I. Kor 12:28
I. Kor 12:28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọlọrun si gbé awọn miran kalẹ ninu ijọ, ekini awọn aposteli, ekeji awọn woli, ẹkẹta awọn olukọni, lẹhinna iṣẹ iyanu, lẹhinna ẹ̀bun imularada, iranlọwọ, ẹbùn akoso, onirũru ède.
I. Kor 12:28 Yoruba Bible (YCE)
Oríṣìíríṣìí eniyan ni Ọlọrun yàn ninu ìjọ: àwọn kinni ni àwọn aposteli, àwọn keji, àwọn wolii; àwọn kẹta, àwọn olùkọ́ni; lẹ́yìn náà, àwọn oníṣẹ́ ìyanu, kí ó tó wá kan àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn tabi àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, tabi àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti darí ètò iṣẹ́ ìjọ, ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti sọ èdè àjèjì.
I. Kor 12:28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè.