I. Kor 8:5-6
I. Kor 8:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe bi awọn ti a npè li ọlọrun tilẹ wà, iba ṣe li ọrun tabi li aiye (gẹgẹ bi ọ̀pọ ọlọrun ti wà ati ọ̀pọ oluwa,) Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀.
I. Kor 8:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tí à ń pè ní oriṣa wà, ìbáà ṣe ní ọ̀run tabi ní ayé, gẹ́gẹ́ bí oriṣa ti pọ̀, tí “àwọn oluwa” tún pọ̀, ṣugbọn ní tiwa, Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba, lọ́dọ̀ ẹni tí gbogbo nǹkan ti wá, ati lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ń lọ. Oluwa kan ni ó wà. Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí a dá gbogbo nǹkan, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá àwa náà.
I. Kor 8:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèkéé mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa). Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.