si fi àkara pẹlu omi bọ́ wọn? Nisisiyi, iwọ si wipe, Lọ sọ fun oluwa rẹ pe, Wò o, Elijah mbẹ nihin! on o si pa mi. Elijah si wipe, Bi Oluwa awọn ọmọ-ogun ti wà, niwaju ẹniti emi duro, nitõtọ, emi o fi ara mi han fun u loni yi. Bẹ̃ni Obadiah lọ lati pade Ahabu, o si sọ fun u: Ahabu si lọ lati pade Elijah. O si ṣe, bi Ahabu ti ri Elijah, Ahabu si wi fun u pe, Iwọ li ẹniti nyọ Israeli li ẹnu! On sì dahùn pe, Emi kò yọ Israeli li ẹnu; bikoṣe iwọ ati ile baba rẹ, ninu eyiti ẹnyin ti kọ̀ ofin Oluwa silẹ, ti iwọ si ti ntọ̀ Baalimu lẹhin.

I. A. Ọba 18:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, ní ọdún kẹta tí ọ̀dá ti dá, OLUWA sọ fún Elija pé, “Lọ fi ara rẹ han Ahabu ọba, n óo sì rọ̀jò sórí ilẹ̀.” Elija bá lọ fi ara han Ahabu. Ìyàn tí ó mú ní ìlú Samaria pọ̀ pupọ. Ahabu pe Ọbadaya, tí ó jẹ́ alabojuto ààfin. Ọbadaya jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA gan-an. Nígbà tí Jesebẹli bẹ̀rẹ̀ sí pa àwọn wolii OLUWA, Ọbadaya yìí ló kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, ó kó aadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi. Ahabu sọ fún Ọbadaya pé, “Lọ wo gbogbo orísun omi ati àfonífojì ní gbogbo ilẹ̀ yìí, kí o wò ó bóyá a lè rí koríko láti fi bọ́ àwọn ẹṣin ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kí wọ́n má baà kú.” Wọ́n ṣe àdéhùn ibi tí olukuluku yóo lọ wò ní gbogbo ilẹ̀ náà, olukuluku sì gba ọ̀nà tirẹ̀ lọ. Ahabu ọba lọ sí apá kan, Ọbadaya sì lọ sí apá keji. Bí Ọbadaya ti ń lọ, lójijì ni ó pàdé Elija. Ó ranti rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì bi í léèrè pé, “Àbí ìwọ kọ́ ni, Elija, oluwa mi?” Elija dá a lóhùn pé, “Èmi ni, lọ sọ fún oluwa rẹ, ọba, pé èmi Elija wà níhìn-ín.” Ọbadaya bá bèèrè pé, “Kí ni mo ṣe, tí o fi fẹ́ fa èmi iranṣẹ rẹ, lé Ahabu ọba lọ́wọ́ láti pa? OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, pé ọba ti wá ọ káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè ayé. Bí ọba ìlú kan, tabi tí orílẹ̀-èdè kan, bá sọ pé o kò sí ní ilẹ̀ òun, Ahabu á ní dandan, àfi kí wọ́n búra pé lóòótọ́ ni wọn kò rí ọ. Nisinsinyii, o wá sọ fún mi pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín. Bí mo bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ tán tí ẹ̀mí Ọlọrun bá gbé ọ lọ sí ibi tí n kò mọ̀ ńkọ́? Bí mo bá lọ sọ fún Ahabu pé o wà níhìn-ín, tí kò bá rí ọ mọ́, pípa ni yóo pa mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ìgbà èwe mi ni mo ti bẹ̀rù OLUWA. Àbí o kò gbọ́ nígbà tí Jesebẹli ń pa àwọn wolii OLUWA, pé mo kó ọgọrun-un ninu wọn pamọ́ sinu ihò àpáta meji, mo kó araadọta sinu ihò kọ̀ọ̀kan, mo sì ń fún wọn ní oúnjẹ ati omi. O ṣe wá sọ pé kí n lọ sọ fún oluwa mi pé o wà níhìn-ín? Pípa ni yóo pa mí.” Elija dá a lóhùn pé, “Ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí mò ń sìn, mo ṣèlérí fún ọ pé, n óo fara han ọba lónìí.” Ọbadaya bá lọ sọ fún ọba, ọba sì lọ pàdé Elija. Nígbà tí Ahabu rí Elija, ó wí fún un pé, “Ojú rẹ nìyí ìwọ tí ò ń yọ Israẹli lẹ́nu!” Elija dáhùn pé, “Èmi kọ́ ni mò ń yọ Israẹli lẹ́nu, ìwọ gan-an ni. Ìwọ ati ilé baba rẹ; nítorí ẹ ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, ẹ sì ń sin oriṣa Baali.

I. A. Ọba 18:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ní ọdún kẹta, ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Elijah wá pé: “Lọ, kí o sì fi ara rẹ̀ hàn fún Ahabu, èmi yóò sì rọ òjò sórí ilẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ fi ara rẹ̀ han Ahabu. Ìyàn ńlá sì mú ní Samaria, Ahabu sì ti pe Ọbadiah, ẹni tí ń ṣe olórí ilé rẹ̀. Ọbadiah sì bẹ̀rù OLúWA gidigidi. Nígbà tí Jesebeli sì ń pa àwọn wòlíì OLúWA kúrò, Ọbadiah sì mú ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pamọ́ sínú ihò òkúta, àádọ́ta ní ihò kọ̀ọ̀kan, ó sì fi àkàrà pẹ̀lú omi bọ́ wọn. Ahabu sì ti wí fún Ọbadiah pé, “Lọ sí gbogbo ilẹ̀ sí orísun omi gbogbo àti sí ilẹ̀ gbogbo. Bóyá àwa lè rí koríko láti gba àwọn ẹṣin àti àwọn ìbáaka là, kí a má bá à ṣòfò àwọn ẹranko pátápátá.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pín ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ dé láàrín ara wọn, Ahabu gba ọ̀nà kan lọ, Ọbadiah sì gba ọ̀nà mìíràn lọ. Bí Ọbadiah sì ti ń rìn lọ, Elijah sì pàdé rẹ̀. Ọbadiah sì mọ̀ ọ́n, ó dojúbolẹ̀, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ni nítòótọ́, Elijah, olúwa mi?” Elijah sì dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, lọ kí o sọ fún olúwa rẹ pé, ‘Elijah ń bẹ níhìn-ín.’ ” Ọbadiah sì béèrè pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ kí ni mo ha dá tí ìwọ fi ń fi ìránṣẹ́ rẹ lé Ahabu lọ́wọ́ láti pa? Mo mọ̀ dájú pé bí OLúWA Ọlọ́run rẹ ti ń bẹ, kò sí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan tí olúwa mi kò ti rán ènìyàn lọ láti wò ọ́. Àti nígbà tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan bá wí pé o kò sí, òun a sì mú kí wọ́n búra wí pé wọn kò rí ọ. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ wí fún mi pé kí n lọ sọ́dọ̀ olúwa mi, kí n sì wí pé, ‘Elijah ń bẹ níhìn-ín.’ Èmi kò sì mọ ibi tí ẹ̀mí OLúWA yóò gbé ọ lọ nígbà tí mo bá fi ọ́ sílẹ̀. Bí mo bá lọ, tí mo sì sọ fún Ahabu, tí kò sì rí ọ, òun a sì pa mí. Síbẹ̀ èmi ìránṣẹ́ rẹ bẹ̀rù OLúWA láti ìgbà èwe mi wá. Ṣé OLúWA mi kò ha ti gbọ́ ohun tí mo ṣe nígbà tí Jesebeli ń pa àwọn wòlíì OLúWA? Mo fi ọgọ́rùn-ún wòlíì OLúWA pamọ́ sínú ihò òkúta méjì, àràádọ́ta ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo sì fi omi àti oúnjẹ bọ́ wọn. Ìwọ sì sọ fún mi nísinsin yìí pé, kí n tọ olúwa mi lọ pé, ‘Elijah ń bẹ níhìn-ín.’ Òun a sì pa mí!” Elijah sì wí pé, “Bí OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, nítòótọ́ èmi yóò fi ara mi hàn fún Ahabu lónìí.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọbadiah sì lọ láti pàdé Ahabu, ó sì sọ fún un, Ahabu sì lọ láti pàdé Elijah. Nígbà tí Ahabu sì rí Elijah, ó sì wí fún un pé, “Ṣé ìwọ nìyìí, ìwọ tí ń yọ Israẹli lẹ́nu?” Elijah sì dá a lóhùn pé, “Èmi kò yọ Israẹli lẹ́nu, bí kò ṣe ìwọ àti ilé baba rẹ. Ẹ ti kọ òfin OLúWA sílẹ̀, ẹ sì ń tọ Baali lẹ́yìn.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa