I. Kor 4

4
Iṣẹ́ Àwọn Aposteli
1JẸ ki enia ki o ma kà wa bẹ̃ bi iranṣẹ Kristi, ati iriju awọn ohun ijinlẹ Ọlọrun.
2Pẹlupẹlu a mbere lọwọ iriju pe ki oluwarẹ̀ na ki o jẹ olõtọ.
3Ṣugbọn, ohun kikini ni fun mi pe, ki ẹ mã ṣe idajọ mi, tabi ki a mã ṣe idajọ mi nipa idajọ enia: nitotọ emi kò ṣe idajọ emi tikarami.
4Nitoriti emi kò mọ̀ ohunkohun si ara mi; ṣugbọn a kò ti ipa eyi dá mi lare: Ṣugbọn ẹniti nṣe idajọ mi li Oluwa.
5Nitorina, ẹ máṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaju akokò na, titi Oluwa yio fi de, ẹniti yio mu ohun òkunkun ti o farasin wá si imọlẹ, ti yio si fi ìmọ ọkàn hàn: nigbana li olukuluku yio si ni iyìn tirẹ̀ lọdọ Ọlọrun.
6Njẹ ará, nkan wọnyi ni mo ti fi ṣe apẹrẹ ara mi ati Apollo nitori nyin; ki ẹnyin ki o le ti ipa wa kọ́ ki ẹ maṣe ré ohun ti a ti kọwe rẹ̀ kọja, ki ẹnikan ninu nyin ki o máṣe ti itori ẹnikan gberaga si ẹnikeji.
7Nitori tali o mu ọ yàtọ? kini iwọ si ní ti iwọ kò ti gbà? njẹ bi iwọ ba si ti gbà a, éhatiṣe ti iwọ fi nhalẹ, bi ẹnipe iwọ kò gbà a?
8A sá tẹ́ nyin lọrùn nisisiyi, a sá ti sọ nyin di ọlọrọ̀ nisisiyi, ẹnyin ti njọba laisi wa: iba si wu mi ki ẹnyin ki o jọba, ki awa ki o le jùmọ jọba pẹlu nyin.
9Nitori mo rò pe Ọlọrun ti yan awa Aposteli kẹhin bi awọn ẹniti a dalẹbi ikú: nitoriti a fi wa ṣe iran wò fun aiye, ati fun angẹli, ati fun enia.
10Awa jẹ aṣiwere nitori Kristi, ṣugbọn ẹnyin jẹ ọlọgbọ́n ninu Kristi; awa jẹ alailera, ṣugbọn ẹnyin jẹ alagbara; ẹnyin jẹ ọlọlá, ṣugbọn awa jẹ ẹni ẹ̀gan.
11Ani titi fi di wakati yi li ebi npa wa, ti òrungbẹ si ngbẹ wa, ti a si wà ni ìhoho, ti a si nlù wa, ti a kò si ni ibugbé kan;
12Ti a nṣe lãlã, a nfi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ: nwọn ngàn wa, awa nsure; nwọn nṣe inunibini si wa, awa nforitì i:
13Nwọn nkẹgàn wa, awa mbẹ̀bẹ: a ṣe wa bi ohun ẹgbin aiye, bi ẽri ohun gbogbo titi di isisiyi.
14Emi kò kọ̀we nkan wọnyi lati fi dojutì nyin, ṣugbọn lati kìlọ fun nyin bi awọn ọmọ mi ayanfẹ.
15Nitori bi ẹnyin tilẹ ni ẹgbarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹnyin kò ni baba pipọ: nitoripe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí nyin.
16Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣe afarawe mi.
17Nitorina ni mo ṣe rán Timotiu si nyin, ẹniti iṣe ọmọ mi olufẹ ati olododo ninu Oluwa, ẹniti yio ma mu nyin ranti ọ̀na mi ti o wà ninu Kristi, gẹgẹ bi mo ti nkọ́ni ninu gbogbo ijọ nibigbogbo.
18Ṣugbọn awọn ẹlomiran gberaga ninu nyin, bi ẹnipe emi kì yio tọ̀ nyin wá mọ́.
19Ṣugbọn emi ó tọ̀ nyin wá ni lọ̃lọ yi, bi Oluwa ba fẹ; kì si iṣe ọ̀rọ awọn ti ngberaga li emi o mọ̀, bikoṣe agbara.
20Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe ninu ọ̀rọ, bikoṣe ninu agbara.
21Kili ẹnyin nfẹ? emi ó ha tọ̀ nyin wá ti emi ti kùmọ bi, tabi ni ifẹ, ati ẹmí inututù?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kor 4: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