I. A. Ọba 14:1-31

I. A. Ọba 14:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Li àkoko na, Abijah ọmọ Jeroboamu ṣàisan. Jeroboamu si wi fun aya rẹ̀ pe, Dide, emi bẹ̀ ọ, si pa ara rẹ dà, ki a má ba le mọ̀ ọ li aya Jeroboamu; ki o si lọ si Ṣilo: kiyesi i, nibẹ li Ahijah, woli wà, ti o sọ fun mi pe, emi o jọba lori enia yi. Ki o si mu ìṣu àkara mẹwa li ọwọ́ rẹ, ati akara wẹwẹ, ati igo oyin, ki o si lọ sọdọ rẹ̀: on o si wi fun ọ bi yio ti ri fun ọmọde na. Aya Jeroboamu si ṣe bẹ̃, o si dide, o si lọ si Ṣilo, o si wá si ile Ahijah. Ṣugbọn Ahijah kò riran; nitoriti oju rẹ̀ fọ́ nitori ogbó rẹ̀. Oluwa si wi fun Ahijah, pe, Kiyesi i, aya Jeroboamu mbọ̀ wá bère ohun kan lọwọ rẹ niti ọmọ rẹ̀: nitori ti o ṣàisan: bayi bayi ni ki iwọ ki o wi fun u: yio si ṣe, nigbati o ba wọle, yio ṣe ara rẹ̀ bi ẹlomiran. Bẹ̃ li o si ri, nigbati Ahijah gbọ́ iró ẹsẹ rẹ̀, bi o ti mbọ̀ wá li ẹnu ọ̀na, on si wipe, Wọle wá, iwọ, aya Jeroboamu, ẽṣe ti iwọ fi ṣe ara rẹ bi ẹlomiran? nitori iṣẹ wuwo li a fi rán mi si ọ. Lọ, sọ fun Jeroboamu, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Nitori bi mo ti gbé ọ ga lati inu awọn enia, ti mo si fi ọ jẹ olori Israeli enia mi. Ti mo si fà ijọba ya kuro ni ile Dafidi, mo si fi i fun ọ: sibẹ iwọ kò ri bi Dafidi iranṣẹ mi, ẹniti o pa ofin mi mọ, ti o si tọ̀ mi lẹhin tọkàntọkàn rẹ̀, lati ṣe kiki eyi ti o tọ li oju mi: Ṣugbọn iwọ ti ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o ti wà ṣaju rẹ: nitori iwọ ti lọ, iwọ si ti ṣe awọn ọlọrun miran, ati ere didà, lati ru ibinu mi, ti iwọ si ti gbé mi sọ si ẹhin rẹ: Nitorina, kiyesi i, emi o mu ibi wá si ile Jeroboamu, emi o ke gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Jeroboamu, ati ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli, emi o si mu awọn ti o kù ni ile Jeroboamu kuro, gẹgẹ bi enia ti ikó igbẹ kuro, titi gbogbo rẹ̀ yio fi tan. Ẹni Jeroboamu ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ: ati ẹniti o ba kú ni igbẹ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio jẹ: nitori Oluwa ti sọ ọ. Nitorina, iwọ dide, lọ si ile rẹ: nigbati ẹsẹ rẹ ba si wọ̀ ilu, ọmọ na yio kú. Gbogbo Israeli yio si ṣọ̀fọ rẹ̀, nwọn o si sin i; nitori kiki on nikan li ẹniti yio wá si isa-okú ninu ẹniti iṣe ti Jeroboamu, nitori lọdọ rẹ̀ li a ri ohun rere diẹ sipa Oluwa, Ọlọrun Israeli, ni ile Jeroboamu. Oluwa yio si gbé ọba kan dide lori Israeli, ti yio ke ile Jeroboamu kuro li ọjọ na: ṣugbọn kini? ani nisisiyi! Nitoriti Oluwa yio kọlu Israeli bi a ti imì iye ninu omi, yio si fa Israeli tu kuro ni ilẹ rere yi, ti o ti fi fun awọn baba wọn, yio si fọ́n wọn ka kọja odò na, nitoriti nwọn ṣe ere oriṣa wọn, nwọn si nru ibinu Oluwa. Yio si kọ̀ Israeli silẹ nitori ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ẹniti o ṣẹ̀, ti o si mu Israeli dẹṣẹ. Aya Jeroboamu si dide, o si lọ, o si de Tira: nigbati o si wọ̀ iloro ile, ọmọde na si kú; Nwọn si sin i; gbogbo Israeli si sọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah woli. Ati iyokù iṣe Jeroboamu, bi o ti jagun, ati bi o ti jọba, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli. Awọn ọjọ ti Jeroboamu jọba