NIGBATI ayaba Ṣeba si gbọ́ okiki Solomoni niti orukọ Oluwa, o wá lati fi àlọ dán a wò.
O si wá si Jerusalemu pẹlu ẹgbẹ nlanla, ibakasiẹ ti o ru turari, ati ọ̀pọlọpọ wura, ati okuta oniyebiye: nigbati o si de ọdọ Solomoni o ba a sọ gbogbo eyiti mbẹ li ọkàn rẹ̀.
Solomoni si fi èsi si gbogbo ọ̀rọ rẹ̀, kò si ibère kan ti o pamọ fun ọba ti kò si sọ fun u.
Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri gbogbo ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́.
Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati iwọṣọ wọn, ati awọn agbọti rẹ̀, ati ọna ti o mba goke lọ si ile Oluwa; kò kù agbara kan fun u mọ.
O si wi fun ọba pe, Otitọ li ọ̀rọ ti mo gbọ́ ni ilẹ mi niti iṣe rẹ ati niti ọgbọ́n rẹ.
Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ na gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri: si kiyesi i, a kò sọ idajì wọn fun mi: iwọ si ti fi ọgbọ́n ati irọra kún okiki ti mo gbọ́.
Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro niwaju rẹ nigbagbogbo, ti ngbọ́ ọgbọ́n rẹ.
Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o ni inu-didùn si ọ lati gbe ọ ka ori itẹ́ Israeli: nitoriti Oluwa fẹràn Israeli titi lai, nitorina li o ṣe fi ọ jọba, lati ṣe idajọ ati otitọ.
On si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọ́pọlọpọ ati okuta iyebiye: iru ọ̀pọlọpọ turari bẹ̃ kò de mọ bi eyiti ayaba Ṣeba fi fun Solomoni, ọba.
Pẹlupẹlu awọn ọ̀wọ-ọkọ̀ Hiramu ti o mu wura lati Ofiri wá, mu igi Algumu, (igi Sandali) lọpọlọpọ ati okuta oniyebiye lati Ofiri wá.
Ọba si fi igi Algumu na ṣe opó fun ile Oluwa, ati fun ile ọba dùru pẹlu ati ohun-elo orin miran fun awọn akọrin: iru igi Algumu bẹ̃ kò de mọ, bẹ̃ni a kò ri wọn titi di oni yi.
Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba ni gbogbo ifẹ rẹ̀, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti a fi fun u lati ọwọ Solomoni ọba wá. Bẹ̃li o si yipada, o si lọ si ilu rẹ̀, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀.