I. Kor 12:1-11

I. Kor 12:1-11 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ̀yin ará, n kò fẹ́ kí nǹkan nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣókùnkùn si yín. Ẹ mọ̀ pé nígbà tí ẹ jẹ́ aláìmọ Ọlọrun, ẹ̀ ń bọ oriṣa tí kò lè fọhùn. À ń tì yín síwá sẹ́yìn. Nítorí náà, mò ń fi ye yín pé kò sí ẹni tí ó lè máa fi agbára Ẹ̀mí Ọlọrun sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ fi Jesu gégùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè wí pé, “Jesu ni Oluwa,” láìjẹ́ pé Ẹ̀mí Mímọ́ bá darí rẹ̀. Oríṣìíríṣìí ni ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà ni wọ́n ti ń wá. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ iranṣẹ ni ó wà, ṣugbọn Oluwa kan náà ni à ń sìn. Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà, ṣugbọn Ọlọrun kan náà ní ń ṣe ohun gbogbo ninu gbogbo eniyan. Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ń farahàn ninu olukuluku wa fún ire gbogbo wa. Nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni a ti fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, a sì fún ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà. Ẹlòmíràn ní igbagbọ, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà; ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àtiṣe iṣẹ́ ìyanu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn iwaasu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí èké, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti túmọ̀ àwọn èdè àjèjì. Ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan ṣoṣo ni gbogbo ẹ̀bùn wọnyi ti wá; bí ó sì ti wù ú ni ó pín wọn fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

I. Kor 12:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè. Ẹ̀yin kò mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ kèfèrí, a fà yín lọ sọ́dọ̀ àwọn odi òrìṣà. Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jesu,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jesu,” bí kò ṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́. Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni o ń pín wọn. Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni. Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gbogbo wọn nínú gbogbo wọn. Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè. Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn nímọ̀ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá. Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà ni èyí ti wá. Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwòsàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí. Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrín àwọn ẹ̀mí. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀. Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí. Àní, Ẹ̀mí kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.