I. Kor 12:5-8
I. Kor 12:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Onirũru iṣẹ-iranṣẹ li ó si wà, Oluwa kanna si ni. Onirũru iṣẹ li o si wà, ṣugbọn Ọlọrun kanna ni ẹniti nṣiṣẹ gbogbo wọn ninu gbogbo wọn. Ṣugbọn a nfi ifihàn Ẹmí fun olukuluku enia lati fi jère. Nitoriti a fi ọ̀rọ ọgbọ́n fun ẹnikan nipa Ẹmí; ati fun ẹlomiran ọ̀rọ-ìmọ nipa Ẹmí kanna
I. Kor 12:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ iranṣẹ ni ó wà, ṣugbọn Oluwa kan náà ni à ń sìn. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà, ṣugbọn Ọlọrun kan náà ní ń ṣe ohun gbogbo ninu gbogbo eniyan. Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ń farahàn ninu olukuluku wa fún ire gbogbo wa. Nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni a ti fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, a sì fún ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà.
I. Kor 12:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni. Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gbogbo wọn nínú gbogbo wọn. Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè. Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn nímọ̀ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá. Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà ni èyí ti wá.