ÀWỌN ỌBA KINNI 12:6-15

ÀWỌN ỌBA KINNI 12:6-15 YCE

Rehoboamu ọba bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n jẹ́ olùdámọ̀ràn Solomoni baba rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀, ó bi wọ́n léèrè pé, “Irú ìdáhùn wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe bí iranṣẹ fún àwọn eniyan wọnyi lónìí, tí o sì sìn wọ́n, tí o sì fún wọn ní èsì rere sí ìbéèrè tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ ni wọn óo máa sìn títí lae.” Ṣugbọn ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jíròrò pẹlu àwọn ọdọmọkunrin, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọ́n wà ní ààfin pẹlu rẹ̀. Ó bi wọ́n léèrè, ó ní, “Kí ni ìmọ̀ràn tí ẹ lè gbà mí, lórí irú ìdáhùn tí a le fún àwọn eniyan tí wọ́n ní kí n dín ẹrù wúwo tí baba mi dì lé àwọn lórí kù?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ohun tí o óo wí fún àwọn tí wọ́n ní baba rẹ di ẹrù wúwo lé àwọn lórí, ṣugbọn kí o bá àwọn dín ẹrù yìí kù ni pé ìka ọwọ́ rẹ tí ó kéré jùlọ tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba rẹ lọ. Sọ fún wọn pé, ‘Ṣé ẹ sọ pé ẹrù wúwo ni baba mi dì rù yín? Tèmi tí n óo dì rù yín yóo tilẹ̀ tún wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ; ati pé ẹgba ni baba mi fi ń nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.’ ” Jeroboamu ati gbogbo àwọn eniyan náà bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wọn. Rehoboamu gbójú mọ́ àwọn eniyan náà bí ó ti ń dá wọn lóhùn, ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọdọmọkunrin ti gbà á nímọ̀ràn. Ó ní, “Ẹrù wúwo ni ẹ sọ pé baba mi dì rù yín, ṣugbọn èmi yóo tilẹ̀ tún dì kún un ni. Ẹgba ni ó fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.” Nítorí náà, ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé OLUWA alára ni ó fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí rí bẹ́ẹ̀, kí ọ̀rọ̀ OLUWA lè ṣẹ, tí ó bá Jeroboamu ọmọ Nebati sọ, láti ẹnu wolii Ahija ará Ṣilo.