I. Kor 12:18-27
I. Kor 12:18-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn nisisiyi Ọlọrun ti fi awọn ẹ̀ya sinu ara, olukuluku wọn gẹgẹ bi o ti wù u. Bi gbogbo wọn ba si jẹ ẹ̀ya kan, nibo li ara iba gbé wà? Ṣugbọn nisisiyi, nwọn jẹ ẹya pupọ, ṣugbọn ara kan. Oju kò si le wi fun ọwọ́ pe, emi kò ni ifi ọ ṣe: tabi ki ori wi ẹ̀wẹ fun ẹsẹ pe, emi kò ni ifi nyin ṣe. Ṣugbọn awọn ẹ̀ya ara wọnni ti o dabi ẹnipe nwọn ṣe ailera jù, awọn li a kò le ṣe alaini jù: Ati awọn ẹ̀ya ara wọnni ti awa rò pe nwọn ṣe ailọlá jù, lori wọnyi li awa si nfi ọlá si jù; bẹni ibi aiyẹ wa si ni ẹyẹ lọpọlọpọ jù. Nitoripe awọn ibi ti o li ẹyẹ li ara wa kò fẹ ohun kan: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe ara lọkan, o si fi ọ̀pọlọpọ ọlá fun ibi ti o ṣe alaini: Ki ìyapa ki o máṣe si ninu ara; ṣugbọn ki awọn ẹ̀ya ara ki o le mã ṣe aniyan kanna fun ara wọn. Bi ẹ̀ya kan ba si njìya, gbogbo ẹ̀ya a si jùmọ ba a jìya; tabi bi a ba mbọla fun ẹ̀ya kan, gbogbo ẹ̀ya a jùmọ ba a yọ̀. Njẹ ara Kristi li ẹnyin iṣe, olukuluku nyin si jẹ ẹ̀ya ara rẹ̀.
I. Kor 12:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà. Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo nínú ẹ̀yà ara, níbo ni ara yóò gbé wà. Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni. Bí ó tí rí yìí, ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò le sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan an ni a kò le ṣe aláìnílò. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé ko yẹ rárá ni àwa ń fi si ipò ọlá ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ. Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní. Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn. Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀. Gbogbo yín jẹ́ ara Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kristi.
I. Kor 12:18-27 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn lóòótọ́ ni, Ọlọrun fi àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan sí ipò wọn bí ó ti wù ú. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yà kan ṣoṣo ni gbogbo ara ní, níbo ni ara ìbá wà? Bí ó ti wà yìí, ẹ̀yà pupọ ni ó ní, ṣugbọn ara kan ṣoṣo ni. Ojú kò lè wí fún ọwọ́ pé, “N kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè wí fún ẹsẹ̀ pé, “N kò nílò yín.” Kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ẹ̀yà ara tí kò lágbára jẹ́ àwọn tí a kò lè ṣe aláìní. Àwọn ẹ̀yà mìíràn tí a rò pé wọn kò dùn ún wò ni à ń dá lọ́lá jù. Àwọn ẹ̀yà ara tí kò dùn ún wò ni à ń yẹ́ sí jùlọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀yà ara tí ó dùn ún wò kò nílò ọ̀ṣọ́ lọ títí. Ọlọrun ti ṣe ètò àwọn ẹ̀yà ara ní ọ̀nà tí ó fi fi ọlá fún àwọn ẹ̀yà tí kò dùn ún wò, kí ó má baà sí ìyapa ninu ara, ṣugbọn kí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara lè máa ṣe aájò kan náà fún ara wọn. Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jẹ ìrora, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù níí máa bá a jẹ ìrora. Bí ara bá tu ẹ̀yà kan, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù ni yóo máa bá a yọ̀. Ẹ̀yin ni ara Kristi, ẹ̀yà ara rẹ̀ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan yín.