I. Kor 4:6-7
I. Kor 4:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ ará, nkan wọnyi ni mo ti fi ṣe apẹrẹ ara mi ati Apollo nitori nyin; ki ẹnyin ki o le ti ipa wa kọ́ ki ẹ maṣe ré ohun ti a ti kọwe rẹ̀ kọja, ki ẹnikan ninu nyin ki o máṣe ti itori ẹnikan gberaga si ẹnikeji. Nitori tali o mu ọ yàtọ? kini iwọ si ní ti iwọ kò ti gbà? njẹ bi iwọ ba si ti gbà a, éhatiṣe ti iwọ fi nhalẹ, bi ẹnipe iwọ kò gbà a?
I. Kor 4:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, mo fi ara mi ati Apolo ṣe àpẹẹrẹ ohun tí à ń sọ nítorí yín, kí ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára wa, pé kí ẹ má ṣe tayọ ohun tí ó wà ní àkọsílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé ẹnìkan ga ju ẹnìkejì lọ. Ta ni ó gbe yín ga ju ẹlòmíràn lọ? Kí ni ohun tí ẹ dá ní, tí kò jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni ẹ ti rí i gbà? Kí wá ni ìdí ìgbéraga yín bí ẹni pé ẹ̀yin ni ẹ dá a ní?
I. Kor 4:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.” Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?