I. Kor 15:12-34
I. Kor 15:12-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si? Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde: Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwãsu wa, asan si ni igbagbọ́ nyin pẹlu. Pẹlupẹlu a mu wa li ẹlẹri eke fun Ọlọrun; nitoriti awa jẹri Ọlọrun pe o jí Kristi dide: ẹniti on kò jí dide, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde? Nitoripe bi a kò bá ji awọn oku dide, njẹ a kò jí Kristi dide: Bi a kò ba si jí Kristi dide, asan ni igbagbọ́ nyin; ẹnyin wà ninu ẹ̀ṣẹ nyin sibẹ. Njẹ awọn pẹlu ti o sùn ninu Kristi ṣegbé. Bi o ba ṣe pe ni kìki aiye yi nikan li awa ni ireti ninu Kristi, awa jasi òtoṣi jùlọ ninu gbogbo enia. Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn. Nitori igbati o ti ṣepe nipa enia ni ikú ti wá, nipa enia li ajinde ninu okú si ti wá pẹlu. Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bẹ̃ni a ó si sọ gbogbo enia di alãye ninu Kristi. Ṣugbọn olukuluku enia ni ipa tirẹ̀: Kristi akọbi; lẹhin eyini awọn ti iṣe ti Kristi ni bibọ rẹ̀. Nigbana ni opin yio de, nigbati o ba ti fi ijọba fun Ọlọrun ani Baba; nigbati o ba ti mu gbogbo aṣẹ ati gbogbo ọla ati agbara kuro. Nitori on kò le ṣaima jọba titi yio fi fi gbogbo awọn ọta sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ikú ni ọtá ikẹhin ti a ó parun. Nitori o ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ṣugbọn nigbati o wipe ohun gbogbo li a fi sabẹ rẹ̀, o daju pe, on nikanṣoṣo li o kù, ti o fi ohun gbogbo si i labẹ. Nigbati a ba si fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ tan, nigbana li a ó fi Ọmọ tikararẹ̀ pẹlu sabẹ ẹniti o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀, ki Ọlọrun ki o le jasi ohun gbogbo li ohun gbogbo. Njẹ kili awọn ti a baptisi nitori okú yio ha ṣe, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde rara? nitori kili a ha ṣe mbaptisi wọn nitori okú? Nitori kili awa si ṣe mbẹ ninu ewu ni wakati gbogbo? Mo sọ nipa ayọ̀ ti mo ni lori nyin ninu Kristi Jesu Oluwa wa pe, emi nkú lojojumọ́. Ki a wi bi enia, bi mo ba ẹranko jà ni Efesu, anfãni kili o jẹ́ fun mi? bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde, ẹ jẹ ki a mã jẹ, ẹ jẹ ki a mã mu; ọla li awa o sá kú. Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ. Ẹ jí iji ododo, ki ẹ má si dẹṣẹ̀; nitori awọn ẹlomiran kò ni ìmọ Ọlọrun: mo sọ eyi ki oju ki o le ti nyin.
I. Kor 15:12-34 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó jẹ́ pé, à ń kéde pé Kristi jinde kúrò ninu òkú, báwo ni àwọn kan ninu yín ṣe wá ń wí pé kò sí ajinde òkú? Bí kò bá sí ajinde òkú, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde. Bí a kò bá jí Kristi dìde ninu òkú, a jẹ́ pé asán ni iwaasu wa, asán sì ni igbagbọ yín. Tí ó bá jẹ́ pé a kò jí àwọn òkú dìde, a tún jẹ́ pé a purọ́ mọ́ Ọlọrun, nítorí a jẹ́rìí pé ó jí Kristi dìde, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jí i dìde. Nítorí pé bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde. Bí a kò bá sì jí Kristi dìde, a jẹ́ pé lásán ni igbagbọ yín, ẹ sì wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín sibẹ. Tí ó bá wá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àwọn onigbagbọ tí wọ́n ti kú ti ṣègbé! Tí ó bá jẹ́ pé ninu ayé yìí nìkan ni a ní ìrètí ninu Kristi, àwa ni ẹni tí àwọn eniyan ìbá máa káàánú jùlọ! Ṣugbọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ yìí ni pé a ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú, òun sì ni àkọ́bí ninu àwọn tí wọ́n kú. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ eniyan ni ikú fi dé, nípasẹ̀ eniyan náà ni ajinde òkú fi dé. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ Adamu ni gbogbo eniyan ṣe kú, bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ Kristi ni a sọ gbogbo eniyan di alààyè. Ṣugbọn a óo jí olukuluku dìde létòlétò: Kristi ni ẹni àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá farahàn, a óo jí àwọn tíí ṣe tirẹ̀ dìde. Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé, lẹ́yìn tí ó bá ti dá ìjọba pada fún Ọlọrun Baba, tí ó sì ti pa gbogbo àṣẹ, ọlá ati agbára run. Nítorí ó níláti jọba títí Ọlọrun yóo fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí ìkáwọ́ rẹ̀. Ikú ni ọ̀tá ìkẹyìn tí yóo parun. Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ó ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.” Ṣugbọn nígbà tí ó sọ pé, “Gbogbo nǹkan ni ó fi sí ìkáwọ́ rẹ̀,” ó dájú pé ẹnìkan ni kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀: ẹni náà sì ni Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ Kristi. Nígbà tí gbogbo nǹkan bá ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tán, ni Ọmọ fúnrarẹ̀ yóo wá bọ́ sí ìkáwọ́ Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀, kí Ọlọrun lè jẹ́ olórí ohun gbogbo ninu ohun gbogbo. Ó tún ku nǹkankan! Nítorí kí ni àwọn kan ṣe ń ṣe ìrìbọmi nítorí àwọn tí ó kú? Bí a kò bá ní jí àwọn òkú dìde, kí ni ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ìrìbọmi nítorí wọn? Àwa náà ńkọ́? Nítorí kí ni a ṣe ń fi ẹ̀mí wa wéwu nígbà gbogbo? Lojoojumọ ni mò ń kú! Ará, mo fi ìgbéraga tí mo ní ninu yín búra, àní èyí tí mo ní ninu Kristi Jesu Oluwa wa. Bí mo bá tìtorí iyì eniyan bá ẹranko jà ní Efesu, anfaani wo ni ó ṣe fún mi? Bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, bí wọ́n ti máa ń wí, wọn á ní: “Ẹ jẹ́ kí á máa jẹ, kí á máa mu, nítorí ọ̀la ni a óo kú.” Ẹ má jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ burúkú a máa ba ìwà rere jẹ́. Ẹ ronú, kí ẹ sì máa ṣe dáradára. Ẹ má dẹ́ṣẹ̀ mọ́. Àwọn tí kò mọ Ọlọrun wà láàrin yín! Mò ń sọ èyí kí ojú kí ó lè tì yín ni.
I. Kor 15:12-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kristi pé ó tí jíǹde kúrò nínú òkú, èéha tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín fi wí pé, àjíǹde òkú kò sí. Ṣùgbọ́n bí àjíǹde òkú kò sí, ǹjẹ́ Kristi kò jíǹde. Bí Kristi kò bá sì jíǹde, ǹjẹ́ asán ni ìwàásù wà, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, a mú wa ni ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run; nítorí ti àwa jẹ́rìí Ọlọ́run pé ó jí Kristi dìde kúrò nínú òkú: ẹni tí òun kò jí dìde bí ó bá ṣe pé àwọn òkú kò jíǹde? Nítorí pé bi á kò bá jí àwọn òkú dìde, ǹjẹ́ a kò jí Kristi dìde, bí a kò bá sì jí Kristi dìde, asán ní ìgbàgbọ́ yín; ẹ̀yin wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín síbẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn pẹ̀lú tí ó sùn nínú Kristi ṣègbé. Bí ó bá ṣe pé kìkì ayé yìí nìkan ní àwa ní ìrètí nínú Kristi, àwa jásí òtòṣì jùlọ nínú gbogbo ènìyàn. Ǹjẹ́ nísinsin yìí Kristi tí jíǹde kúrò nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn. Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nípa ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú. Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kristi. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀: Kristi àkọ́bí; lẹ́yìn èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kristi ni wíwá rẹ̀. Nígbà náà ni òpin yóò dé, nígbà tí ó bá ti fi ìjọba fún Ọlọ́run Baba, nígbà tí ó bá pa gbogbo àṣẹ àti gbogbo ọlá àti agbára run. Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jẹ ọba kí òun to fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ikú ní ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun “Nítorí ó ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé, “Ohun gbogbo ni á fi sí abẹ́ rẹ̀,” o dájú pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ní kò sí ní abẹ́ rẹ̀, Òun ní ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso Kristi. Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni á ó fi ọmọ tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jásí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo. Ní báyìí, bí kò bá sí àjíǹde, kín ní ète àwọn ènìyàn tí wọn ń tẹ bọ omi nítorí òkú? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde rárá, nítorí kín ni a ṣe ń bamitiisi wọn nítorí wọn? Nítorí kín ní àwa sì ṣe ń bẹ nínú ewu ni wákàtí gbogbo? Mo sọ nípa ayọ̀ tí mo ní lórí yín nínú Kristi Jesu Olúwa wá pé, èmi ń kú lójoojúmọ́. Kí a wí bí ènìyàn, bí mo bá ẹranko jà ní Efesu, àǹfààní kín ni ó jẹ́ fún mi? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde, “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí á máa mú; nítorí ní ọlá ni àwa ó kú.” Kí a má tàn yín jẹ́, “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́.” Ẹ jí ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀; nítorí àwọn ẹlòmíràn kò ni imọ̀ Ọlọ́run, mo sọ èyí kí ojú ba à lè tiyín.