1 Ọba 12:25-33

1 Ọba 12:25-33 YCB

Nígbà náà ni Jeroboamu kọ́ Ṣekemu ní òkè Efraimu, ó sì ń gbé inú rẹ̀. Láti ibẹ̀ ó sì jáde lọ, ó sì kọ́ Penieli. Jeroboamu rò nínú ara rẹ̀ pé, “Ìjọba náà yóò padà nísinsin yìí sí ilé Dafidi. Bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá gòkè lọ láti ṣe ìrúbọ ní ilé OLúWA ní Jerusalẹmu, wọn yóò tún fi ọkàn wọn fún OLúWA wọn, Rehoboamu ọba Juda. Wọn yóò sì pa mí, wọn yóò sì tún padà tọ Rehoboamu ọba Juda lọ.” Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọrọ màlúù wúrà méjì. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Israẹli, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Ejibiti wá.” Ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀ ní Beteli, àti èkejì ní Dani. Nǹkan yìí sì di ẹ̀ṣẹ̀; àwọn ènìyàn sì lọ títí dé Dani láti sin èyí tí ó wà níbẹ̀. Jeroboamu sì kọ́ ojúbọ sórí ibi gíga, ó sì yan àwọn àlùfáà láti inú àwọn ènìyàn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe inú àwọn ọmọ Lefi. Jeroboamu sì dá àsè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àsè tí ó wà ní Juda, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Beteli, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Beteli. Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kẹjọ, oṣù tí ó rò ní ọkàn ara rẹ̀, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó kọ́ ní Beteli. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá àsè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì gun orí pẹpẹ náà lọ láti rú ẹbọ.