I. A. Ọba 15:1-24

I. A. Ọba 15:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ li ọdun kejidilogun Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, Abijah jọba lori Juda. Ọdun mẹta li o jọba ni Jerusalemu: orukọ iya rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu. O si rin ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀, ti o ti dá niwaju rẹ̀: ọkàn rẹ̀ kò si pé pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọkàn Dafidi baba rẹ̀. Ṣugbọn nitori Dafidi li Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fun u ni imọlẹ kan ni Jerusalemu, lati gbé ọmọ rẹ̀ ró lẹhin rẹ̀, ati lati fi idi Jerusalemu mulẹ: Nitori Dafidi ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, kò si yipada kuro ninu gbogbo eyiti o paṣẹ fun u li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, bikoṣe ni kiki ọ̀ran Uriah, ara Hitti. Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo. Njẹ iyokù iṣe Abijah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ogun si wà lãrin Abijah ati Jeroboamu. Abijah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sin i ni ilu Dafidi: Asa, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀. Ati li ogun ọdun Jeroboamu ọba Israeli, ni Asa jọba lori Juda. Ọdun mọkanlelogoji li o jọba ni Jerusalemu, orukọ iya nla rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu. Asa si ṣe eyiti o tọ loju Oluwa, bi Dafidi baba rẹ̀. O si mu awọn ti nṣe panṣaga kuro ni ilẹ na, o si kó gbogbo ere ti awọn baba rẹ̀ ti ṣe kuro. Ati Maaka iya rẹ̀ papã, li o si mu kuro lati ma ṣe ayaba, nitori ti o yá ere kan fun oriṣa rẹ̀; Asa si ke ere na kuro; o si daná sun u nibi odò Kidroni. Ṣugbọn ibi giga wọnnì ni a kò mu kuro; sibẹ ọkàn Asa pé pẹlu Oluwa li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo. O si mu ohun-mimọ́ wọnnì ti baba rẹ̀, ati ohun-mimọ́ wọnnì ti on tikararẹ̀ wọ ile Oluwa, fadaka ati wura, ati ohun-elo wọnnì, Ogun si wà lãrin Asa ati Baaṣa, ọba Israeli ni gbogbo ọjọ wọn. Baaṣa, ọba Israeli, si goke lọ si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má le jẹ ki ẹnikẹni ki o jade tabi ki o wọle tọ Asa ọba lọ. Nigbana ni Asa mu gbogbo fadaka, ati wura ti o kù ninu iṣura ile Oluwa, ati iṣura ile ọba, o si fi wọn si ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀: Asa ọba si rán wọn si ọdọ Benhadadi, ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni, ọba Siria, ti o ngbe Damasku, wipe, Jẹ ki majẹmu ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin baba mi ati baba rẹ, kiye si i, emi ran ọrẹ fadaka ati wura si ọ; wá, ki o si dà majẹmu rẹ pẹlu Baaṣa, ọba Israeli, ki o le lọ kuro lọdọ mi. Bẹ̃ni Benhadadi fi eti si ti Asa ọba, o si rán awọn alagbara olori-ogun ti o ni, si ilu Israeli wọnnì, o si kọlu Ijoni, ati Dani ati Abel-bet-maaka, ati gbogbo Kenneroti pẹlu gbogbo ilẹ Naftali. O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o si ṣiwọ ati kọ́ Rama, o si ngbe Tirsa. Nigbana ni Asa ọba kede ká gbogbo Juda, kò da ẹnikan si: nwọn si kó okuta Rama kuro, ati igi rẹ̀, ti Baaṣa fi kọle: Asa ọba si fi wọn kọ́ Geba ti Benjamini, ati Mispa. Iyokù gbogbo iṣe Asa, ati gbogbo agbara rẹ̀ ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati ilu wọnnì ti o kọ́, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ṣugbọn li akoko ogbó rẹ̀, àrun ṣe e li ẹsẹ rẹ̀. Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

I. A. Ọba 15:1-24 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọdún kejidinlogun tí Jeroboamu jọba Israẹli, ni Abijamu gorí oyè ní ilẹ̀ Juda. Ọdún mẹta ló fi jọba ní Jerusalẹmu. Maaka ọmọ Absalomu ni ìyá rẹ̀. Gbogbo irú ẹ̀ṣẹ̀ tí baba Abijamu dá, ni òun náà dá. Kò fi tọkàntọkàn ṣe olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ bí Dafidi, baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. Sibẹsibẹ, nítorí ti Dafidi, OLUWA Ọlọrun fún Abijamu ní ọmọkunrin kan tí ó gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀, ní Jerusalẹmu, tí ó sì dáàbò bo Jerusalẹmu. Ìdí rẹ̀ ni pé, Dafidi ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, kò sì ṣàìgbọràn sí àṣẹ rẹ̀ rí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, (àfi ohun tí ó ṣe sí Uraya ará Hiti). Ogun tí ó wà láàrin Rehoboamu ati Jeroboamu tún wà bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Abijamu wà lórí oyè. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Abijamu ṣe wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ogun si wà láàrin Abijah ati Jeroboamu. Abijamu jáde láyé, wọ́n sì sin ín ní ìlú Dafidi, Asa, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀. Nígbà tí ó di ogún ọdún tí Jeroboamu ti jọba Israẹli ni Asa gorí oyè ní ilẹ̀ Juda. Ọdún mọkanlelogoji ni ó fi jọba ní Jerusalẹmu. Maaka ọmọ Absalomu ni ìyá baba rẹ̀. Asa ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi Dafidi baba ńlá rẹ̀. Gbogbo àwọn aṣẹ́wó ọkunrin tí wọ́n wà ní ojúbọ àwọn oriṣa káàkiri ní ilẹ̀ Juda, ni Asa lé jáde kúrò ni ilẹ̀ náà; ó sì kó gbogbo àwọn oriṣa tí àwọn baba ńlá rẹ̀ ti ṣe dànù. Ó yọ Maaka, ìyá baba rẹ̀, kúrò lórí oyè ìyá ọba, nítorí pé Maaka yá ère tí ó tini lójú kan fún oriṣa Aṣera. Asa gé oriṣa náà lulẹ̀, ó sì dáná sun ún ní àfonífojì Kidironi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Asa kò pa gbogbo àwọn ojúbọ oriṣa wọn run, ó jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Gbogbo àwọn ohun èlò pẹlu wúrà ati fadaka tí baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ati àwọn tí òun pàápàá yà sọ́tọ̀, ni ó dá pada sinu ilé OLUWA. Nígbà gbogbo ni Asa ọba Juda, ati Baaṣa, ọba Israẹli ń gbógun ti ara wọn, ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà lórí oyè. Baaṣa gbógun ti ilẹ̀ Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi yí Rama po, kí ẹnikẹ́ni má baà rí ààyè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, tabi kí ẹnikẹ́ni jáde kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Asa ọba bá kó gbogbo fadaka ati wúrà tí ó kù ninu ilé ìṣúra ní ilé OLUWA ati ti ààfin ọba jọ, ó kó wọn rán àwọn iranṣẹ rẹ̀ sí Benhadadi ọmọ Tabirimoni, ọmọ Hesioni, ọba ilẹ̀ Siria, tí ó wà ní ìlú Damasku. Asa ní kí wọ́n wí fún Benhadadi, pé, “Jẹ́ kí a ní àjọṣepọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti ṣe; gba wúrà ati fadaka tí mo fi ranṣẹ sí ọ yìí, kí o dẹ́kun àjọṣepọ̀ rẹ pẹlu Baaṣa ọba Israẹli, kí ó lè kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀ mi.” Benhadadi ọba gba ohun tí Asa wí, ó sì rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ láti lọ gbógun ti àwọn ìlú ńláńlá Israẹli. Wọ́n gba ìlú Ijoni ati Dani, Abeli Beti Maaka, ati gbogbo agbègbè Kineroti, pẹlu gbogbo agbègbè Nafutali. Nígbà tí Baaṣa gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó dáwọ́ odi tí ó ń mọ yí Rama dúró, ó sì ń gbé Tirisa. Asa ọba bá kéde ní gbogbo ilẹ̀ Juda, ó ní kí gbogbo eniyan patapata láìku ẹnìkan, lọ kó gbogbo òkúta ati igi ti Baaṣa fi ń mọ odi Rama kúrò ní Rama. Igi ati òkúta náà ni Asa fi mọ odi ìlú Geba tí ó wà ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ati ti ìlú Misipa. Gbogbo nǹkan yòókù tí Asa ọba ṣe, ati àwọn ìwà akin tí ó hù, ati àwọn ìlú tí ó mọ odi yípo, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda, ṣugbọn ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, nǹkankan mú un lẹ́sẹ̀. Asa jáde láyé, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi. Jehoṣafati, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè lẹ́yìn rẹ̀.

I. A. Ọba 15:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọdún kejì-dínlógún ìjọba Jeroboamu ọmọ Nebati, Abijah jẹ ọba lórí Juda, ó sì jẹ ọba ní ọdún mẹ́ta ní Jerusalẹmu. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Maaka, ọmọbìnrin Absalomu. Ó sì rìn nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí baba rẹ̀ ti dá ṣáájú rẹ̀; ọkàn rẹ̀ kò sì pé pẹ̀lú OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti ṣe. Ṣùgbọ́n, nítorí i Dafidi OLúWA Ọlọ́run rẹ̀ fún un ní ìmọ́lẹ̀ kan ní Jerusalẹmu nípa gbígbé ọmọ rẹ̀ ró láti jẹ ọba ní ipò rẹ̀ àti láti fi ìdí Jerusalẹmu múlẹ̀. Nítorí tí Dafidi ṣe èyí tí ó dára ní ojú OLúWA, tí kò sì kùnà láti pa gbogbo èyí tí OLúWA pàṣẹ fún un mọ́ ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo; bí kò ṣe ní kìkì ọ̀ràn Uriah ará Hiti. Ogun sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu ní gbogbo ọjọ́ ayé Abijah. Ní ti ìyókù ìṣe Abijah, àti gbogbo èyí tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ogun sì wà láàrín Abijah àti Jeroboamu. Abijah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Ní ogún ọdún Jeroboamu ọba Israẹli, Asa jẹ ọba lórí Juda, Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu ní ọdún mọ́kànlélógójì. Orúkọ ìyá ńlá rẹ̀ sì ni Maaka, ọmọbìnrin Absalomu. Asa sì ṣe èyí tí ó dára lójú OLúWA, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe. Ó sì mú àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà kúrò ní ilẹ̀ náà, ó sì kó gbogbo ère tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe kúrò. Ó sì mú Maaka ìyá ńlá rẹ̀ kúrò láti máa ṣe ayaba, nítorí tí ó yá ère kan fún Aṣerah òrìṣà rẹ̀. Asa sì ké ère náà lulẹ̀, ó sì jó o ní Àfonífojì Kidironi. Ṣùgbọ́n kò mú àwọn ibi gíga kúrò, síbẹ̀ ọkàn Asa pé pẹ̀lú OLúWA ní ọjọ́ ayé rẹ̀ gbogbo. Ó sì mú wúrà àti fàdákà àti àwọn ohun èlò tí òun àti baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wọ ilé OLúWA. Ogun sì wà láàrín Asa àti Baaṣa ọba Israẹli ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn. Baaṣa, ọba Israẹli sì gòkè lọ sí Juda, ó sì kọ́ Rama láti má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba lọ. Nígbà náà ni Asa mú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó kù nínú ìṣúra ilé OLúWA àti ìṣúra ilé ọba. Ó sì fi lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì rán wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Beni-Hadadi ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni ọba Siria tí ó ń gbé ní Damasku. Ó sì wí pé, “Jẹ́ kí májẹ̀mú kí ó wà láàrín èmi àti ìwọ, bí ó sì ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Wò ó, Èmi rán ọrẹ fàdákà àti wúrà sí ọ. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, da májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Baaṣa, ọba Israẹli, kí ó lè lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.” Beni-Hadadi gba ti Asa ọba, ó sì rán àwọn alágbára olórí ogun rẹ̀ sí àwọn ìlú Israẹli. Ó sì ṣẹ́gun Ijoni, Dani àti Abeli-Beti-Maaka, àti gbogbo Kinnereti pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. Nígbà tí Baaṣa sì gbọ́ èyí, ó sì ṣíwọ́ kíkọ́ Rama, ó sì lọ kúrò sí Tirsa. Nígbà náà ni Asa ọba kéde ká gbogbo Juda, kò dá ẹnìkan sí: wọ́n sì kó òkúta Rama kúrò àti igi rẹ̀, tí Baaṣa fi kọ́lé. Asa ọba sì fi wọ́n kọ́ Geba ti Benjamini àti Mispa. Ní ti ìyókù gbogbo ìṣe Asa, àti gbogbo agbára rẹ̀, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti àwọn ìlú tí ó kọ́, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? Ṣùgbọ́n, ní ìgbà ogbó rẹ̀, ààrùn ṣe é ní ẹsẹ̀ rẹ̀. Asa sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.