I. A. Ọba 14
14
Ikú ọmọ Jeroboamu ọkunrin
1Li àkoko na, Abijah ọmọ Jeroboamu ṣàisan.
2Jeroboamu si wi fun aya rẹ̀ pe, Dide, emi bẹ̀ ọ, si pa ara rẹ dà, ki a má ba le mọ̀ ọ li aya Jeroboamu; ki o si lọ si Ṣilo: kiyesi i, nibẹ li Ahijah, woli wà, ti o sọ fun mi pe, emi o jọba lori enia yi.
3Ki o si mu ìṣu àkara mẹwa li ọwọ́ rẹ, ati akara wẹwẹ, ati igo oyin, ki o si lọ sọdọ rẹ̀: on o si wi fun ọ bi yio ti ri fun ọmọde na.
4Aya Jeroboamu si ṣe bẹ̃, o si dide, o si lọ si Ṣilo, o si wá si ile Ahijah. Ṣugbọn Ahijah kò riran; nitoriti oju rẹ̀ fọ́ nitori ogbó rẹ̀.
5Oluwa si wi fun Ahijah, pe, Kiyesi i, aya Jeroboamu mbọ̀ wá bère ohun kan lọwọ rẹ niti ọmọ rẹ̀: nitori ti o ṣàisan: bayi bayi ni ki iwọ ki o wi fun u: yio si ṣe, nigbati o ba wọle, yio ṣe ara rẹ̀ bi ẹlomiran.
6Bẹ̃ li o si ri, nigbati Ahijah gbọ́ iró ẹsẹ rẹ̀, bi o ti mbọ̀ wá li ẹnu ọ̀na, on si wipe, Wọle wá, iwọ, aya Jeroboamu, ẽṣe ti iwọ fi ṣe ara rẹ bi ẹlomiran? nitori iṣẹ wuwo li a fi rán mi si ọ.
7Lọ, sọ fun Jeroboamu, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Nitori bi mo ti gbé ọ ga lati inu awọn enia, ti mo si fi ọ jẹ olori Israeli enia mi.
8Ti mo si fà ijọba ya kuro ni ile Dafidi, mo si fi i fun ọ: sibẹ iwọ kò ri bi Dafidi iranṣẹ mi, ẹniti o pa ofin mi mọ, ti o si tọ̀ mi lẹhin tọkàntọkàn rẹ̀, lati ṣe kiki eyi ti o tọ li oju mi:
9Ṣugbọn iwọ ti ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o ti wà ṣaju rẹ: nitori iwọ ti lọ, iwọ si ti ṣe awọn ọlọrun miran, ati ere didà, lati ru ibinu mi, ti iwọ si ti gbé mi sọ si ẹhin rẹ:
10Nitorina, kiyesi i, emi o mu ibi wá si ile Jeroboamu, emi o ke gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Jeroboamu, ati ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli, emi o si mu awọn ti o kù ni ile Jeroboamu kuro, gẹgẹ bi enia ti ikó igbẹ kuro, titi gbogbo rẹ̀ yio fi tan.
11Ẹni Jeroboamu ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ: ati ẹniti o ba kú ni igbẹ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio jẹ: nitori Oluwa ti sọ ọ.
12Nitorina, iwọ dide, lọ si ile rẹ: nigbati ẹsẹ rẹ ba si wọ̀ ilu, ọmọ na yio kú.
13Gbogbo Israeli yio si ṣọ̀fọ rẹ̀, nwọn o si sin i; nitori kiki on nikan li ẹniti yio wá si isa-okú ninu ẹniti iṣe ti Jeroboamu, nitori lọdọ rẹ̀ li a ri ohun rere diẹ sipa Oluwa, Ọlọrun Israeli, ni ile Jeroboamu.
14Oluwa yio si gbé ọba kan dide lori Israeli, ti yio ke ile Jeroboamu kuro li ọjọ na: ṣugbọn kini? ani nisisiyi!
15Nitoriti Oluwa yio kọlu Israeli bi a ti imì iye ninu omi, yio si fa Israeli tu kuro ni ilẹ rere yi, ti o ti fi fun awọn baba wọn, yio si fọ́n wọn ka kọja odò na, nitoriti nwọn ṣe ere oriṣa wọn, nwọn si nru ibinu Oluwa.
16Yio si kọ̀ Israeli silẹ nitori ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ẹniti o ṣẹ̀, ti o si mu Israeli dẹṣẹ.
17Aya Jeroboamu si dide, o si lọ, o si de Tira: nigbati o si wọ̀ iloro ile, ọmọde na si kú;
18Nwọn si sin i; gbogbo Israeli si sọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah woli.
Ikú Jeroboamu
19Ati iyokù iṣe Jeroboamu, bi o ti jagun, ati bi o ti jọba, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.
20Awọn ọjọ ti Jeroboamu jọba jẹ ọdun mejilelogun, o si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀. Nadabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Rehoboamu, Ọba Juda
(II. Kro 11:5—12:15)
21Rehoboamu, ọmọ Solomoni, si jọba ni Juda: Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanlelogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni.
22Juda si ṣe buburu niwaju Oluwa, nwọn si fi ẹ̀ṣẹ wọn mu u jowu jù gbogbo eyiti baba wọn ti ṣe, ti nwọn si ti dá.
23Nitori awọn pẹlu kọ́ ibi giga fun ara wọn, ati ere, ati igbo-oriṣa lori gbogbo oke giga, ati labẹ gbogbo igi tutu.
24Awọn ti nhùwa panṣaga mbẹ ni ilẹ na: nwọn si ṣe gẹgẹ bi gbogbo ohun irira awọn orilẹ-ède ti Oluwa lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli.
25O si ṣe li ọdun karun Rehoboamu ọba, Ṣiṣaki, ọba Egipti goke wá si Jerusalemu:
26O si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; ani gbogbo rẹ̀ li o kó lọ: o si kó gbogbo asà wura ti Solomoni ti ṣe lọ.
27Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn si ọwọ́ olori awọn oluṣọ ti nṣọ ilẹkun ile ọba.
28Bẹ̃li o si ri, nigbati ọba ba nlọ si ile Oluwa, nwọn a rù wọn, nwọn a si mu wọn pada sinu yara oluṣọ.
29Iyokù iṣe Rehoboamu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
30Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ wọn gbogbo.
31Rehoboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni. Abijah, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. A. Ọba 14: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.