I. A. Ọba 15:1-24

I. A. Ọba 15:1-24 YBCV

NJẸ li ọdun kejidilogun Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, Abijah jọba lori Juda. Ọdun mẹta li o jọba ni Jerusalemu: orukọ iya rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu. O si rin ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀, ti o ti dá niwaju rẹ̀: ọkàn rẹ̀ kò si pé pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọkàn Dafidi baba rẹ̀. Ṣugbọn nitori Dafidi li Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fun u ni imọlẹ kan ni Jerusalemu, lati gbé ọmọ rẹ̀ ró lẹhin rẹ̀, ati lati fi idi Jerusalemu mulẹ: Nitori Dafidi ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, kò si yipada kuro ninu gbogbo eyiti o paṣẹ fun u li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, bikoṣe ni kiki ọ̀ran Uriah, ara Hitti. Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo. Njẹ iyokù iṣe Abijah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ogun si wà lãrin Abijah ati Jeroboamu. Abijah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sin i ni ilu Dafidi: Asa, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀. Ati li ogun ọdun Jeroboamu ọba Israeli, ni Asa jọba lori Juda. Ọdun mọkanlelogoji li o jọba ni Jerusalemu, orukọ iya nla rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu. Asa si ṣe eyiti o tọ loju Oluwa, bi Dafidi baba rẹ̀. O si mu awọn ti nṣe panṣaga kuro ni ilẹ na, o si kó gbogbo ere ti awọn baba rẹ̀ ti ṣe kuro. Ati Maaka iya rẹ̀ papã, li o si mu kuro lati ma ṣe ayaba, nitori ti o yá ere kan fun oriṣa rẹ̀; Asa si ke ere na kuro; o si daná sun u nibi odò Kidroni. Ṣugbọn ibi giga wọnnì ni a kò mu kuro; sibẹ ọkàn Asa pé pẹlu Oluwa li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo. O si mu ohun-mimọ́ wọnnì ti baba rẹ̀, ati ohun-mimọ́ wọnnì ti on tikararẹ̀ wọ ile Oluwa, fadaka ati wura, ati ohun-elo wọnnì, Ogun si wà lãrin Asa ati Baaṣa, ọba Israeli ni gbogbo ọjọ wọn. Baaṣa, ọba Israeli, si goke lọ si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má le jẹ ki ẹnikẹni ki o jade tabi ki o wọle tọ Asa ọba lọ. Nigbana ni Asa mu gbogbo fadaka, ati wura ti o kù ninu iṣura ile Oluwa, ati iṣura ile ọba, o si fi wọn si ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀: Asa ọba si rán wọn si ọdọ Benhadadi, ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni, ọba Siria, ti o ngbe Damasku, wipe, Jẹ ki majẹmu ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin baba mi ati baba rẹ, kiye si i, emi ran ọrẹ fadaka ati wura si ọ; wá, ki o si dà majẹmu rẹ pẹlu Baaṣa, ọba Israeli, ki o le lọ kuro lọdọ mi. Bẹ̃ni Benhadadi fi eti si ti Asa ọba, o si rán awọn alagbara olori-ogun ti o ni, si ilu Israeli wọnnì, o si kọlu Ijoni, ati Dani ati Abel-bet-maaka, ati gbogbo Kenneroti pẹlu gbogbo ilẹ Naftali. O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o si ṣiwọ ati kọ́ Rama, o si ngbe Tirsa. Nigbana ni Asa ọba kede ká gbogbo Juda, kò da ẹnikan si: nwọn si kó okuta Rama kuro, ati igi rẹ̀, ti Baaṣa fi kọle: Asa ọba si fi wọn kọ́ Geba ti Benjamini, ati Mispa. Iyokù gbogbo iṣe Asa, ati gbogbo agbara rẹ̀ ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati ilu wọnnì ti o kọ́, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ṣugbọn li akoko ogbó rẹ̀, àrun ṣe e li ẹsẹ rẹ̀. Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.