I. Kor 10:7-8
I. Kor 10:7-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si jẹ abọriṣa, bi awọn miran ninu wọn; bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia na joko lati jẹ ati lati mu, nwọn si dide lati ṣire. Bẹ̃ni ki awa ki o máṣe ṣe àgbere gẹgẹ bi awọn miran ninu wọn ti ṣe, ti ẹgbã-mọkanla-le-ẹgbẹrun enia si ṣubu ni ijọ kan.
I. Kor 10:7-8 Yoruba Bible (YCE)
Kí ẹ má sì di abọ̀rìṣà bí àwọn mìíràn ninu wọn. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn eniyan náà jókòó láti jẹ ati láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣe àríyá.” Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè bí àwọn mìíràn ninu wọn ti ṣe àgbèrè, tí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹẹdogun (23,000) eniyan fi kú ní ọjọ́ kan.
I. Kor 10:7-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan.