I. Kor 15:3-8
I. Kor 15:3-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe ṣiwaju ohun gbogbo mo fi eyiti emi pẹlu ti gbà le nyin lọwọ, bi Kristi ti kú nitori ẹ̀ṣẹ wa gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi; Ati pe a sinkú rẹ̀, ati pe o jinde ni ijọ kẹta gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi: Ati pe o farahan Kefa, lẹhin eyini awọn mejila: Lẹhin eyini o farahan awọn ará ti o jù ẹ̃dẹgbẹta lọ lẹkanna; apakan ti o pọ̀ju ninu wọn wà titi fi di isisiyi, ṣugbọn awọn diẹ ti sùn. Lẹhin eyini o farahan Jakọbu; lẹhinna fun gbogbo awọn Aposteli. Ati nikẹhin gbogbo wọn o farahàn mi pẹlu, bi ẹni ti a bí ṣiwaju akokò rẹ̀.
I. Kor 15:3-8 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ohun kinni tí ó ṣe pataki jùlọ tí èmi fúnra mi kọ́, tí mo sì fi kọ́ yín ni pé Kristi kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí. Ati pé a sin ín, a sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí. Ó fara han Peteru. Lẹ́yìn náà ó tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Lẹ́yìn náà ó tún fara han ẹẹdẹgbẹta (500) àwọn onigbagbọ lẹ́ẹ̀kan náà. Ọpọlọpọ ninu wọn wà títí di ìsinsìnyìí, ṣugbọn àwọn mìíràn ti kú. Lẹ́yìn náà, ó fara han Jakọbu, ó sì tún fara han gbogbo àwọn aposteli. Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín gbogbo wọn, ó wá farahàn mí, èmi tí mo dàbí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé.
I. Kor 15:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí èyí tí mo rí gbà ṣáájú ohun gbogbo ní èmi pẹ̀lú ti fi lé e yín lọ́wọ́, bí Kristi ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tí wí. Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ tí wí; Àti pé ó farahàn Peteru, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ lẹ́ẹ̀kan náà; ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fi di ìsinsin yìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn. Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jakọbu; lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn aposteli. Àti níkẹyìn gbogbo wọn ó farahàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀.