I. Kor 11:2-34

I. Kor 11:2-34 Bibeli Mimọ (YBCV)

Njẹ, ará, mo yìn nyin ti ẹnyin nranti mi ninu ohun gbogbo, ti ẹnyin ti di ẹ̀kọ́ wọnni mu ṣinṣin, ani gẹgẹ bi mo ti fi wọn le nyin lọwọ. Ṣugbọn mo fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, Kristi li ori olukuluku ọkunrin; ori obinrin si li ọkọ rẹ̀; ati ori Kristi si li Ọlọrun. Olukuluku ọkunrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ ti o bo ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀. Ṣugbọn olukuluku obinrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ li aibò ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀: nitori ọkanna ni pẹlu ẹniti o fári. Nitori bi obinrin kò ba bo ori, ẹ jẹ ki o rẹ́ irun rẹ̀ pẹlu: ṣugbọn bi o bá ṣepe ohun itiju ni fun obinrin lati rẹ́ irun tabi lati fári rẹ̀, jẹ ki o bò ori. Nitori nitõtọ kò yẹ ki ọkunrin ki o bò ori rẹ̀, niwọnbi on ti jẹ aworan ati ogo Ọlọrun: ṣugbọn obinrin ni iṣe ogo ọkunrin. Nitori ọkunrin kò ti ara obinrin wá; ṣugbọn obinrin ni o ti ara ọkunrin wá. Bẹ̃ni a kò dá ọkunrin nitori obinrin; ṣugbọn a da obinrin nitori ọkunrin. Nitori eyi li o fi yẹ fun obinrin lati ni ami aṣẹ li ori rẹ̀, nitori awọn angẹli. Ṣugbọn ọkunrin kò le ṣe laisi obinrin, bẹ̃ni obinrin kò le ṣe laisi ọkunrin ninu Oluwa. Nitori gẹgẹ bi obinrin ti ti ara ọkunrin wá, bẹ̃li ọkunrin tipasẹ obinrin wá pẹlu: ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun li ohun gbogbo ti wá. Ẹ gba a rò lãrin ẹnyin tikaranyin: o ha tọ́ ki obinrin ki o mã gbadura si Ọlọrun laibori? Ani ẹda tikararẹ̀ kò ha kọ́ nyin pe, bi ọkunrin ba ni irun gigun, àbuku ni fun u? Ṣugbọn bi obinrin ba ni irun gigun, ogo li o jẹ fun u: nitoriti a fi irun rẹ̀ fun u fun ibori. Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba dabi ẹniti o fẹran iyàn jija, awa kò ni irú aṣa bẹ̃, tabi awọn ijọ Ọlọrun. Ṣugbọn niti aṣẹ ti mo nfun nyin yi, emi kò yìn nyin pe, ẹ npejọ kì iṣe fun rere, ṣugbọn fun buburu. Nitori lọna ikini, mo gbọ́ pe, nigbati ẹnyin pejọ ni ijọ, ìyapa mbẹ lãrin nyin; mo si gbà a gbọ́ li apakan. Nitoripe kò le ṣe ki o má si adamọ pẹlu larin nyin, ki awọn ti o daju larin nyin ba le farahàn. Nitorina nigbati ẹnyin ba pejọ si ibi kanna, kì iṣe lati jẹ Onjẹ Oluwa. Nitoripe nigbati ẹnyin ba njẹun, olukuluku nkọ́ jẹ onjẹ tirẹ̀, ebi a si mã pa ẹnikan, ọti a si mã pa ẹnikeji. Kinla? ẹnyin kò ni ile nibiti ẹ o mã jẹ, ti ẹ o si mã mu? tabi ẹnyin ngàn ijọ Ọlọrun, ẹnyin si ndojutì awọn ti kò ni? Kili emi o wi fun nyin? emi o ha yìn nyin ninu eyi? emi kò yìn nyin. Nitoripe lọwọ Oluwa li emi ti gbà eyiti mo si ti fifun nyin, pe Jesu Oluwa li oru ọjọ na ti a fi i han, o mu akara: Nigbati o si ti dupẹ, o bù u, o si wipe, Gbà, jẹ: eyi li ara mi ti a bu fun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. Gẹgẹ bẹ̃ li o si mú ago, lẹhin onjẹ, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ mi: nigbakugba ti ẹnyin ba nmu u, ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi. Nitori nigbakugba ti ẹnyin ba njẹ akara yi, ti ẹnyin ba si nmu ago yi, ẹnyin nkede ikú Oluwa titi yio fi de. Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹ akara, ti o si mu ago Oluwa laiyẹ, yio jẹbi ara ati ẹ̀jẹ Oluwa. Ṣugbọn ki enia ki o wadi ara rẹ̀ daju, bẹ̃ni ki o si jẹ ninu akara na, ki o si mu ninu ago na. Nitori ẹnikẹni ti o ba njẹ, ti o ba si nmu laimọ̀ ara Oluwa yatọ, o njẹ o si nmu ẹbi fun ara rẹ̀. Nitori idi eyi li ọ̀pọlọpọ ninu nyin ṣe di alailera ati olokunrun, ti ọ̀pọlọpọ si sùn. Ṣugbọn bi awa ba wadi ara wa, a kì yio da wa lẹjọ. Ṣugbọn nigbati a ba ndá wa lẹjọ, lati ọwọ́ Oluwa li a ti nnà wa, ki a má bã dá wa lẹbi pẹlu aiye. Nitorina, ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba pejọ lati jẹun, ẹ mã duro dè ara nyin. Bi ebi ba npa ẹnikẹni, ki o jẹun ni ile; ki ẹnyin ki o má bã pejọ fun ẹbi. Iyokù li emi ó si tò lẹsẹsẹ nigbati mo ba de.

I. Kor 11:2-34 Yoruba Bible (YCE)

Mo yìn yín nítorí pé ẹ̀ ń ranti mi nígbà gbogbo, ati pé ẹ kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ tí mo fi kọ yín látijọ́ bọ́ lọ́wọ́ yín. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé Kristi ni orí fún olukuluku ọkunrin, ọkunrin ni orí fún obinrin, Ọlọrun wá ni orí Kristi. Ọkunrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu tí ó bo orí fi àbùkù kan orí rẹ̀. Ṣugbọn obinrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu láì bo orí rẹ̀ fi àbùkù kan orí rẹ̀. Ó dàbí kí ó kúkú fá orí rẹ̀. Nítorí bí obinrin kò bá bo orí, kí ó kúkú gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ ìtìjú fún obinrin láti gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀ tabi láti fá orí rẹ̀ a jẹ́ pé ó níláti bo orí rẹ̀. Nítorí kò tọ́ kí ọkunrin bo orí rẹ̀, nítorí àwòrán ati ògo Ọlọrun ni. Ṣugbọn ògo ọkunrin ni obinrin. Nítorí ọkunrin kò wá láti ara obinrin; obinrin ni ó wá láti ara ọkunrin. Ati pé a kò dá ọkunrin nítorí obinrin, obinrin ni a dá nítorí ọkunrin. Nítorí èyí, ó yẹ kí obinrin ní àmì àṣẹ ní orí nítorí àwọn angẹli. Ṣugbọn ṣá, ninu Oluwa, bí obinrin ti nílò ọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin nílò obinrin. Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ara ọkunrin ni obinrin ti wá, láti inú obinrin ni ọkunrin náà sì ti wá. Ṣugbọn ohun gbogbo ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá. Ẹ̀yin náà ẹ ro ọ̀rọ̀ ọ̀hún wò láàrin ara yín. Ǹjẹ́ ó bójú mu pé kí obinrin gbadura sí Ọlọrun láì bo orí? Mo ṣebí ìṣe ẹ̀dá pàápàá kọ yín pé tí ọkunrin bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn, ó fi àbùkù kan ara rẹ̀; bẹ́ẹ̀ sì ni pé ohun ìyìn ni ó jẹ́ fún obinrin tí ó bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn. Nítorí a fi irun gígùn fún obinrin láti bò ó lórí. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ mọ̀ pé ní tiwa, a kò ní oríṣìí àṣà mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ninu àwọn ìjọ Ọlọrun. Nígbà tí mò ń sọ èyí, nǹkankan wà tí n kò yìn yín fún, nítorí nígbà tí ẹ bá péjọ, ìpéjọpọ̀ yín ń ṣe ibi ju rere lọ. Nítorí, ní ọ̀nà kinni, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ìyapa a máa wà láàrin yín. Mo gbàgbọ́ pé òtítọ́ wà ninu ìròyìn yìí. Nítorí ìyapa níláti wà láàrin yín, kí àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́ láàrin yín lè farahàn. Nítorí èyí, nígbà tí ẹ bá péjọ sí ibìkan náà, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ni ẹ̀ ń jẹ. Nítorí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín níí máa kánjú jẹun, ebi a máa pa àwọn kan nígbà tí àwọn mìíràn ti mu ọtí lámuyó! Ṣé ẹ kò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ, kí ẹ máa mu ni? Àbí ẹ fẹ́ kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọrun ni? Ẹ fẹ́ dójú ti àwọn aláìní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ni kí n sọ fun yín? Ṣé kí n máa yìn yín ni? Rárá o! N kò ní yìn yín fún èyí. Nítorí láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni mo ti gba ohun tí mo fi kọ yín, pé ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi Jesu Oluwa lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ó mú burẹdi, lẹ́yìn tí ó ti dúpẹ́ tán, ó bù ú, ó ní, “Èyí ni ara mi tí ó wà fun yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Bákan náà ni ó mú ife lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Èyí ni ife ti majẹmu titun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ burẹdi yìí, tí ẹ sì ń mu ninu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Oluwa títí yóo fi dé. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jẹ burẹdi, tabi tí ó ń mu ninu ife Oluwa láìyẹ jẹ̀bi ìlòkulò ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa. Kí olukuluku yẹ ara rẹ̀ wò kí ó tó jẹ ninu burẹdi, kí ó sì tó mu ninu ife Oluwa. Nítorí ẹni tí ó bá ń jẹ, tí ó ń mu láìmọ ìyàtọ̀ tí ó wà ninu ara Kristi, ìdájọ́ ni ó ń jẹ, tí ó sì ń mu, lórí ara rẹ̀. Nítorí èyí ni ọpọlọpọ ninu yín ṣe di aláìlera ati ọlọ́kùnrùn, tí ọpọlọpọ tilẹ̀ ti kú. Ṣugbọn tí a bá ti yẹ ara wa wò, a kò ní dá wa lẹ́jọ́. Ṣugbọn bí a bá bọ́ sinu ìdájọ́ Oluwa, ó fi ń bá wa wí ni, kí ó má baà dá wa lẹ́bi pẹlu àwọn yòókù. Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá péjọ láti jẹun, ẹ máa dúró de ara yín. Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun kí ó tó kúrò ní ilé, kí ìpéjọpọ̀ yín má baà jẹ́ ìdálẹ́bi fun yín. Nígbà tí mo bá dé, n óo ṣe ètò nípa àwọn nǹkan tí ó kù.

I. Kor 11:2-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmí yìn yín fún rírántí mi nínú ohun gbogbo àti fún dídi gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ yín mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi lélẹ̀ fún un yín. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ̀yin mọ̀ pé, Kristi ni orí olúkúlùkù ọkùnrin, orí obìnrin sì ni ọkọ rẹ̀ àti orí Kristi sì ní Ọlọ́run. Gbogbo ọkùnrin tó bá borí rẹ̀ nígbà tó bá ń gbàdúrà tàbí sọtẹ́lẹ̀ kò bọ̀wọ̀ fún orí rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni obìnrin tí ó bá ń gbàdúrà tàbí tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀, kò bu ọlá fún orí ara rẹ̀ nítorí ọ̀kan náà ni pẹ̀lú ẹni tí ó fárí. Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀. Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un láti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀. Ṣùgbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwòrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe. Ọkùnrin kò ti inú obìnrin wá, ṣùgbọ́n a yọ obìnrin jáde lára ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni a kò dá ọkùnrin fún àǹfààní obìnrin ṣùgbọ́n a da obìnrin fún ọkùnrin. Nítorí ìdí èyí àti nítorí àwọn angẹli, ni obìnrin ṣe gbọdọ̀ ní ààmì àṣẹ rẹ̀ ní orí rẹ̀. Ẹ rántí pé, nínú ètò Ọlọ́run obìnrin kò lè wà láìsí ọkùnrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin kò lè wà láàsí obìnrin. Lóòtítọ́ láti ara ọkùnrin ni a ti yọ obìnrin jáde bẹ́ẹ̀ sì ni ọkùnrin tipasẹ̀ obìnrin wa. Ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ohun gbogbo ti wà. Kí ni ẹ̀yìn fúnrayín rò lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún obìnrin láti máa gbàdúrà Ọlọ́run ní gbangba láìbo orí rẹ̀ bí? Ǹjẹ́ ìwà abínibí yín kò ha kọ́ yín pé, bí ọkùnrin bá ní irun gígùn, àbùkù ni ó jẹ́ fún un. Ṣùgbọ́n bí obìnrin bá ní irun gígùn, ògo ni ó jẹ́ fún un nítorí irun gígùn tí a fi fún un jẹ́ ìbòrí fún un. Ṣùgbọ́n tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní ìlànà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrín ìjọ Ọlọ́run. Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá péjọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú. Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan. Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere. Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ. Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara. Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín. Nítorí èyí tí èmi gbà lọ́wọ́ Olúwa ni mo ti fi fún un yin. Ní alẹ́ ọjọ́ tí Judasi fihàn, Olúwa Jesu Kristi mú àkàrà. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkàrà náà tan, ó bù ú, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ gbà kí ẹ sì jẹ, èyí ní ara mi tí a fi fún un yín. Ẹ máa ṣe eléyìí ni rántí mi.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó sì wí pé, “Ago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, ẹ máa ṣe èyí, nígbàkígbà ti ẹ̀yìn bá ń mu ú, ní ìrántí mi.” Nítorí nígbàkúgbà tí ẹ bá ń jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ǹ mu nínú ago yìí, ni ẹ tún sọ nípa ikú Olúwa. Ẹ máa ṣe eléyìí títí yóò fi padà dé. Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà. Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín. Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáradára, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé. Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkúgbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbí fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín. Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni nínú yin, kí ó jẹun láti ilé wá, kí ó má ba á mú ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ nígbà tí ẹ bá péjọ. Tí mo bá dé, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ ìyókù tí n kò ì ti fẹnu bà lẹ́sẹẹsẹ.