I. Kor 12:14-18
I. Kor 12:14-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe ara kì iṣe ẹ̀ya kan, bikoṣe pupọ. Bi ẹsẹ ba wipe, Nitori emi kì iṣe ọwọ́, emi kì iṣe ti ara; eyi kò wipe ki iṣe ti ara. Bi etí ba si wipe, Nitori emi ki iṣe oju, emi kì iṣe ti ara: eyi kò wipe ki iṣe ti ara. Bi gbogbo ara ba jẹ oju, nibo ni igbọràn iba gbé wà? Bi gbogbo rẹ̀ ba si jẹ igbọràn, nibo ni igbõrùn iba gbé wà? Ṣugbọn nisisiyi Ọlọrun ti fi awọn ẹ̀ya sinu ara, olukuluku wọn gẹgẹ bi o ti wù u.
I. Kor 12:14-18 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo ni ara ní; wọ́n pọ̀. Bí ẹsẹ̀ bá sọ pé, “Èmi kì í ṣe ọwọ́, nítorí náà èmi kò sí ninu ara,” èyí kò wí pé kì í tún ṣe ẹ̀yà ara mọ́. Bí etí bá sọ pé, “Èmi kì í ṣe ojú, nítorí náà èmi kò sí ninu ara,” kò wí pé kí ó má ṣe ẹ̀yà ara mọ́. Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, báwo ni yóo ti ṣe gbọ́ràn? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, báwo ni yóo ti ṣe gbóòórùn? Ṣugbọn lóòótọ́ ni, Ọlọrun fi àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan sí ipò wọn bí ó ti wù ú.
I. Kor 12:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀. Tí ẹsẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara. Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” èyí kò le mú kí ó má jẹ́ apá kan ara mọ́ Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, níbo ni ìgbọ́ran ìbá gbé wà? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, níbo ni ìgbóórùn ìbá gbé wà? Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà.