I. A. Ọba 12:6-15

I. A. Ọba 12:6-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

Rehoboamu ọba si ba awọn àgbagba, ti imã duro niwaju Solomoni, baba rẹ̀, nigbati o wà lãye, gbimọ̀ wipe, Imọran kili ẹnyin dá, ki emi ki o lè da awọn enia yi lohùn? Nwọn si wi fun u pe, Bi iwọ o ba jẹ iranṣẹ fun awọn enia yi loni, ti iwọ o si sin wọn, ti iwọ o si da wọn lohùn, ati ti iwọ o sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ṣe iranṣẹ rẹ titi lai. Ṣugbọn o kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti nwọn dagba pẹlu rẹ̀, ti nwọn si duro niwaju rẹ̀ gbimọ̀. O si wi fun wọn pe, Imọran kini ẹnyin dá ki awa ki o le dá awọn enia yi lohùn, ti nwọn ba mi sọ wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi si wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ? Awọn ipẹrẹ ti o dagba pẹlu rẹ̀ wi fun u pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn enia yi ti nwọn ba ọ sọ wipe, Baba rẹ mu ki àjaga wa di wuwo, sugbọn iwọ mu ki o fuyẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o sọ fun wọn: ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ. Njẹ nisisiyi, baba mi ti gbe àjaga wuwo kà nyin, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi ti fi paṣan nà nyin, sugbọn emi o fi akẽke nà nyin. Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo awọn enia na wá sọdọ Rehoboamu ni ijọ kẹta, gẹgẹ bi ọba ti dá wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta. Ọba si da awọn enia li ohùn akọ, o si kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá. O si sọ fun wọn gẹgẹ bi ìmọran awọn ipẹrẹ wipe, Baba mi mu ki àjaga nyin ki o wuwo, emi o si bù kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin, Ọba kò si fi eti si ti awọn enia na; nitoriti ọ̀ran na ati ọwọ Oluwa wá ni, ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti Oluwa ti ọwọ Ahijah, ara Ṣilo, sọ fun Jeroboamu, ọmọ Nebati.

I. A. Ọba 12:6-15 Yoruba Bible (YCE)

Rehoboamu ọba bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n jẹ́ olùdámọ̀ràn Solomoni baba rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀, ó bi wọ́n léèrè pé, “Irú ìdáhùn wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe bí iranṣẹ fún àwọn eniyan wọnyi lónìí, tí o sì sìn wọ́n, tí o sì fún wọn ní èsì rere sí ìbéèrè tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ ni wọn óo máa sìn títí lae.” Ṣugbọn ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jíròrò pẹlu àwọn ọdọmọkunrin, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọ́n wà ní ààfin pẹlu rẹ̀. Ó bi wọ́n léèrè, ó ní, “Kí ni ìmọ̀ràn tí ẹ lè gbà mí, lórí irú ìdáhùn tí a le fún àwọn eniyan tí wọ́n ní kí n dín ẹrù wúwo tí baba mi dì lé àwọn lórí kù?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ohun tí o óo wí fún àwọn tí wọ́n ní baba rẹ di ẹrù wúwo lé àwọn lórí, ṣugbọn kí o bá àwọn dín ẹrù yìí kù ni pé ìka ọwọ́ rẹ tí ó kéré jùlọ tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba rẹ lọ. Sọ fún wọn pé, ‘Ṣé ẹ sọ pé ẹrù wúwo ni baba mi dì rù yín? Tèmi tí n óo dì rù yín yóo tilẹ̀ tún wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ; ati pé ẹgba ni baba mi fi ń nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.’ ” Jeroboamu ati gbogbo àwọn eniyan náà bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wọn. Rehoboamu gbójú mọ́ àwọn eniyan náà bí ó ti ń dá wọn lóhùn, ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọdọmọkunrin ti gbà á nímọ̀ràn. Ó ní, “Ẹrù wúwo ni ẹ sọ pé baba mi dì rù yín, ṣugbọn èmi yóo tilẹ̀ tún dì kún un ni. Ẹgba ni ó fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.” Nítorí náà, ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé OLUWA alára ni ó fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí rí bẹ́ẹ̀, kí ọ̀rọ̀ OLUWA lè ṣẹ, tí ó bá Jeroboamu ọmọ Nebati sọ, láti ẹnu wolii Ahija ará Ṣilo.

I. A. Ọba 12:6-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Rehoboamu ọba fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn àgbàgbà tí ń dúró níwájú Solomoni baba rẹ̀ nígbà tí ó wà láààyè. Ó sì béèrè pé, “Ìmọ̀ràn wo ni ẹ̀yin yóò gbà mí láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá jẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí lónìí, kí o sì sìn wọ́n, àti kí o sì sọ ọ̀rọ̀ rere sí wọn nígbà tí ìwọ bá ń dá wọn lóhùn, wọn yóò máa ṣe ìránṣẹ́ rẹ títí láé.” Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín. Ó sì bi wọ́n pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni a ó ṣe dá àwọn ènìyàn yí lóhùn, tí wọ́n wí fún mi pé, Ṣé kí àjàgà tí baba rẹ fi sí wa lọ́rùn kí ó fúyẹ́ díẹ̀?” Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, ‘Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa’; sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ. Baba mi ti gbé àjàgà wúwo lé e yín; Èmi yóò sì fi kún àjàgà yín. Baba mi ti fi pàṣán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.” Jeroboamu àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ọba ti wí pé, “Ẹ padà tọ̀ mí wá ní ọjọ́ kẹta.” Ọba sì fi ohùn líle dá àwọn ènìyàn lóhùn, ó sì kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbàgbà fún un, Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo; Èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i; Baba mi fi pàṣán nà yín; Èmi yóò fi àkéekèe nà yín.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fi etí sí ti àwọn ènìyàn, nítorí tí ọ̀ràn náà ti ọwọ́ OLúWA wá láti mú ọ̀rọ̀ tí ó sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati láti ẹnu Ahijah ará Ṣilo ṣẹ.