I. Kor 12

12
Àwọn Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́
1NJẸ niti ẹbun ẹmí, ará, emi kò fẹ ki ẹnyin ki o jẹ ope.
2Ẹnyin mọ̀ pe nigbati ẹnyin jẹ Keferi, a fà nyin lọ sọdọ awọn odi oriṣa, lọnakọna ti a fa nyin.
3Nitorina mo fẹ ki ẹ mọ̀ pe, kò si ẹniti nsọ̀rọ nipa Ẹmí Ọlọrun ki o wipe ẹni ifibu ni Jesu: ati pe, kò si ẹniti o le wipe, Oluwa ni Jesu, bikoṣe nipa Ẹmí Mimọ́.
4Njẹ onirũru ẹ̀bun li o wà, ṣugbọn Ẹmí kanna ni.
5Onirũru iṣẹ-iranṣẹ li ó si wà, Oluwa kanna si ni.
6Onirũru iṣẹ li o si wà, ṣugbọn Ọlọrun kanna ni ẹniti nṣiṣẹ gbogbo wọn ninu gbogbo wọn.
7Ṣugbọn a nfi ifihàn Ẹmí fun olukuluku enia lati fi jère.
8Nitoriti a fi ọ̀rọ ọgbọ́n fun ẹnikan nipa Ẹmí; ati fun ẹlomiran ọ̀rọ-ìmọ nipa Ẹmí kanna;
9Ati fun ẹlomiran igbagbọ́ nipa Ẹmí kanna; ati fun ẹlomiran ẹ̀bun imularada nipa Ẹmí kanna;
10Ati fun ẹlomiran iṣẹ iyanu iṣe; ati fun ẹlomiran isọtẹlẹ; ati fun ẹlomiran ìmọ ẹmí yatọ; ati fun ẹlomiran onirũru ède; ati fun ẹlomiran itumọ̀ ède:
11Ṣugbọn gbogbo wọnyi li ẹnikan nì, ani Ẹmí kanna nṣe, o npín fun olukuluku gẹgẹ bi o ti wù u.
Gbogbo Ìjọ Jẹ́ Ẹ̀yà Ara Kan
12Nitori gẹgẹ bi ara ti jẹ ọ̀kan, ti o si li ẹ̀ya pupọ, ṣugbọn ti gbogbo ẹ̀ya ara ti iṣe pupọ jẹ́ ara kan: bẹ̃ si ni Kristi pẹlu.
13Nitoripe ninu Ẹmí kan li a ti baptisi gbogbo wa sinu ara kan, iba ṣe Ju, tabi Hellene, iba ṣe ẹrú, tabi omnira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹmí kan.
14Nitoripe ara kì iṣe ẹ̀ya kan, bikoṣe pupọ.
15Bi ẹsẹ ba wipe, Nitori emi kì iṣe ọwọ́, emi kì iṣe ti ara; eyi kò wipe ki iṣe ti ara.
16Bi etí ba si wipe, Nitori emi ki iṣe oju, emi kì iṣe ti ara: eyi kò wipe ki iṣe ti ara.
17Bi gbogbo ara ba jẹ oju, nibo ni igbọràn iba gbé wà? Bi gbogbo rẹ̀ ba si jẹ igbọràn, nibo ni igbõrùn iba gbé wà?
18Ṣugbọn nisisiyi Ọlọrun ti fi awọn ẹ̀ya sinu ara, olukuluku wọn gẹgẹ bi o ti wù u.
19Bi gbogbo wọn ba si jẹ ẹ̀ya kan, nibo li ara iba gbé wà?
20Ṣugbọn nisisiyi, nwọn jẹ ẹya pupọ, ṣugbọn ara kan.
21Oju kò si le wi fun ọwọ́ pe, emi kò ni ifi ọ ṣe: tabi ki ori wi ẹ̀wẹ fun ẹsẹ pe, emi kò ni ifi nyin ṣe.
22Ṣugbọn awọn ẹ̀ya ara wọnni ti o dabi ẹnipe nwọn ṣe ailera jù, awọn li a kò le ṣe alaini jù:
23Ati awọn ẹ̀ya ara wọnni ti awa rò pe nwọn ṣe ailọlá jù, lori wọnyi li awa si nfi ọlá si jù; bẹni ibi aiyẹ wa si ni ẹyẹ lọpọlọpọ jù.
24Nitoripe awọn ibi ti o li ẹyẹ li ara wa kò fẹ ohun kan: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe ara lọkan, o si fi ọ̀pọlọpọ ọlá fun ibi ti o ṣe alaini:
25Ki ìyapa ki o máṣe si ninu ara; ṣugbọn ki awọn ẹ̀ya ara ki o le mã ṣe aniyan kanna fun ara wọn.
26Bi ẹ̀ya kan ba si njìya, gbogbo ẹ̀ya a si jùmọ ba a jìya; tabi bi a ba mbọla fun ẹ̀ya kan, gbogbo ẹ̀ya a jùmọ ba a yọ̀.
27Njẹ ara Kristi li ẹnyin iṣe, olukuluku nyin si jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀.
28Ọlọrun si gbé awọn miran kalẹ ninu ijọ, ekini awọn aposteli, ekeji awọn woli, ẹkẹta awọn olukọni, lẹhinna iṣẹ iyanu, lẹhinna ẹ̀bun imularada, iranlọwọ, ẹbùn akoso, onirũru ède.
29Gbogbo wọn ni iṣe aposteli bi? gbogbo wọn ni iṣe woli bi? gbogbo wọn ni iṣe olukọni bi? gbogbo wọn ni iṣe iṣẹ iyanu bi?
30Gbogbo wọn li o li ẹ̀bun imularada bi? gbogbo wọn ni nfi onirũru ède fọ̀ bi? gbogbo wọn ni nṣe itumọ̀ bi?
31Ṣugbọn ẹ mã fi itara ṣafẹri ẹ̀bun ti o tobi jù: sibẹ emi o fi ọ̀na kan ti o tayọ rekọja hàn nyin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kor 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa