I. A. Ọba 12:25-33

I. A. Ọba 12:25-33 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbana ni Jeroboamu kọ́ Ṣekemu li oke Efraimu o si ngbe inu rẹ̀; o si jade lati ibẹ lọ, o si kọ́ Penueli. Jeroboamu si wi li ọkàn rẹ̀ pe, Nisisiyi ni ijọba na yio pada si ile Dafidi: Bi awọn enia wọnyi ba ngoke lọ lati ṣe irubọ ni ile Oluwa ni Jerusalemu, nigbana li ọkàn awọn enia yi yio tun yipada sọdọ oluwa wọn, ani sọdọ Rehoboamu, ọba Juda, nwọn o si pa mi, nwọn o si tun pada tọ̀ Rehoboamu, ọba Juda lọ. Ọba si gbìmọ, o si ya ẹgbọ̀rọ malu wura meji, o si wi fun wọn pe, O pọ̀ju fun nyin lati mã goke lọ si Jerusalemu: Israeli, wò awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wá! O si gbe ọkan kalẹ ni Beteli, ati ekeji li o fi si Dani. Nkan yi si di ẹ̀ṣẹ: nitori ti awọn enia lọ lati sìn niwaju ọkan, ani titi de Dani. O si kọ́ ile ibi giga wọnni, o si ṣe alufa lati inu awọn enia, ti kì iṣe inu awọn ọmọ Lefi. Jeroboamu si dá àse silẹ li oṣu kẹjọ, li ọjọ kẹdogun oṣu, gẹgẹ bi àse ti o wà ni Juda, o si gun ori pẹpẹ na lọ: bẹ̃ni o si ṣe ni Beteli, o rubọ si awọn ọmọ-malu ti o ṣe: o si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti o ti ṣe si Beteli. O si gun ori pẹpẹ na lọ ti o ti ṣe ni Beteli li ọjọ kẹdogun oṣu kẹjọ, li oṣu ti o rò li ọkàn ara rẹ̀; o si da àse silẹ fun awọn ọmọ Israeli; o si gun ori pẹpẹ na lọ, lati fi turari jona.

I. A. Ọba 12:25-33 Yoruba Bible (YCE)

Jeroboamu ọba Israẹli mọ odi yí ìlú Ṣekemu, tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ká, ó sì ń gbé ibẹ̀. Lẹ́yìn náà, láti Ṣekemu ó lọ mọ odi yí ìlú Penueli ká. Nígbà tí ó yá, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìjọba yìí yóo pada di ti ilé Dafidi.” Ó ní, “Bí àwọn eniyan wọnyi bá ń lọ rúbọ ní ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, ọkàn gbogbo wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ pada sẹ́yìn Rehoboamu, oluwa wọn; wọn óo sì pa mí, wọn óo sì pada tọ Rehoboamu, ọba Juda, lọ.” Jeroboamu lọ gba àmọ̀ràn, ó bá fi wúrà yá ère akọ mààlúù meji, ó sì wí fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ó pẹ́ tí ẹ ti ń lọ rúbọ ní Jerusalẹmu. Ó tó gẹ́ẹ́! Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.” Ó gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní ìlú Bẹtẹli ó sì gbé ekeji sí ìlú Dani. Ọ̀rọ̀ yìí di ẹ̀ṣẹ̀ sí wọn lọ́rùn nítorí pé àwọn eniyan náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìlú Bẹtẹli ati ìlú Dani láti jọ́sìn. Jeroboamu tún kọ́ àwọn pẹpẹ ìrúbọ sí orí òkè káàkiri, ó sì yan àwọn eniyan ninu gbogbo ìdílé tí kì í ṣe ìran ẹ̀yà Lefi, láti máa ṣiṣẹ́ alufaa. Jeroboamu ya ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún ilẹ̀ Juda, ó sì rúbọ lórí pẹpẹ sí akọ mààlúù tí ó fi wúrà ṣe ní ìlú Bẹtẹli. Ó fi àwọn alufaa kan sibẹ, láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa ninu àwọn ilé ìsìn tí ó kọ́ sibẹ. Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ tíí ṣe ọjọ́ tí ó yàn fún ara rẹ̀, ó lọ sí ibi pẹpẹ tí ó kọ́ sí ìlú Bẹtẹli láti rúbọ. Ó yan àjọ̀dún fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì lọ sun turari lórí pẹpẹ.

I. A. Ọba 12:25-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Jeroboamu kọ́ Ṣekemu ní òkè Efraimu, ó sì ń gbé inú rẹ̀. Láti ibẹ̀ ó sì jáde lọ, ó sì kọ́ Penieli. Jeroboamu rò nínú ara rẹ̀ pé, “Ìjọba náà yóò padà nísinsin yìí sí ilé Dafidi. Bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá gòkè lọ láti ṣe ìrúbọ ní ilé OLúWA ní Jerusalẹmu, wọn yóò tún fi ọkàn wọn fún OLúWA wọn, Rehoboamu ọba Juda. Wọn yóò sì pa mí, wọn yóò sì tún padà tọ Rehoboamu ọba Juda lọ.” Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọrọ màlúù wúrà méjì. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Israẹli, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Ejibiti wá.” Ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní Beteli, àti èkejì ní Dani. Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀; àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dani láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀. Jeroboamu sì kọ́ ojúbọ sórí ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe inú àwọn ọmọ Lefi. Jeroboamu sì dá àsè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àsè tí ó wà ní Juda, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Beteli, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Beteli. Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ, oṣù tí ó rò ní ọkàn ara rẹ̀, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó kọ́ ní Beteli. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá àsè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì gun orí pẹpẹ náà lọ láti rú ẹbọ.