I. Kor 4:15-17
I. Kor 4:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori bi ẹnyin tilẹ ni ẹgbarun olukọni ninu Kristi, ṣugbọn ẹnyin kò ni baba pipọ: nitoripe ninu Kristi Jesu ni mo ti fi ihinrere bí nyin. Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ mã ṣe afarawe mi. Nitorina ni mo ṣe rán Timotiu si nyin, ẹniti iṣe ọmọ mi olufẹ ati olododo ninu Oluwa, ẹniti yio ma mu nyin ranti ọ̀na mi ti o wà ninu Kristi, gẹgẹ bi mo ti nkọ́ni ninu gbogbo ijọ nibigbogbo.
I. Kor 4:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé, ẹ̀ báà ní ẹgbẹrun àwọn olùtọ́ ninu Kristi, ẹ kò ní ju ẹyọ baba kan lọ. Nítorí ninu Kristi Jesu, èmi ni mo bi yín nípa ọ̀rọ̀ ìyìn rere. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìwà jọ mí. Ìdí tí mo ṣe rán Timoti si yín nìyí, ẹni tí ó jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ fún mi, ati olóòótọ́ ninu nǹkan ti Oluwa. Òun ni yóo ran yín létí àwọn ohun tí mo fi ń ṣe ìwà hù ninu ìgbé-ayé titun ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ gbogbo àwọn ìjọ níbi gbogbo.

I. Kor 4:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbàárùn-ún olùkọ́ni nínú Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kristi Jesu ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìhìnrere. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi. Nítorí náà ni mo ṣe rán Timotiu sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.