jẹ ọdun mejilelogun, o si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀. Nadabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Rehoboamu, ọmọ Solomoni, si jọba ni Juda: Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanlelogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni. Juda si ṣe buburu niwaju Oluwa, nwọn si fi ẹ̀ṣẹ wọn mu u jowu jù gbogbo eyiti baba wọn ti ṣe, ti nwọn si ti dá. Nitori awọn pẹlu kọ́ ibi giga fun ara wọn, ati ere, ati igbo-oriṣa lori gbogbo oke giga, ati labẹ gbogbo igi tutu. Awọn ti nhùwa panṣaga mbẹ ni ilẹ na: nwọn si ṣe gẹgẹ bi gbogbo ohun irira awọn orilẹ-ède ti Oluwa lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli. O si ṣe li ọdun karun Rehoboamu ọba, Ṣiṣaki, ọba Egipti goke wá si Jerusalemu: O si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; ani gbogbo rẹ̀ li o kó lọ: o si kó gbogbo asà wura ti Solomoni ti ṣe lọ. Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn si ọwọ́ olori awọn oluṣọ ti nṣọ ilẹkun ile ọba. Bẹ̃li o si ri, nigbati ọba ba nlọ si ile Oluwa, nwọn a rù wọn, nwọn a si mu wọn pada sinu yara oluṣọ. Iyokù iṣe Rehoboamu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ wọn gbogbo. Rehoboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni. Abijah, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

I. A. Ọba 14:1-31 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò yìí Abija, ọmọ Jeroboamu ọba ṣàìsàn, Jeroboamu wí fún aya rẹ̀ pé, “Dìde, kí o yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má lè dá ọ mọ̀ pé aya ọba ni ọ́. Lọ sí Ṣilo níbi tí wolii Ahija tí ó wí fún mi pé n óo jọba Israẹli, ń gbé. Mú burẹdi mẹ́wàá, àkàrà dídùn díẹ̀, ati ìgò oyin kan lọ́wọ́ fún un, yóo sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ náà fún ọ.” Aya Jeroboamu sì ṣe bí Jeroboamu ti wí. Ó lọ sí ilé wolii Ahija ní Ṣilo. Ogbó ti dé sí Ahija ní àkókò yìí, kò sì ríran mọ́, ṣugbọn OLUWA ti sọ fún un pé aya Jeroboamu ń bọ̀ wá bèèrè ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ̀ tí ó ń ṣàìsàn, OLUWA sì ti sọ ohun tí Ahija yóo sọ fún un. Nígbà tí aya Jeroboamu dé, ó ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni. Ṣugbọn bí Ahija ti gbúròó rẹ̀ tí ó ń wọlé bọ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wọlé, ìwọ aya Jeroboamu. Kí ló dé tí o fi ń ṣe bí ẹni pé ẹlòmíràn ni ọ́? Ìròyìn burúkú ni mo ní fún ọ. Lọ sọ fún Jeroboamu pé, ‘OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “Mo gbé ọ ga láàrin àwọn eniyan náà, mo sì fi ọ́ jọba lórí Israẹli, àwọn eniyan mi. Mo gba ìjọba lọ́wọ́ ìdílé Dafidi, mo sì fún ọ, o kò ṣe bíi Dafidi, iranṣẹ mi, tí ó pa òfin mi mọ́, tí ó sìn mí tọkàntọkàn, tí ó sì ṣe kìkì ohun tí ó dára lójú mi. Ṣugbọn o ti dá ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ burúkú ju ti àwọn tí wọ́n jọba ṣáájú rẹ lọ. O yá ère, o sì dá oniruuru oriṣa láti máa sìn, o mú mi bínú, o sì ti pada lẹ́yìn mi. Nítorí náà, n óo jẹ́ kí ibi bá ìdílé rẹ, n óo sì pa gbogbo ọkunrin inú ìdílé rẹ run, àtẹrú àtọmọ. Bí ìgbà tí eniyan bá sun pàǹtí, tí ó sì jóná ráúráú ni n óo pa gbogbo ìdílé rẹ run. Ajá ni yóo jẹ òkú ẹnikẹ́ni ninu ìdílé rẹ tí ó bá kú láàrin ìlú; ẹni tí ó bá sì kú sinu igbó, ẹyẹ ni yóo jẹ òkú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí.” ’ “Nítorí náà, dìde kí o pada sílé, ṣugbọn bí o bá ti ń wọ ìlú, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ náà yóo kú. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, wọn yóo sì sin ín, nítorí òun nìkan ni wọ́n óo sin ninu ìdílé Jeroboamu, nítorí òun nìkan ni inú OLUWA Ọlọrun Israẹli dùn sí. OLUWA yóo fi ẹnìkan jọba lórí Israẹli tí yóo run ìdílé Jeroboamu lónìí, àní láti ìsinsìnyìí lọ. OLUWA yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà, wọn óo sì máa gbọ̀n bí ewé ojú omi. OLUWA yóo fà wọ́n tu kúrò ninu ilẹ̀ dáradára tí ó fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì fọ́n wọn káàkiri òdìkejì odò Yufurate, nítorí ère oriṣa Aṣerimu tí wọ́n ṣe tí ó mú OLUWA bínú. Yóo kọ Israẹli sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu dá ati èyí tí ó mú kí Israẹli dá pẹlu.” Aya Jeroboamu bá gbéra, ó pada sí Tirisa. Bí ó ti fẹ́ wọlé ni ọmọ tí ń ṣàìsàn náà kú. Àwọn ọmọ Israẹli sin ín, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA gba ẹnu wolii Ahija, iranṣẹ rẹ̀ sọ. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jeroboamu ọba ṣe: àwọn ogun tí ó jà, ati bí ó ti ṣe ṣe ìjọba rẹ̀, gbogbo rẹ̀ wà ninu ìwé àkọsílẹ̀ Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli. Jeroboamu jọba fún ọdún mejilelogun. Lẹ́yìn náà, ó kú, wọ́n sì sin ín. Nadabu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ẹni ọdún mọkanlelogoji ni Rehoboamu ọmọ Solomoni nígbà tí ó gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda, ọdún mẹtadinlogun ni ó fi jọba ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin gbogbo ilẹ̀ Israẹli fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ̀. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀. Àwọn ẹ̀yà Juda ṣẹ̀ sí OLUWA, wọ́n sì ṣe ohun tí ó mú un bínú lọpọlọpọ ju gbogbo àwọn baba ńlá wọn lọ. Nítorí wọ́n kọ́ pẹpẹ ìrúbọ, wọ́n sì ri ọ̀wọ̀n òkúta ati ère oriṣa Aṣerimu mọ́lẹ̀ lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ igi tútù káàkiri. Àwọn ọkunrin tí wọ́n sọ ara wọn di aṣẹ́wó ní ojúbọ àwọn oriṣa náà sì pọ̀ ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe, ni àwọn náà ń ṣe. Ní ọdún karun-un ìjọba Rehoboamu, Ṣiṣaki, ọba Ijipti, gbógun ti Jerusalẹmu. Ó kó gbogbo ìṣúra tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti ààfin ọba pátá; gbogbo apata wúrà tí Solomoni ṣe ni ó kó lọ pẹlu. Rehoboamu bá ṣe apata idẹ dípò wọn. Ó sì fi àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ààfin ọba ṣe alabojuto wọn. Nígbàkúùgbà tí ọba bá ń lọ sinu ilé OLUWA, àwọn ẹ̀ṣọ́ á gbé apata náà tẹ̀lé e, wọn á sì dá wọn pada sinu ilé ìṣúra lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Rehoboamu ọba ṣe ni a kọ sílẹ̀ ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. Ní gbogbo ìgbà ayé Rehoboamu ati ti Jeroboamu ni àwọn mejeeji í máa gbógun ti ara wọn. Rehoboamu jáde láyé, wọ́n sì sin ín sinu ibojì ọba, ní ìlú Dafidi. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀. Abijamu ọmọ rẹ̀ ni ó sì gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀.

I. A. Ọba 14:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní àkókò náà Abijah ọmọ Jeroboamu sì ṣàìsàn, Jeroboamu sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́n ní aya Jeroboamu. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣilo. Ahijah wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yìí. Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì sọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.” Bẹ́ẹ̀ ni aya Jeroboamu sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Ahijah ní Ṣilo. Ahijah kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀. Ṣùgbọ́n OLúWA ti sọ fún Ahijah pé, “Kíyèsi i, aya Jeroboamu ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí, nígbà tí Ahijah sì gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà, ó sì wí pé, “Wọlé wá, aya Jeroboamu. Kí ló dé tí ìwọ fi ṣe ara rẹ bí ẹlòmíràn? A ti fi iṣẹ́ búburú rán mi sí ọ. Lọ, sọ fún Jeroboamu pé báyìí ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí; Èmi sì gbé ọ ga láti inú àwọn ènìyàn, mo sì fi ọ́ jẹ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi. Mo fa ìjọba náà ya kúrò ní ilé Dafidi, mo sì fi fún ọ ṣùgbọ́n, ìwọ kò dàbí Dafidi ìránṣẹ́ mi, tí ó pa àṣẹ mi mọ́, tí ó sì tọ̀ mí lẹ́yìn tọkàntọkàn rẹ̀, láti ṣe kìkì èyí tí ó tọ́ ní ojú mi. Ìwọ sì ti ṣe búburú ju gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú rẹ lọ. Ìwọ sì ti ṣe àwọn ọlọ́run mìíràn fún ara rẹ, àwọn òrìṣà tí a gbẹ́; o sì ti mú mi bínú, o sì ti gbé mi sọ sí ẹ̀yìn rẹ. “ ‘Nítorí èyí, Èmi yóò mú ibi wá sí ilé Jeroboamu. Èmi yóò ké gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ Jeroboamu, àti ọmọ ọ̀dọ̀ àti òmìnira ní Israẹli. Èmi yóò mú ilé Jeroboamu kúrò bí ènìyàn ti ń kó ìgbẹ́ kúrò, títí gbogbo rẹ̀ yóò fi tán. Ajá yóò jẹ ẹni Jeroboamu tí ó bá kú ní ìlú, àti ẹni tí ó bá kú ní igbó ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ. OLúWA ti sọ ọ́!’ “Ní ti ìwọ, padà lọ ilé, nígbà tí o bá sì fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ ìlú, ọmọ náà yóò kú. Gbogbo Israẹli yóò sì ṣọ̀fọ̀ fún un, wọn yóò sì sin ín. Òun nìkan ni a ó sì sin nínú ẹni tí ń ṣe ti Jeroboamu, nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ni a ti rí ohun rere díẹ̀ sípa OLúWA Ọlọ́run Israẹli, ní ilé Jeroboamu. “OLúWA yóò gbé ọba kan dìde fúnrarẹ̀ lórí Israẹli tí yóò ké ilé Jeroboamu kúrò. Ọjọ́ náà nìyìí! Kí ni? Àní nísinsin yìí. OLúWA yóò kọlu Israẹli, yóò sì dàbí koríko ti ń mì nínú omi. Yóò sì fa Israẹli tu kúrò ní ilẹ̀ rere yìí, tí ó ti fi fún àwọn baba wọn, yóò sì fọ́n wọn ká kọjá odò Eufurate, nítorí wọ́n ti rú ìbínú OLúWA nípa ṣíṣe ère Aṣerah. Yóò sì kọ Israẹli sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu ti ṣẹ̀ àti tí ó mú Israẹli ṣẹ̀.” Nígbà náà ni aya Jeroboamu sì dìde, ó sì lọ, ó sì lọ sí Tirsa. Bí ó sì ti fi ẹsẹ̀ tẹ ìloro ilé, ọmọdé náà sì kú. Wọ́n sì sin ín, gbogbo Israẹli sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti wí láti ẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀, Ahijah wòlíì. Ìyókù ìṣe Jeroboamu, bí ó ti jagun, àti bí ó ti jẹ ọba, ni a kọ sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli. Jeroboamu sì jẹ ọba fún ọdún méjìlélógún, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Nadabu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Rehoboamu ọmọ Solomoni sì jẹ ọba ní Juda. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní ọdún mọ́kànlélógún ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLúWA ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama, ará Ammoni. Juda sì ṣe búburú níwájú OLúWA nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn tí wọ́n ti dá, wọ́n sì mú u jowú ju gbogbo èyí tí baba wọn ti ṣe lọ. Wọ́n sì tún kọ́ ibi gíga fún ara wọn, àti ère òkúta àti òpó Aṣerah lórí gbogbo òkè gíga, àti lábẹ́ gbogbo igi tútù. Àwọn tí wọn jẹ́ ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà wà ní ilẹ̀ náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí OLúWA ti lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ó sì ṣe ní ọdún karùn-ún Rehoboamu, Ṣiṣaki ọba Ejibiti kọlu Jerusalẹmu. Ó sì kó ìṣúra ilé OLúWA lọ àti ìṣúra ilé ọba. Gbogbo rẹ̀ ni ó kó lọ, pẹ̀lú asà wúrà tí Solomoni ti ṣe. Rehoboamu ọba sì ṣe asà idẹ ní ipò wọn, ó sì fi wọ́n sí ọwọ́ olórí àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlẹ̀kùn ilé ọba. Nígbàkígbà tí ọba bá sì lọ sí ilé OLúWA Wọ́n á rù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn padà sínú yàrá olùṣọ́. Ní ti ìyókù ìṣe Rehoboamu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ǹjẹ́ a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda bí? Ogun sì wà láàrín Rehoboamu àti Jeroboamu ní ọjọ́ wọn gbogbo. Rehoboamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní Ìlú Dafidi. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Naama; ará Ammoni. Abijah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.