I. Kor 10:1-6
I. Kor 10:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORI emi kò fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀, ara, bi gbogbo awọn baba wa ti wà labẹ awọsanma, ti gbogbo wọn si là okun já; Ti a si baptisi gbogbo wọn si Mose ninu awọsanma ati ninu okun; Ti gbogbo wọn si ti jẹ onjẹ ẹmí kanna; Ti gbogbo wọn si mu ohun mimu ẹmí kanna: nitoripe nwọn nmu ninu Apata ẹmí ti ntọ̀ wọn lẹhin: Kristi si li Apata na. Ṣugbọn ọ̀pọlọpọ wọn ni inu Ọlọrun kò dùn si: nitoripe a bì wọn ṣubu li aginjù. Nkan wọnyi si jasi apẹrẹ fun awa, ki awa ki o má bã ṣe ifẹkufẹ ohun buburu, gẹgẹ bi awọn pẹlu ti ṣe ifẹkufẹ.

I. Kor 10:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, ẹ má gbàgbé pé gbogbo àwọn baba wa ni wọ́n wà lábẹ́ ìkùukùu. Gbogbo wọn ni wọ́n la òkun kọjá. Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìrìbọmi ninu ìkùukùu ati ninu òkun, kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Mose. Gbogbo wọn ni wọ́n jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. Gbogbo wọn ni wọ́n mu omi ẹ̀mí kan náà, nítorí wọ́n mu omi tí ó jáde láti inú òkúta ẹ̀mí tí ó ń tẹ̀lé wọn. Òkúta náà ni Kristi. Ṣugbọn sibẹ inú Ọlọrun kò dùn sí ọpọlọpọ ninu wọn, nítorí ọpọlọpọ wọn ni wọ́n kú dànù káàkiri ninu aṣálẹ̀. Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa, pé kí á má ṣe kó nǹkan burúkú lé ọkàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti kó o lé ọkàn.
I. Kor 10:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú aginjù. Ọlọ́run ṣamọ̀nà wọn nípa rírán ìkùùkuu síwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi Òkun pupa já. A lè pe eléyìí ní ìtẹ̀bọmi ti Mose nínú ìkùùkuu àti nínú omi Òkun. Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. Wọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù. Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si.