I. A. Ọba 16:1-34

I. A. Ọba 16:1-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, ọ̀rọ Oluwa tọ Jehu, ọmọ Hanani wá, si Baaṣa wipe, Bi o ti ṣepe mo gbé ọ ga lati inu ẽkuru wá, ti mo si ṣe ọ li olori Israeli, enia mi; iwọ si rìn li ọ̀na Jeroboamu, iwọ si ti mu ki Israeli enia mi ki o ṣẹ̀, lati fi ẹ̀ṣẹ wọn mu mi binu; Kiyesi i, emi o mu iran Baaṣa, ati iran ile rẹ̀ kuro; emi o si ṣe ile rẹ̀ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati. Ẹni Baaṣa ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ; ati ẹni rẹ̀ ti o kú ni oko li ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ. Ati iyokù iṣe Baaṣa, ati ohun ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli. Baaṣa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Tirsa: Ela, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀. Ati pẹlu nipa ọwọ́ Jehu woli, ọmọ Hanani, li ọ̀rọ Oluwa de si Baaṣa, ati si ile rẹ̀, ani nitori gbogbo ibi ti o ṣe niwaju Oluwa, ni fifi iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ mu u binu, ati wiwà bi ile Jeroboamu, ati nitori ti o pa a. Li ọdun kẹrindilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Tirsa li ọdun meji. Ati iranṣẹ rẹ̀ Simri, olori idaji kẹkẹ́ rẹ̀, dìtẹ rẹ̀, nigbati o ti wà ni Tirsa, o si mu amupara ni ile Arsa, iriju ile rẹ̀ ni Tirsa. Simri si wọle o si kọlù u, o si pa a, li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, o si jọba ni ipò rẹ̀. O si ṣe, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, bi o ti joko li ori itẹ rẹ̀, o lù gbogbo ile Baaṣa pa: kò kù ọmọde ọkunrin kan silẹ, ati awọn ibatan rẹ̀ ati awọn ọrẹ́ rẹ̀. Bayi ni Simri pa gbogbo ile Baaṣa run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ si Baaṣa nipa ọwọ́ Jehu woli, Nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ Baaṣa, ati Ela, ọmọ rẹ̀, nipa eyiti nwọn ṣẹ̀, ati nipa eyiti nwọn mu Israeli ṣẹ̀, ni fifi ohun-asán wọn wọnnì mu ki Oluwa, Ọlọrun Israeli binu. Ati iyokù iṣe Ela, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Simri jọba ijọ meje ni Tirsa. Awọn enia si do tì Gibbetoni, ti awọn ara Filistia. Awọn enia ti o dotì gbọ́ wipe, Simri ditẹ̀ o si ti pa ọba pẹlu: nitorina gbogbo Israeli fi Omri, olori ogun, jẹ ọba lori Israeli li ọjọ na ni ibudo. Omri si goke lati Gibbetoni lọ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, nwọn si do tì Tirsa. O si ṣe, nigbati Simri mọ̀ pe a gba ilu, o wọ inu ãfin ile ọba lọ, o si tẹ iná bọ ile ọba lori ara rẹ̀, o si kú. Nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wọnni ti o da, ni ṣiṣe buburu niwaju Oluwa, ni rirìn li ọ̀na Jeroboamu ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da, lati mu ki Israeli ki o ṣẹ̀. Ati iyokù iṣe Simri, ati ọtẹ rẹ̀ ti o dì, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Nigbana li awọn enia Israeli da meji; apakan awọn enia ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin, lati fi i jọba, apakan si ntọ̀ Omri lẹhin. Ṣugbọn awọn enia ti ntọ̀ Omri lẹhin bori awọn ti ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin: bẹ̃ni Tibni kú, Omri si jọba. Li ọdun kọkanlelọgbọn Asa, ọba Juda, ni Omri bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli fun ọdun mejila: ọdun mẹfa li o jọba ni Tirsa. O si rà oke Samaria lọwọ Semeri ni talenti meji fadaka, o si tẹdo lori oke na, o si pe orukọ ilu na ti o tẹ̀do ni Samaria nipa orukọ Semeri, oluwa oke Samaria. Ṣugbọn Omri ṣe buburu li oju Oluwa, o si ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o wà ṣãju rẹ̀. Nitori ti o rìn ni gbogbo ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, eyiti o mu Israeli ṣẹ̀, lati fi ohun-asán wọn wọnni mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu. Ati iyokù iṣe Omri ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi hàn, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? Omri si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria: Ahabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Ati li ọdun kejidilogoji Asa, ọba Juda, ni Ahabu, ọmọ Omri, bẹ̀rẹ si jọba lori Israeli: Ahabu, ọmọ Omri, si jọba lori Israeli ni Samaria li ọdun mejilelogun, Ahabu, ọmọ Omri, si ṣe buburu li oju Oluwa jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju rẹ̀ lọ. O si ṣe, bi ẹnipe o ṣe ohun kekere fun u lati ma rìn ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, o si mu Jesebeli, ọmọbinrin Etbaali, ọba awọn ara Sidoni li aya, o si lọ, o si sin Baali, o si bọ ọ, O si tẹ pẹpẹ kan fun Baali ninu ile Baali, ti o kọ́ ni Samaria. Ahabu si ṣe ere oriṣa kan; Ahabu si ṣe jù gbogbo awọn ọba Israeli lọ, ti o wà ṣaju rẹ̀, lati mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli binu. Li ọjọ rẹ̀ ni Hieli, ara Beteli, kọ́ Jeriko: o fi ipilẹ rẹ̀ le ilẹ ni Abiramu, akọbi rẹ̀, o si gbé awọn ilẹkun ibode rẹ̀ kọ́ ni Segubu abikẹhin rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Joṣua, ọmọ Nuni sọ.

I. A. Ọba 16:1-34 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọrun rán wolii Jehu, ọmọ Hanani, pé kí ó sọ fún Baaṣa ọba pé, “O kò jámọ́ nǹkankan tẹ́lẹ̀, kí n tó fi ọ́ ṣe olórí àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi. Ṣugbọn irú ìgbésẹ̀ tí Jeroboamu gbé ni ìwọ náà gbé, ìwọ náà mú kí àwọn eniyan mi dẹ́ṣẹ̀; ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì ti mú mi bínú gidigidi. Nítorí náà, n óo pa ìwọ ati ìdílé rẹ rẹ́. Bí mo ti ṣe ìdílé Jeroboamu, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe ìdílé tìrẹ náà. Ẹnikẹ́ni ninu ìdílé rẹ tí ó bá kú láàrin ìlú, ajá ni yóo jẹ òkú rẹ̀, èyíkéyìí ninu wọn tí ó bá sì kú sinu igbó, àwọn ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀.” Gbogbo nǹkan yòókù tí Baaṣa ṣe, ati gbogbo iṣẹ́ akikanju rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Baaṣa kú, wọ́n sì sin ín sí Tirisa. Ela ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀. Lẹ́yìn náà OLUWA ti ẹnu wolii Jehu ọmọ Hanani bá Baaṣa ati ìdílé rẹ̀ wí nítorí gbogbo ibi tí ó ṣe lójú OLUWA, tí ó fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mú OLUWA bínú nítorí pé ó dẹ́ṣẹ̀ bíi Jeroboamu, ati pé òun ló tún pa ìdílé Jeroboamu run. Ní ọdún kẹrindinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, gorí oyè ní ilẹ̀ Israẹli; ó sì jọba ní Tirisa fún ọdún meji. Simiri, ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun rẹ̀, alabojuto ìdajì àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣọ̀tẹ̀ sí i. Ní ọjọ́ kan, níbi tí ó ti ń mu ọtí àmupara ní ilé Arisa, alabojuto ààfin, ní Tirisa, ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa ọba Juda gorí oyè, Simiri bá wọlé, ó fi idà ṣá Ela pa, ó bá fi ara rẹ̀ jọba dípò Ela. Bí Simiri ti gorí oyè, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba ni ó pa gbogbo àwọn ìdílé Baaṣa patapata. Gbogbo àwọn ìbátan ati ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọkunrin ni ó pa láìdá ẹnikẹ́ni sí. Báyìí ni Simiri ṣe pa gbogbo ìdílé Baaṣa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀, láti ẹnu wolii Jehu, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Baaṣa ati Ela ọmọ rẹ̀ dá ati èyí tí wọ́n mú kí Israẹli dá, tí wọ́n mú kí OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú nítorí oriṣa wọn. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ela ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, Simiri gorí oyè ní Tirisa, ó sì jọba Israẹli fún ọjọ́ meje. Ní àkókò yìí àwọn ọmọ ogun Israẹli gbógun ti ìlú Gibetoni ní ilẹ̀ Filistia. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé, Simiri ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ati pé ó ti pa á, lẹsẹkẹsẹ ni gbogbo Israẹli fi Omiri olórí ogun, jọba Israẹli ninu àgọ́ wọn ní ọjọ́ náà. Omiri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá kúrò ní ìlú Gibetoni, wọ́n lọ dó ti ìlú Tirisa. Nígbà tí Simiri rí i pé ọwọ́ ti tẹ ìlú náà, ó lọ sí ibi ààbò tí ó wà ninu ààfin, ó tiná bọ ààfin, ó sì kú sinu iná; nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, tí ó tọ ọ̀nà tí Jeroboamu tọ̀, ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá: tí ó mú kí àwọn ọmọ Israẹli náà dẹ́ṣẹ̀. Gbogbo nǹkan yòókù tí Simiri ṣe: gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Lẹ́yìn ikú Simiri àwọn ọmọ Israẹli pín sí ọ̀nà meji. Àwọn kan wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati, pé òun ni kí ó jọba. Àwọn yòókù sì wà lẹ́yìn Omiri. Níkẹyìn, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Omiri ṣẹgun àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati. Tibini kú, Omiri sì jọba. Ní ọdún kọkanlelọgbọn tí Asa, ọba Juda ti wà lórí oyè, ni Omiri gorí oyè ní Israẹli. Ó sì jọba fún ọdún mejila. Ìlú Tirisa ni ó gbé fún ọdún mẹfa àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, ó ra òkè Samaria ní ìwọ̀n talẹnti fadaka meji, lọ́wọ́ ọkunrin kan tí ń jẹ́ Ṣemeri. Omiri mọ odi yí òkè náà ká, ó sì sọ orúkọ ìlú tí ó kọ́ náà ní Samaria, gẹ́gẹ́ bí orúkọ Ṣemeri, ẹni tí ó ni òkè náà tẹ́lẹ̀. Nǹkan tí Omiri ṣe burú lójú OLUWA, ibi tí ó ṣe pọ̀ ju ti gbogbo àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ lọ. Gbogbo ọ̀nà burúkú tí Jeroboamu ọmọ Nebati rìn ni òun náà ń tọ̀. Òun náà jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú nítorí oriṣa tí wọn ń bọ. Àwọn nǹkan yòókù tí Omiri ṣe ati iṣẹ́ akikanju tí ó ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Omiri kú, wọ́n sì sin ín sí Samaria; Ahabu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀. Ní ọdún kejidinlogoji tí Asa, ọba Juda gorí oyè ni Ahabu, ọmọ Omiri gorí oyè ní Israẹli, Ahabu sì jọba lórí Israẹli ní Samaria fún ọdún mejilelogun. Ahabu ọmọ Omiri ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA ju gbogbo àwọn tí wọ́n ṣáájú rẹ̀ lọ. Bí ẹni pé, gbogbo àìdára tí Ahabu ọba ṣe bíi ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, kò burú tó, ó tún lọ fẹ́ Jesebẹli ọmọbinrin Etibaali, ọba Sidoni, ó sì ń bọ oriṣa Baali. Ó tẹ́ pẹpẹ kan fún oriṣa Baali ninu ilé tí ó kọ́ fún oriṣa náà, ní Samaria. Bákan náà, ó tún ṣe oriṣa Aṣera kan. Ahabu ṣe ohun tí ó bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ninu ju gbogbo àwọn ọba Israẹli tí wọ́n jẹ ṣáájú rẹ̀ lọ. Ní àkókò ìgbà tirẹ̀ ni Hieli ará Bẹtẹli tún ìlú Jẹriko kọ́. Abiramu àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin kú, nígbà tí Hieli fi ìpìlẹ̀ ìlú Jẹriko lélẹ̀. Segubu, àbíkẹ́yìn rẹ̀ ọkunrin sì tún kú bákan náà, nígbà tí ó gbé ìlẹ̀kùn sí ẹnubodè rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀, láti ẹnu Joṣua, ọmọ Nuni.

I. A. Ọba 16:1-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì ṣe, ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ Jehu ọmọ Hanani wá sí Baaṣa pé: “Èmi ti gbé ọ ga láti inú erùpẹ̀ wá, mo sì fi ọ́ ṣe olórí Israẹli ènìyàn mi, ṣùgbọ́n ìwọ sì rìn ní ọ̀nà Jeroboamu, ó sì mú kí Israẹli ènìyàn mi dẹ́ṣẹ̀, láti mú mi bínú nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nítorí náà, èmi yóò mú Baaṣa àti ilé rẹ̀ kúrò, èmi yóò sì ṣe ilé rẹ̀ bí ilé Jeroboamu ọmọ Nebati. Àwọn ajá yóò jẹ ẹni Baaṣa tí ó bá kú ní ìlú, ẹyẹ ojú ọ̀run yóò sì jẹ àwọn tí ó kú ní oko.” Àti ìyókù ìṣe Baaṣa, ohun tí ó ṣe àti agbára rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? Baaṣa sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní Tirsa. Ela ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Ọ̀rọ̀ OLúWA sì wá nípa ọwọ́ Jehu wòlíì ọmọ Hanani pẹ̀lú sí Baaṣa àti ilé rẹ̀, nítorí gbogbo búburú tí ó ti ṣe níwájú OLúWA, ní mímú un bínú nípa ohun tó ti ṣe àti wíwà bí ilé Jeroboamu: àti nítorí tí ó pa á run pẹ̀lú. Ní ọdún kẹrìn-dínlọ́gbọ̀n Asa ọba Juda, Ela ọmọ Baaṣa bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba ní Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Tirsa ní ọdún méjì. Simri, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, olórí ìdajì kẹ̀kẹ́ rẹ̀, dìtẹ̀ sí i. Ela sì wà ní Tirsa nígbà náà, ó sì mu àmupara ní ilé Arsa, ìríjú ilé rẹ̀ ni Tirsa. Simri sì wọlé, ó sì kọlù ú, ó sì pa á ní ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n Asa, ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, bí ó sì ti jókòó lórí ìtẹ́, ó lu gbogbo ilé Baaṣa pa, kò ku ọkùnrin kan sílẹ̀, bóyá ìbátan tàbí ọ̀rẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni Simri pa gbogbo ilé Baaṣa run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó sọ sí Baaṣa nípa ọwọ́ Jehu wòlíì: nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí Baaṣa àti Ela ọmọ rẹ̀ ti ṣẹ̀ àti tí wọ́n ti mú Israẹli ṣẹ̀, tí wọ́n fi mú OLúWA Ọlọ́run Israẹli bínú, wọ́n mú u bínú nípa òrìṣà asán wọn. Ìyókù ìṣe Ela àti gbogbo ohun tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? Ní ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n Asa ọba Juda, ni Simri jẹ ọba ọjọ́ méje ní Tirsa. Àwọn ọmọ-ogun sì dó ti Gibetoni, ìlú àwọn ará Filistini. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli tí ó dó tì gbọ́ wí pé Simri ti dìtẹ̀ sí ọba, ó sì ti pa á, wọ́n kéde Omri, olórí ogun, bí ọba lórí Israẹli ní ọjọ́ náà ní ibùdó. Nígbà náà ni Omri àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ kúrò ní Gibetoni, wọ́n sì dó ti Tirsa. Nígbà tí Simri sì ri pé a ti gba ìlú, ó sì wọ inú ààfin ilé ọba lọ, ó sì tẹ iná bọ ilé ọba lórí ara rẹ̀, ó sì kú, nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀, ní ṣíṣe búburú níwájú OLúWA àti ní rírìn ní ọ̀nà Jeroboamu àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣe àti tí ó ti mú Israẹli ṣẹ̀. Ní ti ìyókù ìṣe Simri, àti ọ̀tẹ̀ rẹ̀ tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? Nígbà náà ní àwọn ènìyàn Israẹli dá sí méjì; apá kan wọn ń tọ Tibni ọmọ Ginati lẹ́yìn, láti fi í jẹ ọba, apá kan tókù sì ń tọ Omri lẹ́yìn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ń tọ Omri lẹ́yìn borí àwọn tí ń tọ Tibni ọmọ Ginati lẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni Tibni kú, Omri sì jẹ ọba. Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Asa ọba Juda, Omri bẹ̀rẹ̀ sí ń jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì jẹ ọba ní ọdún méjìlá, ọdún mẹ́fà ní Tirsa. Ó sì ra òkè Samaria lọ́wọ́ Ṣemeri ní tálẹ́ǹtì méjì fàdákà, ó sì kọ́ ìlú sórí rẹ̀, ó sì pe ìlú náà ní Samaria, nípa orúkọ Ṣemeri, orúkọ ẹni tí ó kọ́kọ́ ni òkè náà. Ṣùgbọ́n Omri sì ṣe búburú níwájú OLúWA, Ó sì ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ. Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà Jeroboamu ọmọ Nebati àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èyí tí ó ti mú Israẹli ṣẹ̀, láti fi ohun asán wọn mú OLúWA, Ọlọ́run Israẹli bínú. Ìyókù ìṣe àti ohun tí Omri ṣe, àti agbára rẹ tí ó fihàn, a kò ha kọ, wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli? Omri sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín ní Samaria. Ahabu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Ní ọdún kejì-dínlógójì Asa ọba Juda, Ahabu ọmọ Omri jẹ ọba ní Israẹli, o si jẹ ọba lórí Israẹli ní Samaria ní ọdún méjìlélógún. Ahabu ọmọ Omri sì ṣe búburú ní ojú OLúWA ju gbogbo àwọn tí ó wà ṣáájú rẹ̀ lọ. Ó sì ṣe bí ẹni pé ó ṣe ohun kékeré fún un láti máa rìn nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, ó sì mú Jesebeli, ọmọbìnrin Etibaali, ọba àwọn ará Sidoni ní aya, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ń sin Baali, ó sì bọ ọ́. Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Baali nínú ilé Baali tí ó kọ́ sí Samaria. Ahabu sì túnṣe ère òrìṣà Aṣerah, ó sì ṣe púpọ̀ láti mú OLúWA Ọlọ́run Israẹli bínú ju èyí tí gbogbo ọba Israẹli tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ ti ṣe lọ. Ní ìgbà ayé Ahabu, Hieli ará Beteli kọ́ Jeriko. Ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀ ní Abiramu, àkọ́bí rẹ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ kọ́ ní Segubu àbíkẹ́yìn rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó ti ipa Joṣua ọmọ Nuni sọ.