I. A. Ọba 10:1-13

I. A. Ọba 10:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI ayaba Ṣeba si gbọ́ okiki Solomoni niti orukọ Oluwa, o wá lati fi àlọ dán a wò. O si wá si Jerusalemu pẹlu ẹgbẹ nlanla, ibakasiẹ ti o ru turari, ati ọ̀pọlọpọ wura, ati okuta oniyebiye: nigbati o si de ọdọ Solomoni o ba a sọ gbogbo eyiti mbẹ li ọkàn rẹ̀. Solomoni si fi èsi si gbogbo ọ̀rọ rẹ̀, kò si ibère kan ti o pamọ fun ọba ti kò si sọ fun u. Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri gbogbo ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́. Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati iwọṣọ wọn, ati awọn agbọti rẹ̀, ati ọna ti o mba goke lọ si ile Oluwa; kò kù agbara kan fun u mọ. O si wi fun ọba pe, Otitọ li ọ̀rọ ti mo gbọ́ ni ilẹ mi niti iṣe rẹ ati niti ọgbọ́n rẹ. Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ na gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri: si kiyesi i, a kò sọ idajì wọn fun mi: iwọ si ti fi ọgbọ́n ati irọra kún okiki ti mo gbọ́. Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro niwaju rẹ nigbagbogbo, ti ngbọ́ ọgbọ́n rẹ. Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o ni inu-didùn si ọ lati gbe ọ ka ori itẹ́ Israeli: nitoriti Oluwa fẹràn Israeli titi lai, nitorina li o ṣe fi ọ jọba, lati ṣe idajọ ati otitọ. On si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọ́pọlọpọ ati okuta iyebiye: iru ọ̀pọlọpọ turari bẹ̃ kò de mọ bi eyiti ayaba Ṣeba fi fun Solomoni, ọba. Pẹlupẹlu awọn ọ̀wọ-ọkọ̀ Hiramu ti o mu wura lati Ofiri wá, mu igi Algumu, (igi Sandali) lọpọlọpọ ati okuta oniyebiye lati Ofiri wá. Ọba si fi igi Algumu na ṣe opó fun ile Oluwa, ati fun ile ọba dùru pẹlu ati ohun-elo orin miran fun awọn akọrin: iru igi Algumu bẹ̃ kò de mọ, bẹ̃ni a kò ri wọn titi di oni yi. Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba ni gbogbo ifẹ rẹ̀, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti a fi fun u lati ọwọ Solomoni ọba wá. Bẹ̃li o si yipada, o si lọ si ilu rẹ̀, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀.

I. A. Ọba 10:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba gbọ́ òkìkí ọgbọ́n Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti fi àwọn ìbéèrè tí ó takókó dán an wò. Ó kó ọpọlọpọ iranṣẹ lẹ́yìn, ó sì di turari olóòórùn dídùn, pẹlu òkúta olówó iyebíye ati ọpọlọpọ wúrà ru ọpọlọpọ ràkúnmí; ó wá sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ patapata fún un. Solomoni dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè rẹ̀, kò sì sí ohunkohun tí ó le fún Solomoni láti ṣàlàyé. Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí Solomoni ti gbọ́n tó, ati irú ààfin tí ó kọ́, irú oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀, ìjókòó àwọn ìjòyè rẹ̀, ìṣesí àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, àwọn tí wọ́n ń gbé ọtí rẹ̀ ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ninu ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ. Ó sọ fún Solomoni ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa ìjọba rẹ ati ọgbọ́n rẹ. Ṣugbọn n kò gbàgbọ́ títí tí mo fi wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Àwọn tí wọ́n sọ fún mi kò tilẹ̀ sọ ìdajì ohun tí mo rí. Ọgbọ́n, ati ọrọ̀ rẹ pọ̀ rékọjá ohun tí mo gbọ́ lọ. Àwọn iyawo rẹ ṣe oríire; bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi tí wọn ń wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo, tí wọn ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n rẹ! Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó sì fi ọ́ jọba Israẹli. Nítorí ìfẹ́ ayérayé tí ó ní sí Israẹli ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn, kí o lè máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo.” Lẹ́yìn náà, ọbabinrin Ṣeba fún Solomoni ọba ní ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà, ati ọpọlọpọ turari olóòórùn dídùn, ati àwọn òkúta olówó iyebíye. Turari tí ọbabinrin Ṣeba fún Solomoni pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé Solomoni kò rí irú rẹ̀ gbà ní ẹ̀bùn mọ́. Àwọn ọkọ̀ ojú omi Hiramu ọba, tí ó kó wúrà wá láti Ofiri kó ọpọlọpọ igi alimugi ati òkúta olówó iyebíye bọ̀ pẹlu. Solomoni ọba fi igi alimugi náà ṣe òpó ilé OLUWA ati ti ààfin rẹ̀. Ó tún lò ninu wọn, ó fi ṣe ohun èlò orin tí wọ́n ń pè ní hapu ati gòjé fún àwọn akọrin rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò rí irú igi alimugi bẹ́ẹ̀ mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí di òní olónìí. Gbogbo ohun tí ọbabinrin Ṣeba fẹ́, tí ó tọrọ lọ́wọ́ Solomoni pátá ni Solomoni fún un, láìka ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n ti kọ́ fi ṣe é lálejò. Ọbabinrin náà pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá pada sí ilẹ̀ wọn.

I. A. Ọba 10:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ òkìkí Solomoni àti ì bà ṣe pọ̀ rẹ̀ ní ti orúkọ OLúWA, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle. Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńláńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀. Solomoni sì dáhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyí tí ó ṣòro fún ọba láti ṣàlàyé fún un. Nígbà tí ayaba Ṣeba sì rí gbogbo ọgbọ́n Solomoni àti ààfin tí ó ti kọ́. Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ sísun tí ó sun ní ilé OLúWA, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́! Ó sì wí fún ọba pé, “Òtítọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní orílẹ̀-èdè mi ní ti iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ. Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsi i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́. Báwo ni inú àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe dùn tó! Báwo ni inú dídùn àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí wọ́n ń dúró níwájú rẹ nígbà gbogbo, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọgbọ́n rẹ! Ìbùkún ni fún OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Israẹli. Nítorí tí OLúWA fẹ́ràn Israẹli títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jẹ ọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo.” Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà (120) tálẹ́ǹtì wúrà, tùràrí olóòórùn dídùn lọ́pọ̀lọpọ̀, àti òkúta iyebíye. Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dàbí irú èyí tí ayaba Ṣeba fi fún Solomoni ọba. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọkọ̀ Hiramu tí ó mú wúrà láti Ofiri wá, wọ́n mú igi algumu, (igi sandali) lọ́pọ̀lọpọ̀ àti òkúta oníyebíye láti Ofiri wá. Ọba sì fi igi algumu náà ṣe òpó fún ilé OLúWA àti fún ààfin ọba, àti láti ṣe dùùrù pẹ̀lú àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Irú igi algumu bẹ́ẹ̀ kò dé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí wọn títí di òní yìí. Solomoni ọba sì fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Solomoni ọba wa. Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.