Njẹ, ará, mo yìn nyin ti ẹnyin nranti mi ninu ohun gbogbo, ti ẹnyin ti di ẹ̀kọ́ wọnni mu ṣinṣin, ani gẹgẹ bi mo ti fi wọn le nyin lọwọ.
Ṣugbọn mo fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, Kristi li ori olukuluku ọkunrin; ori obinrin si li ọkọ rẹ̀; ati ori Kristi si li Ọlọrun.
Olukuluku ọkunrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ ti o bo ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀.
Ṣugbọn olukuluku obinrin ti ngbadura tabi ti nsọtẹlẹ li aibò ori rẹ̀, o ṣe alaibọ̀wọ fun ori rẹ̀: nitori ọkanna ni pẹlu ẹniti o fári.
Nitori bi obinrin kò ba bo ori, ẹ jẹ ki o rẹ́ irun rẹ̀ pẹlu: ṣugbọn bi o bá ṣepe ohun itiju ni fun obinrin lati rẹ́ irun tabi lati fári rẹ̀, jẹ ki o bò ori.
Nitori nitõtọ kò yẹ ki ọkunrin ki o bò ori rẹ̀, niwọnbi on ti jẹ aworan ati ogo Ọlọrun: ṣugbọn obinrin ni iṣe ogo ọkunrin.
Nitori ọkunrin kò ti ara obinrin wá; ṣugbọn obinrin ni o ti ara ọkunrin wá.
Bẹ̃ni a kò dá ọkunrin nitori obinrin; ṣugbọn a da obinrin nitori ọkunrin.
Nitori eyi li o fi yẹ fun obinrin lati ni ami aṣẹ li ori rẹ̀, nitori awọn angẹli.
Ṣugbọn ọkunrin kò le ṣe laisi obinrin, bẹ̃ni obinrin kò le ṣe laisi ọkunrin ninu Oluwa.
Nitori gẹgẹ bi obinrin ti ti ara ọkunrin wá, bẹ̃li ọkunrin tipasẹ obinrin wá pẹlu: ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun li ohun gbogbo ti wá.
Ẹ gba a rò lãrin ẹnyin tikaranyin: o ha tọ́ ki obinrin ki o mã gbadura si Ọlọrun laibori?
Ani ẹda tikararẹ̀ kò ha kọ́ nyin pe, bi ọkunrin ba ni irun gigun, àbuku ni fun u?
Ṣugbọn bi obinrin ba ni irun gigun, ogo li o jẹ fun u: nitoriti a fi irun rẹ̀ fun u fun ibori.
Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba dabi ẹniti o fẹran iyàn jija, awa kò ni irú aṣa bẹ̃, tabi awọn ijọ Ọlọrun.
Ṣugbọn niti aṣẹ ti mo nfun nyin yi, emi kò yìn nyin pe, ẹ npejọ kì iṣe fun rere, ṣugbọn fun buburu.
Nitori lọna ikini, mo gbọ́ pe, nigbati ẹnyin pejọ ni ijọ, ìyapa mbẹ lãrin nyin; mo si gbà a gbọ́ li apakan.
Nitoripe kò le ṣe ki o má si adamọ pẹlu larin nyin, ki awọn ti o daju larin nyin ba le farahàn.
Nitorina nigbati ẹnyin ba pejọ si ibi kanna, kì iṣe lati jẹ Onjẹ Oluwa.
Nitoripe nigbati ẹnyin ba njẹun, olukuluku nkọ́ jẹ onjẹ tirẹ̀, ebi a si mã pa ẹnikan, ọti a si mã pa ẹnikeji.
Kinla? ẹnyin kò ni ile nibiti ẹ o mã jẹ, ti ẹ o si mã mu? tabi ẹnyin ngàn ijọ Ọlọrun, ẹnyin si ndojutì awọn ti kò ni? Kili emi o wi fun nyin? emi o ha yìn nyin ninu eyi? emi kò yìn nyin.
Nitoripe lọwọ Oluwa li emi ti gbà eyiti mo si ti fifun nyin, pe Jesu Oluwa li oru ọjọ na ti a fi i han, o mu akara:
Nigbati o si ti dupẹ, o bù u, o si wipe, Gbà, jẹ: eyi li ara mi ti a bu fun nyin: ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi.
Gẹgẹ bẹ̃ li o si mú ago, lẹhin onjẹ, o wipe, Ago yi ni majẹmu titun ninu ẹ̀jẹ mi: nigbakugba ti ẹnyin ba nmu u, ẹ mã ṣe eyi ni iranti mi.
Nitori nigbakugba ti ẹnyin ba njẹ akara yi, ti ẹnyin ba si nmu ago yi, ẹnyin nkede ikú Oluwa titi yio fi de.
Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹ akara, ti o si mu ago Oluwa laiyẹ, yio jẹbi ara ati ẹ̀jẹ Oluwa.
Ṣugbọn ki enia ki o wadi ara rẹ̀ daju, bẹ̃ni ki o si jẹ ninu akara na, ki o si mu ninu ago na.
Nitori ẹnikẹni ti o ba njẹ, ti o ba si nmu laimọ̀ ara Oluwa yatọ, o njẹ o si nmu ẹbi fun ara rẹ̀.
Nitori idi eyi li ọ̀pọlọpọ ninu nyin ṣe di alailera ati olokunrun, ti ọ̀pọlọpọ si sùn.
Ṣugbọn bi awa ba wadi ara wa, a kì yio da wa lẹjọ.
Ṣugbọn nigbati a ba ndá wa lẹjọ, lati ọwọ́ Oluwa li a ti nnà wa, ki a má bã dá wa lẹbi pẹlu aiye.
Nitorina, ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba pejọ lati jẹun, ẹ mã duro dè ara nyin.
Bi ebi ba npa ẹnikẹni, ki o jẹun ni ile; ki ẹnyin ki o má bã pejọ fun ẹbi. Iyokù li emi ó si tò lẹsẹsẹ nigbati mo ba de.