I. Kor 15:20-23
I. Kor 15:20-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn. Nitori igbati o ti ṣepe nipa enia ni ikú ti wá, nipa enia li ajinde ninu okú si ti wá pẹlu. Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bẹ̃ni a ó si sọ gbogbo enia di alãye ninu Kristi. Ṣugbọn olukuluku enia ni ipa tirẹ̀: Kristi akọbi; lẹhin eyini awọn ti iṣe ti Kristi ni bibọ rẹ̀.
I. Kor 15:20-23 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ yìí ni pé a ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú, òun sì ni àkọ́bí ninu àwọn tí wọ́n kú. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ eniyan ni ikú fi dé, nípasẹ̀ eniyan náà ni ajinde òkú fi dé. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ Adamu ni gbogbo eniyan ṣe kú, bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ Kristi ni a sọ gbogbo eniyan di alààyè. Ṣugbọn a óo jí olukuluku dìde létòlétò: Kristi ni ẹni àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá farahàn, a óo jí àwọn tíí ṣe tirẹ̀ dìde.
I. Kor 15:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ nísinsin yìí Kristi tí jíǹde kúrò nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn. Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nípa ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú. Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kristi. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀: Kristi àkọ́bí; lẹ́yìn èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kristi ni wíwá rẹ̀.