I. Kor 15:1-58

I. Kor 15:1-58 Bibeli Mimọ (YBCV)

NJẸ, ará, emi nsọ ihinrere na di mimọ̀ fun nyin ti mo ti wãsu fun nyin, eyiti ẹnyin pẹlu ti gbà, ninu eyi ti ẹnyin si duro; Nipaṣe eyiti a fi ngbà nyin là pẹlu, bi ẹnyin ba di ọ̀rọ ti mo ti wãsu fun nyin mú ṣinṣin, bikoṣepe ẹnyin ba gbagbọ́ lasan. Nitoripe ṣiwaju ohun gbogbo mo fi eyiti emi pẹlu ti gbà le nyin lọwọ, bi Kristi ti kú nitori ẹ̀ṣẹ wa gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi; Ati pe a sinkú rẹ̀, ati pe o jinde ni ijọ kẹta gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi: Ati pe o farahan Kefa, lẹhin eyini awọn mejila: Lẹhin eyini o farahan awọn ará ti o jù ẹ̃dẹgbẹta lọ lẹkanna; apakan ti o pọ̀ju ninu wọn wà titi fi di isisiyi, ṣugbọn awọn diẹ ti sùn. Lẹhin eyini o farahan Jakọbu; lẹhinna fun gbogbo awọn Aposteli. Ati nikẹhin gbogbo wọn o farahàn mi pẹlu, bi ẹni ti a bí ṣiwaju akokò rẹ̀. Nitori emi li ẹniti o kere jùlọ ninu awọn Aposteli, emi ẹniti kò yẹ ti a ba pè li Aposteli, nitoriti mo ṣe inunibini si ijọ enia Ọlọrun. Ṣugbọn nipa õre-ọfẹ Ọlọrun, mo ri bi mo ti ri: õre-ọfẹ rẹ̀ ti a fifun mi kò si jẹ asan; ṣugbọn mo ṣiṣẹ lọpọlọpọ jù gbogbo wọn lọ: ṣugbọn kì iṣe emi, bikoṣe õre-ọfẹ Ọlọrun ti o wà pẹlu mi. Nitorina ibã ṣe emi tabi awọn ni, bẹ̃li awa wãsu, bẹ̃li ẹnyin si gbagbọ́. Njẹ bi a ba nwasu Kristi pe o ti jinde kuro ninu okú, ẽhatiṣe ti awọn miran ninu nyin fi wipe, ajinde okú kò si? Ṣugbọn bi ajinde okú kò si, njẹ Kristi kò jinde: Bi Kristi kò ba si jinde, njẹ asan ni iwãsu wa, asan si ni igbagbọ́ nyin pẹlu. Pẹlupẹlu a mu wa li ẹlẹri eke fun Ọlọrun; nitoriti awa jẹri Ọlọrun pe o jí Kristi dide: ẹniti on kò jí dide, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde? Nitoripe bi a kò bá ji awọn oku dide, njẹ a kò jí Kristi dide: Bi a kò ba si jí Kristi dide, asan ni igbagbọ́ nyin; ẹnyin wà ninu ẹ̀ṣẹ nyin sibẹ. Njẹ awọn pẹlu ti o sùn ninu Kristi ṣegbé. Bi o ba ṣe pe ni kìki aiye yi nikan li awa ni ireti ninu Kristi, awa jasi òtoṣi jùlọ ninu gbogbo enia. Njẹ nisisiyi Kristi ti jinde kuro ninu okú, o si di akọbi ninu awọn ti o sùn. Nitori igbati o ti ṣepe nipa enia ni ikú ti wá, nipa enia li ajinde ninu okú si ti wá pẹlu. Nitori bi gbogbo enia ti kú ninu Adamu, bẹ̃ni a ó si sọ gbogbo enia di alãye ninu Kristi. Ṣugbọn olukuluku enia ni ipa tirẹ̀: Kristi akọbi; lẹhin eyini awọn ti iṣe ti Kristi ni bibọ rẹ̀. Nigbana ni opin yio de, nigbati o ba ti fi ijọba fun Ọlọrun ani Baba; nigbati o ba ti mu gbogbo aṣẹ ati gbogbo ọla ati agbara kuro. Nitori on kò le ṣaima jọba titi yio fi fi gbogbo awọn ọta sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ikú ni ọtá ikẹhin ti a ó parun. Nitori o ti fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Ṣugbọn nigbati o wipe ohun gbogbo li a fi sabẹ rẹ̀, o daju pe, on nikanṣoṣo li o kù, ti o fi ohun gbogbo si i labẹ. Nigbati a ba si fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ tan, nigbana li a ó fi Ọmọ tikararẹ̀ pẹlu sabẹ ẹniti o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀, ki Ọlọrun ki o le jasi ohun gbogbo li ohun gbogbo. Njẹ kili awọn ti a baptisi nitori okú yio ha ṣe, bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde rara? nitori kili a ha ṣe mbaptisi wọn nitori okú? Nitori kili awa si ṣe mbẹ ninu ewu ni wakati gbogbo? Mo sọ nipa ayọ̀ ti mo ni lori nyin ninu Kristi Jesu Oluwa wa pe, emi nkú lojojumọ́. Ki a wi bi enia, bi mo ba ẹranko jà ni Efesu, anfãni kili o jẹ́ fun mi? bi o ba ṣe pe awọn okú kò jinde, ẹ jẹ ki a mã jẹ, ẹ jẹ ki a mã mu; ọla li awa o sá kú. Ki a má tàn nyin jẹ: ẹgbẹ́ buburu bà ìwa rere jẹ. Ẹ jí iji ododo, ki ẹ má si dẹṣẹ̀; nitori awọn ẹlomiran kò ni ìmọ Ọlọrun: mo sọ eyi ki oju ki o le ti nyin. Ṣugbọn ẹnikan yio wipe, Bawo li a o ha ji awọn okú dide? iru ara wo ni nwọn o pada si? Iwọ alaimoye, ohun ti iwọ fọnrugbin ki iyè bikoṣepe o ba kú: Ati eyiti iwọ fọnrugbin, ara ti mbọ̀ ki iwọ fọnrugbin, ṣugbọn irugbin lasan ni, ibã ṣe alikama, tabi irú miran. Ṣugbọn Ọlọrun fun u li ara bi o ti wù u, ati fun olukuluku irú ara tirẹ̀. Gbogbo ẹran-ara kì iṣe ẹran-ara kanna: ṣugbọn ọ̀tọ li ẹran-ara ti enia, ọ̀tọ li ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ ni ti ẹja, ọ̀tọ si ni ti ẹiyẹ. Ara ti oke ọrun mbẹ, ara ti aiye pẹlu si mbẹ: ṣugbọn ogo ti oke ọrun ọ̀tọ, ati ogo ti aiye ọ̀tọ. Ọtọ li ogo ti õrùn, ọ̀tọ li ogo ti oṣupa, ọ̀tọ si li ogo ti irawọ; irawọ sá yàtọ si irawọ li ogo. Gẹgẹ bẹ̃ si li ajinde okú. A gbìn i ni idibajẹ; a si jí i dide li aidibajẹ: A gbìn i li ainiyìn; a si jí i dide li ogo: a gbìn i li ailera, a si jí i dide li agbara: A gbìn i li ara iyara; a si jí i dide li ara ẹmí. Bi ara iyara ba mbẹ, ara ẹmí si mbẹ. Bẹ̃li a si kọ ọ pe, Adamu ọkunrin iṣaju, alãye ọkàn li a da a; Adamu ikẹhin ẹmí isọnidãye. Ṣugbọn eyi ti iṣe ẹlẹmí kọ́ tète ṣaju, bikoṣe eyi ti iṣe ara iyara; lẹhinna eyi ti iṣe ẹlẹmí. Ọkunrin iṣaju ti inu erupẹ̀ wá, ẹni erupẹ̀: ọkunrin ekeji Oluwa lati ọrun wá ni. Bi ẹni erupẹ̀ ti ri, irú bẹ̃ si ni awọn ti iṣe ti erupẹ̀: bi ẹni ti ọrun ti ri, irú bẹ si ni awọn ti iṣe ti ọrun. Bi awa si ti rù aworan ẹni erupẹ̀, bẹ̃li awa ó si ru aworan ẹni ti ọrun. Ará, njẹ eyi ni mo wipe, ara on ẹ̀jẹ kò le jogún ijọba Ọlọrun; bẹ̃ni idibajẹ kò le jogún aidibajẹ. Kiyesi i, ohun ijinlẹ ni mo sọ fun nyin; gbogbo wa kì yio sùn, ṣugbọn gbogbo wa li a o palarada, Lọgan, ni iṣẹ́ju, nigba ipè ikẹhin: nitori ipè yio dún, a o si jí awọn okú dide li aidibajẹ, a ó si pawalara dà. Nitoripe ara idibajẹ yi kò le ṣaigbé aidibajẹ wọ̀, ati ara kikú yi kò le ṣaigbé ara aiku wọ̀. Ṣugbọn nigbati ara idibajẹ yi ba ti gbe aidibajẹ wọ̀, ti ara kikú yi ba si ti gbe aikú wọ̀ bẹ̃ tan, nigbana ni ọ̀rọ ti a kọ yio ṣẹ pe, A gbé ikú mì ni iṣẹgun. Ikú, oró rẹ dà? Isà okú, iṣẹgun rẹ dà? Oró ikú li ẹ̀ṣẹ; ati agbara ẹ̀ṣẹ li ofin. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun ẹniti o fi iṣẹgun fun wa nipa Oluwa wa Jesu Kristi. Nitorina ẹnyin ará mi olufẹ ẹ mã duro ṣinṣin, laiyẹsẹ, ki ẹ mã pọ̀ si i ni iṣẹ Oluwa nigbagbogbo, niwọn bi ẹnyin ti mọ̀ pe iṣẹ nyin kì iṣe asan ninu Oluwa.

