I. Kor 10:9-11
I. Kor 10:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe dán Oluwa wò, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti dán a wò, ti a si fi ejò run wọn. Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe kùn, gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti kùn, ti a si ti ọwọ́ oluparun run wọn. Nkan wọnyi si ṣe si wọn bi apẹrẹ fun wa: a si kọwe wọn fun ikilọ̀ awa ẹniti igbẹhin aiye de bá.
I. Kor 10:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni kí á má ṣe dán Oluwa wò, bí àwọn mìíràn ninu wọn ti dán an wò, tí ejò fi ṣán wọn pa. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe kùn bí àwọn mìíràn ninu wọn ṣe kùn, tí Apani sì pa wọ́n. Gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. A kọ wọ́n sílẹ̀ kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa, àwa tí a wà ní ìgbà ìkẹyìn.
I. Kor 10:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá.