I. Kor 15:30-34
I. Kor 15:30-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori kili awa si ṣe mbẹ ninu ewu ni wakati gbogbo? Mo sọ nipa ayọ̀ ti mo ni lori nyin ninu Kristi Jesu Oluwa wa pe, emi nkú lojojumọ́. Ki a wi bi enia, bi mo ba ẹranko jà ni Efesu, anfãni kili o jẹ́ fun mi? bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde, ẹ jẹ ki a mã jẹ, ẹ jẹ ki a mã mu; ọla li awa o sá kú. Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ. Ẹ jí iji ododo, ki ẹ má si dẹṣẹ̀; nitori awọn ẹlomiran kò ni ìmọ Ọlọrun: mo sọ eyi ki oju ki o le ti nyin.
I. Kor 15:30-34 Yoruba Bible (YCE)
Àwa náà ńkọ́? Nítorí kí ni a ṣe ń fi ẹ̀mí wa wéwu nígbà gbogbo? Lojoojumọ ni mò ń kú! Ará, mo fi ìgbéraga tí mo ní ninu yín búra, àní èyí tí mo ní ninu Kristi Jesu Oluwa wa. Bí mo bá tìtorí iyì eniyan bá ẹranko jà ní Efesu, anfaani wo ni ó ṣe fún mi? Bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, bí wọ́n ti máa ń wí, wọn á ní: “Ẹ jẹ́ kí á máa jẹ, kí á máa mu, nítorí ọ̀la ni a óo kú.” Ẹ má jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ burúkú a máa ba ìwà rere jẹ́. Ẹ ronú, kí ẹ sì máa ṣe dáradára. Ẹ má dẹ́ṣẹ̀ mọ́. Àwọn tí kò mọ Ọlọrun wà láàrin yín! Mò ń sọ èyí kí ojú kí ó lè tì yín ni.
I. Kor 15:30-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí kín ní àwa sì ṣe ń bẹ nínú ewu ni wákàtí gbogbo? Mo sọ nípa ayọ̀ tí mo ní lórí yín nínú Kristi Jesu Olúwa wá pé, èmi ń kú lójoojúmọ́. Kí a wí bí ènìyàn, bí mo bá ẹranko jà ní Efesu, àǹfààní kín ni ó jẹ́ fún mi? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde, “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí á máa mú; nítorí ní ọlá ni àwa ó kú.” Kí a má tàn yín jẹ́, “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́.” Ẹ jí ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀; nítorí àwọn ẹlòmíràn kò ni imọ̀ Ọlọ́run, mo sọ èyí kí ojú ba à lè tiyín.