I. Kor 15:1-58 Yoruba Bible (YCE)

Ará, mo fẹ́ ran yín létí ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, tí ẹ gbà, tí ẹ sì bá dúró. Nípa ìyìn rere yìí ni a fi ń gbà yín là, tí ẹ bá dì mọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ asán ni igbagbọ yín. Nítorí ohun kinni tí ó ṣe pataki jùlọ tí èmi fúnra mi kọ́, tí mo sì fi kọ́ yín ni pé Kristi kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí. Ati pé a sin ín, a sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí. Ó fara han Peteru. Lẹ́yìn náà ó tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila. Lẹ́yìn náà ó tún fara han ẹẹdẹgbẹta (500) àwọn onigbagbọ lẹ́ẹ̀kan náà. Ọpọlọpọ ninu wọn wà títí di ìsinsìnyìí, ṣugbọn àwọn mìíràn ti kú. Lẹ́yìn náà, ó fara han Jakọbu, ó sì tún fara han gbogbo àwọn aposteli. Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín gbogbo wọn, ó wá farahàn mí, èmi tí mo dàbí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé. Nítorí èmi ni mo kéré jùlọ ninu àwọn aposteli. N kò tilẹ̀ yẹ ní ẹni tí wọn ìbá máa pè ní aposteli, nítorí pé mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọrun. Ṣugbọn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Oore-ọ̀fẹ́ yìí kò sì jẹ́ lásán lórí mí, nítorí mo ṣe akitiyan ju gbogbo àwọn aposteli yòókù lọ. Ṣugbọn kì í ṣe èmi tìkara mi, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tí ó wà pẹlu mi ni. Nítorí náà, ìbáà ṣe èmi ni, tabi àwọn aposteli yòókù, bákan náà ni iwaasu wa, bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí ẹ gbàgbọ́. Nígbà tí ó jẹ́ pé, à ń kéde pé Kristi jinde kúrò ninu òkú, báwo ni àwọn kan ninu yín ṣe wá ń wí pé kò sí ajinde òkú? Bí kò bá sí ajinde òkú, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde. Bí a kò bá jí Kristi dìde ninu òkú, a jẹ́ pé asán ni iwaasu wa, asán sì ni igbagbọ yín. Tí ó bá jẹ́ pé a kò jí àwọn òkú dìde, a tún jẹ́ pé a purọ́ mọ́ Ọlọrun, nítorí a jẹ́rìí pé ó jí Kristi dìde, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jí i dìde. Nítorí pé bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde. Bí a kò bá sì jí Kristi dìde, a jẹ́ pé lásán ni igbagbọ yín, ẹ sì wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín sibẹ. Tí ó bá wá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àwọn onigbagbọ tí wọ́n ti kú ti ṣègbé! Tí ó bá jẹ́ pé ninu ayé yìí nìkan ni a ní ìrètí ninu Kristi, àwa ni ẹni tí àwọn eniyan ìbá máa káàánú jùlọ! Ṣugbọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ yìí ni pé a ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú, òun sì ni àkọ́bí ninu àwọn tí wọ́n kú. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ eniyan ni ikú fi dé, nípasẹ̀ eniyan náà ni ajinde òkú fi dé. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ Adamu ni gbogbo eniyan ṣe kú, bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ Kristi ni a sọ gbogbo eniyan di alààyè. Ṣugbọn a óo jí olukuluku dìde létòlétò: Kristi ni ẹni àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá farahàn, a óo jí àwọn tíí ṣe tirẹ̀ dìde. Lẹ́yìn náà ni òpin yóo dé, lẹ́yìn tí ó bá ti dá ìjọba pada fún Ọlọrun Baba, tí ó sì ti pa gbogbo àṣẹ, ọlá ati agbára run. Nítorí ó níláti jọba títí Ọlọrun yóo fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí ìkáwọ́ rẹ̀. Ikú ni ọ̀tá ìkẹyìn tí yóo parun. Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ó ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.” Ṣugbọn nígbà tí ó sọ pé, “Gbogbo nǹkan ni ó fi sí ìkáwọ́ rẹ̀,” ó dájú pé ẹnìkan ni kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀: ẹni náà sì ni Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ Kristi. Nígbà tí gbogbo nǹkan bá ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ tán, ni Ọmọ fúnrarẹ̀ yóo wá bọ́ sí ìkáwọ́ Ọlọrun tí ó fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀, kí Ọlọrun lè jẹ́ olórí ohun gbogbo ninu ohun gbogbo. Ó tún ku nǹkankan! Nítorí kí ni àwọn kan ṣe ń ṣe ìrìbọmi nítorí àwọn tí ó kú? Bí a kò bá ní jí àwọn òkú dìde, kí ni ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe ìrìbọmi nítorí wọn? Àwa náà ńkọ́? Nítorí kí ni a ṣe ń fi ẹ̀mí wa wéwu nígbà gbogbo? Lojoojumọ ni mò ń kú! Ará, mo fi ìgbéraga tí mo ní ninu yín búra, àní èyí tí mo ní ninu Kristi Jesu Oluwa wa. Bí mo bá tìtorí iyì eniyan bá ẹranko jà ní Efesu, anfaani wo ni ó ṣe fún mi? Bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, bí wọ́n ti máa ń wí, wọn á ní: “Ẹ jẹ́ kí á máa jẹ, kí á máa mu, nítorí ọ̀la ni a óo kú.” Ẹ má jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ burúkú a máa ba ìwà rere jẹ́. Ẹ ronú, kí ẹ sì máa ṣe dáradára. Ẹ má dẹ́ṣẹ̀ mọ́. Àwọn tí kò mọ Ọlọrun wà láàrin yín! Mò ń sọ èyí kí ojú kí ó lè tì yín ni. Ṣugbọn ẹnìkan lè bèèrè pé, “Báwo ni a óo ti ṣe jí àwọn òkú dìde? Irú ara wo ni wọn óo ní?” Ìwọ òmùgọ̀ yìí! Bí irúgbìn tí a bá gbìn kò bá kọ́ kú, kò lè hù. Ohun tí ó bá hù kì í rí bí ohun tí a gbìn ti rí, nítorí pé irúgbìn lásán ni, ìbáà ṣe àgbàdo tabi àwọn ohun ọ̀gbìn yòókù. Ọlọrun ni ó ń fún un ní ara tí ó bá fẹ́, a fún irúgbìn kọ̀ọ̀kan ní ara tirẹ̀. Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe oríṣìí kan náà. Ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara eniyan, ọ̀tọ̀ ni ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ni ti ẹyẹ, ọ̀tọ̀ ni ti ẹja. Àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí tí ń fò lófuurufú wà. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ti orí ilẹ̀ wà. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà ti àwọn tí ń fò lófuurufú. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà àwọn ti orí ilẹ̀. Ọ̀tọ̀ ni ẹwà oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ ni ti àwọn ìràwọ̀, ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ara wọn ní ẹwà. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà ajinde àwọn òkú. A gbìn ín ní ara tíí díbàjẹ́; a jí i dìde ní ara tí kì í díbàjẹ́. A gbìn ín ní àìlọ́lá; a jí i dìde pẹlu ògo. A gbìn ín pẹlu àìlera: a jí i dìde pẹlu agbára. A gbìn ín pẹlu ara ti ẹ̀dá, a jí i dìde ní ara ti ẹ̀mí. Bí ara ti ẹ̀dá ti wà, bẹ́ẹ̀ ni ti ẹ̀mí wà. Ó wà ninu àkọsílẹ̀ pé, “Adamu, ọkunrin àkọ́kọ́ di alààyè;” ṣugbọn Adamu ìkẹyìn jẹ́ ẹ̀mí tí ó ń sọ eniyan di alààyè. Kì í ṣe ẹni ti ẹ̀mí ni ó kọ́kọ́ wà bíkòṣe ẹni ti ara, lẹ́yìn náà ni ẹni ti ẹ̀mí. Ọkunrin kinni tí a fi erùpẹ̀ dá jẹ́ erùpẹ̀, láti ọ̀run ni ọkunrin keji ti wá. Bí ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá ti rí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí a fi erùpẹ̀ dá rí. Bí ẹni tí ó wá láti ọ̀run ti rí, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ti ọ̀run rí. Bí a ti gbé àwòrán ti ẹni erùpẹ̀ wọ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni a óo gbé àwòrán ti ẹni ọ̀run wọ̀. Ará, ohun tí mò ń sọ ni pé ẹran-ara ati ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọrun, ati pé ohun tíí bàjẹ́ kò lè jogún ohun tí kì í bàjẹ́. Ẹ fetí sílẹ̀! Nǹkan àṣírí ni n óo sọ fun yín. Gbogbo wa kọ́ ni a óo kú, ṣugbọn nígbà tí fèrè ìkẹyìn bá dún, gbogbo wa ni a óo pa lára dà, kíá, bí ìgbà tí eniyan bá ṣẹ́jú. Nítorí fèrè yóo dún, a óo wá jí àwọn òkú dìde pẹlu ara tí kì í bàjẹ́, àwa náà yóo wá yipada. Nítorí ara tíí bàjẹ́ yìí níláti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀; ara tí yóo kú yìí níláti gbé ara tí kì í kú wọ̀. Nígbà tí ara tíí bàjẹ́ bá ti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀ tán, tí ara tí yóo kú bá sì ti gbé ara tí kì í kú wọ̀, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ tí a ti kọ sílẹ̀ yóo wá ṣẹ pé, “A ti gbé ikú mì, a sì ti ṣẹgun.” “Ikú, oró rẹ dà? Isà òkú, ìṣẹ́gun rẹ dà?” Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó fún ikú lóró. Òfin ni ó fún ẹ̀ṣẹ̀ lágbára. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fún wa ní ìṣẹ́gun nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi. Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ dúró gbọningbọnin, láì yẹsẹ̀. Ẹ tẹra mọ́ iṣẹ́ Oluwa nígbà gbogbo. Ẹ kúkú ti mọ̀ pé làálàá tí ẹ̀ ń ṣe níbi iṣẹ́ Oluwa kò ní jẹ́ lásán.

I. Kor 15:1-58 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìhìnrere náà dí mí mọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró. Nípasẹ̀ ìhìnrere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹ̀yin kàn gbàgbọ́ lásán. Nítorí èyí tí mo rí gbà ṣáájú ohun gbogbo ní èmi pẹ̀lú ti fi lé e yín lọ́wọ́, bí Kristi ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tí wí. Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ tí wí; Àti pé ó farahàn Peteru, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ lẹ́ẹ̀kan náà; ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fi di ìsinsin yìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn. Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jakọbu; lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn aposteli. Àti níkẹyìn gbogbo wọn ó farahàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀. Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn aposteli, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní aposteli, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fi fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ jú gbogbo wọn lọ: ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi. Nítorí náà ìbá à ṣe èmí tàbí àwọn ni, èyí ní àwa wàásù, èyí ní ẹ̀yin sì gbàgbọ́. Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kristi pé ó tí jíǹde kúrò nínú òkú, èéha tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín fi wí pé, àjíǹde òkú kò sí. Ṣùgbọ́n bí àjíǹde òkú kò sí, ǹjẹ́ Kristi kò jíǹde. Bí Kristi kò bá sì jíǹde, ǹjẹ́ asán ni ìwàásù wà, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, a mú wa ni ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run; nítorí ti àwa jẹ́rìí Ọlọ́run pé ó jí Kristi dìde kúrò nínú òkú: ẹni tí òun kò jí dìde bí ó bá ṣe pé àwọn òkú kò jíǹde? Nítorí pé bi á kò bá jí àwọn òkú dìde, ǹjẹ́ a kò jí Kristi dìde, bí a kò bá sì jí Kristi dìde, asán ní ìgbàgbọ́ yín; ẹ̀yin wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín síbẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn pẹ̀lú tí ó sùn nínú Kristi ṣègbé. Bí ó bá ṣe pé kìkì ayé yìí nìkan ní àwa ní ìrètí nínú Kristi, àwa jásí òtòṣì jùlọ nínú gbogbo ènìyàn. Ǹjẹ́ nísinsin yìí Kristi tí jíǹde kúrò nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn. Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nípa ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú. Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kristi. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀: Kristi àkọ́bí; lẹ́yìn èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kristi ni wíwá rẹ̀. Nígbà náà ni òpin yóò dé, nígbà tí ó bá ti fi ìjọba fún Ọlọ́run Baba, nígbà tí ó bá pa gbogbo àṣẹ àti gbogbo ọlá àti agbára run. Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jẹ ọba kí òun to fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ikú ní ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun “Nítorí ó ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé, “Ohun gbogbo ni á fi sí abẹ́ rẹ̀,” o dájú pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ní kò sí ní abẹ́ rẹ̀, Òun ní ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso Kristi. Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni á ó fi ọmọ tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jásí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo. Ní báyìí, bí kò bá sí àjíǹde, kín ní ète àwọn ènìyàn tí wọn ń tẹ bọ omi nítorí òkú? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde rárá, nítorí kín ni a ṣe ń bamitiisi wọn nítorí wọn? Nítorí kín ní àwa sì ṣe ń bẹ nínú ewu ni wákàtí gbogbo? Mo sọ nípa ayọ̀ tí mo ní lórí yín nínú Kristi Jesu Olúwa wá pé, èmi ń kú lójoojúmọ́. Kí a wí bí ènìyàn, bí mo bá ẹranko jà ní Efesu, àǹfààní kín ni ó jẹ́ fún mi? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde, “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí á máa mú; nítorí ní ọlá ni àwa ó kú.” Kí a má tàn yín jẹ́, “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́.” Ẹ jí ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀; nítorí àwọn ẹlòmíràn kò ni imọ̀ Ọlọ́run, mo sọ èyí kí ojú ba à lè tiyín. Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, “Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde? Irú ara wó ni wọn ó padà sí?” Ìwọ aláìmòye, ohun tí ìwọ fúnrúgbìn kì í yè bí kò ṣe pé ó ba kú: Àti èyí tí ìwọ fúnrúgbìn, kì í ṣe ara tí ń bọ̀ ni ìwọ fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n èso lásán ni, ìbá à ṣe alikama, tàbí irú mìíràn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún ún ni ara bí o tí wù ú, àti fún olúkúlùkù irúgbìn ara tirẹ̀. Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà: ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ. Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ: ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀. Ọ̀tọ̀ ni ògo ti oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a sí jì í dìde ni àìdíbàjẹ́: A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì jí í dìde ní agbára. A gbìn ín ni, ara ẹran a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí. Bí ara ẹran bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ. Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Adamu ọkùnrin ìṣáájú, alààyè ọkàn ni a dá a;” Adamu ìkẹyìn ẹ̀mí ìsọnidààyè. Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáájú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ara ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí. Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni. Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run. Bí àwa ti rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àwòrán ẹni ti ọ̀run. Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́. Kíyèsi í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín: gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà, Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìde ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà. Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní ìṣẹ́gun.” “Ikú, oró rẹ dà? Ikú, ìṣẹ́gun rẹ́ dà?” Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jesu Kristi! Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, ní ìwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa.