I. Kor 12:12-13
I. Kor 12:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori gẹgẹ bi ara ti jẹ ọ̀kan, ti o si li ẹ̀ya pupọ, ṣugbọn ti gbogbo ẹ̀ya ara ti iṣe pupọ jẹ́ ara kan: bẹ̃ si ni Kristi pẹlu. Nitoripe ninu Ẹmí kan li a ti baptisi gbogbo wa sinu ara kan, iba ṣe Ju, tabi Hellene, iba ṣe ẹrú, tabi omnira; a si ti mú gbogbo wa mu ninu Ẹmí kan.
I. Kor 12:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ara ti jẹ́ ọ̀kan, tí ó ní ọpọlọpọ ẹ̀yà, bí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ti pọ̀ tó, sibẹ tí ara jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, bẹ́ẹ̀ ni Kristi rí. Nítorí nípa Ẹ̀mí kan ni gbogbo wa fi ṣe ìrìbọmi tí a fi di ara kan, ìbáà ṣe pé a jẹ́ Juu tabi Giriki, à báà jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ninu Ẹ̀mí kan ṣoṣo ni a ti fún gbogbo wa mu.
I. Kor 12:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan ṣoṣo. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kristi tí í ṣe ìjọ. Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà.