I. Kro 9:1-37
I. Kro 9:1-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
A si ka iye gbogbo Israeli ni idile idile wọn; si kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli: Juda li a si kó lọ si Babiloni nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀. Awọn ti o tetekọ gbe ilẹ ini wọn, ati ilu wọn li awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ati awọn Netinimu. Ni Jerusalemu ni, ninu awọn ọmọ Juda, ati ninu awọn ọmọ Benjamini, ati ninu awọn ọmọ Efraimu, ati Manasse ngbe; Utai ọmọ Ammihudi, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ninu awọn ọmọ Faresi ọmọ Juda. Ati ninu awọn ara Ṣilo, Asaiah akọbi, ati awọn ọmọ rẹ̀. Ati ninu awọn ọmọ Sera, Jegueli, ati awọn arakunrin wọn, ẹdẹgbẹrin o di mẹwa. Ati ninu awọn ọmọ Benjamini; Sallu, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah, ọmọ Senua. Ati Ibneiah ọmọ Jerohamu, ati Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri, ati Meṣullamu ọmọ Ṣefatiah, ọmọ Regueli, ọmọ Ibniah; Ati awọn arakunrin wọn, gẹgẹ bi idile wọn ẹgbẹrun o din mẹrinlelogoji. Gbogbo awọn ọkunrin wọnyi ni olori ninu awọn baba ni ile baba wọn. Ati ninu awọn alufa; Jedaiah, ati Jehoiaribu ati Jakini, Ati Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu olori ile Ọlọrun; Ati Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkijah, ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Meṣillemiti, ọmọ Immeri; Ati awọn arakunrin wọn olori ile baba wọn, ẹgbẹsan o din ogoji; awọn alagbara akọni ọkunrin fun iṣẹ ìsin ile Ọlọrun. Ati ninu awọn ọmọ Lefi; Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah, ninu awọn ọmọ Merari; Ati Bakbakkari, Hereṣi, ati Galali, ati Mattaniah ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu; Ati Obadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni, ati Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkanah, ti ngbe ileto awọn ara Netofa. Awọn adena si ni Ṣallumu, ati Akkubu, ati Talmoni, ati Ahimani, ati awọn arakunrin wọn; Ṣallumu li olori; Titi di isisiyi awọn ti o duro li oju-ọ̀na ọba niha ilà-õrùn; adena ni wọn li ẹgbẹ awọn ọmọ Lefi. Ati Ṣallumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora, ati awọn arakunrin rẹ̀, ti ile baba rẹ̀, awọn ọmọ Kora, ni mbẹ lori iṣẹ ìsin na, olutọju iloro agọ na; awọn baba wọn ti mbẹ lori ibudo Oluwa ti nwọn ima ṣọ atiwọ̀le na. Ati Finehasi ọmọ Eleasari ni olori lori wọn ni igba atijọ, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀. Sekariah ọmọ Meṣelemiah ni adena ilẹkun agọ ajọ enia. Gbogbo wọnyi ti a ti yàn lati ṣe adena loju iloro, jẹ igba o le mejila. A ka awọn wọnyi nipa idile wọn ni ileto wọn, awọn ẹniti Dafidi ati Samueli, ariran, ti yàn nitori otitọ wọn. Bẹ̃li awọn wọnyi ati awọn ọmọ wọn nṣẹ abojuto iloro ile Oluwa, eyini ni ile agọ na fun iṣọ. Ni igun mẹrẹrin ni awọn adena mbẹ, niha ilà-õrùn, ìwọ-õrún, ariwa ati gusu. Ati awọn arakunrin wọn ngbe ileto wọn, lati ma wá pẹlu wọn ni ijọ ekeje lati igba de igba. Nitoriti awọn ọmọ Lefi wọnyi jẹ awọn olori adena mẹrin, nwọn si wà ninu iṣẹ na, nwọn si wà lori iyara ati ibi iṣura ile Ọlọrun. Nwọn a si ma sùn yi ile Ọlọrun ka, nitori ti nwọn ni itọju na, ati ṣiṣi rẹ̀ li orowurọ jẹ ti wọn. Ati awọn kan ninu wọn ni itọju ohun elo ìsin, lati ma kó wọn sinu ile ati si ode ni iye. Ninu wọn li a yàn lati ma bojuto ohun elo, ati gbogbo ohun elo ibi mimọ́, ati iyẹfun kikunna, ati ọti-waini, ati ororo, ati ojia, ati turari. Ati omiran ninu awọn ọmọ awọn alufa si fi turari ṣe ororo. Ati Mattitiah, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi, ti iṣe akọbi Ṣallumu ọmọ Kora, li o nṣe alabojuto iṣẹ ohun ti a ndín. Ati ninu awọn arakunrin wọn ninu awọn ọmọ Kohati li o nṣe itọju akara-ifihan, lati mã pese rẹ̀ li ọjọjọ isimi. Wọnyi si li awọn akọrin, olori awọn baba awọn ọmọ Lefi, nwọn kò ni iṣẹ ninu iyara wọnni; nitori ti nwọn wà lẹnu iṣẹ wọn lọsan ati loru. Awọn wọnyi ni olori baba awọn ọmọ Lefi, ni iran wọn, olori ni nwọn: awọn wọnyi ni ngbe Jerusalemu. Ati ni Gibeoni ni baba Gibeoni ngbe, Jegieli, orukọ aya ẹniti ijẹ Maaka. Akọbi ọmọ rẹ̀ si ni Abdoni, ati Suri ati Kiṣi, ati Baali, ati Neri, ati Nadabu, Ati Gedori, ati Ahio, ati Sekariah ati Mikloti.
I. Kro 9:1-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo Israẹli ni a kọ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Israẹli. Àwọn ènìyàn Juda ni a kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli nítorí àìṣòótọ́ wọn. Nísinsin yìí, àwọn tí ó kọ́kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi àti àwọn Ìránṣẹ́ ilé OLúWA. Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́: Uttai ọmọ Ammihudu, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ìran ọmọ Peresi ọmọ Juda. Àti nínú ará Ṣilo: Asaiah àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀. Ní ti ará Sera: Jeueli Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690). Àti nínú àwọn ọmọ Benjamini ni: Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah; ọmọ Hasenuah; Ibinaiah ọmọ Jerohamu; Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri; àti Meṣullamu ọmọ Ṣefatia; ọmọ Reueli, ọmọ Ibinijah. Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì, (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé. Ní ti àwọn àlùfáà: Jedaiah; Jehoiaribi; Jakini; Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, olórí tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run; Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah; àti Masai ọmọ Adieli, ọmọ Jahisera, ọmọ Meṣullamu ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Immeri Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run. Ní ti àwọn ará Lefi: Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ará Merari; Bakibakari, Hereṣi, Galali àti Mattaniah, ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu; Ọbadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni; àti Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkana, Tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Netofa. Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà: Ṣallumu, Akkubu, Talmoni, Ahimani àti arákùnrin wọn, Ṣalumu olóyè wọn, ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu-ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà-oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Lefi. Ṣallumu ọmọ Kore ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Láti ìdílé rẹ̀ (àwọn ará Korati) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìloro ẹnu-ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ àbáwọlé ibùgbé OLúWA. Ní ìgbà àkọ́kọ́ Finehasi ọmọ Eleasari jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà, OLúWA sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé. Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó-lé-méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn. Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé OLúWA ilé tí a pè ní àgọ́. Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn àríwá àti gúúsù. Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje. Ṣùgbọ́n àwọn olórí alábojútó ẹnu-ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìṣúra ní ilé Ọlọ́run. Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ; Wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀. Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Ọlọ́run; wọn a máa kà á nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde. Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí olóòórùn dídùn. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípò tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀. Ará Lefi tí a sọ ní Mattitiah àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣallumu ará Kora ni a yàn, tí ń ṣe alábojútó ohun tí a dín. Àti nínú àwọn arákùnrin wọn, nínú àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn, láti máa pèsè rẹ̀ ní ọjọọjọ́ ìsinmi. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, olórí àwọn ìdílé Lefi dúró nínú àgọ́ ilé OLúWA, wọn kò sì ṣe lára iṣẹ́ ìsìn yòókù nítorí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà lọ́sàn, lóru. Gbogbo wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn Lefi, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ lẹ́sẹẹsẹ sínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu. Jeieli baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. Orúkọ ìyàwó rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka, Pẹ̀lú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ Abdoni, tí wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu. Gedori, Ahio, Sekariah àti Mikiloti.
I. Kro 9:1-37 Yoruba Bible (YCE)
A kọ orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìran wọn; a kọ wọ́n sinu ìwé Àwọn Ọba Israẹli. A kó àwọn ẹ̀yà Juda ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni nítorí pé wọ́n ṣe alaiṣootọ sí Ọlọrun. Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ pada dé sórí ilẹ̀ wọn, ní ìlú wọn, ni àwọn ọmọ Israẹli, àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn òṣìṣẹ́ inú tẹmpili. Àwọn eniyan tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Juda, Bẹnjamini, Efuraimu, ati Manase tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Utai ọmọ Amihudu, ọmọ Omiri, ọmọ Imiri, ọmọ Bani, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Pẹrẹsi, ọmọ Juda. Àwọn ọmọ Ṣilo ni Asaaya, àkọ́bí rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ ti Sera ni Jeueli ati àwọn ìbátan rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó dín mẹ́wàá (690). Àwọn tí wọ́n wá láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini ni: Salu, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Hodafaya, ọmọ Hasenua, Ibineaya, ọmọ Jerohamu, Ela, ọmọ Usi, ọmọ Mikiri, Meṣulamu, ọmọ Ṣefataya, ọmọ Reueli, ọmọ Ibinija. Àwọn ìbátan wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti tò wọ́n sinu ìwé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹrindinlọgọta (956). Gbogbo wọn jẹ́ baálé ninu ìdílé wọn, tí ń gbé Jerusalẹmu. Àwọn alufaa tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Jedaaya, Jehoiaribu, Jakini, ati Asaraya ọmọ Hilikaya, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraiotu, ọmọ Ahitubu, olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé Ọlọrun; ati Adaaya, ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malikija ati Maasai ọmọ Adieli, ọmọ Jasera, ọmọ Meṣulamu, ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Imeri. Àwọn tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ilé Ọlọrun láìka àwọn eniyan wọn ati àwọn olórí ìdílé wọn gbogbo jẹ́ ẹgbẹsan ó dín ogoji (1,760). Àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣemaaya ọmọ Haṣihubu, ọmọ Asirikamu, ọmọ Haṣabaya, lára àwọn ọmọ Merari; ati Bakibakari, Hereṣi, Galali ati Matanaya ọmọ Mika, ọmọ Sikiri, ọmọ Asafu, ati Ọbadaya ọmọ Ṣemaaya, ọmọ Galali, ọmọ Jẹdutumu, ati Berekaya ọmọ Asa, ọmọ Elikana, tí ń gbé agbègbè tí àwọn ọmọ Netofa wà. Àwọn aṣọ́nà Tẹmpili nìwọ̀nyí: Ṣalumu, Akubu, Talimoni, Ahimani, ati àwọn eniyan wọn; (Ṣalumu ni olórí wọn). Wọ́n ń ṣọ́ apá ẹnu ọ̀nà ìlà oòrùn ilé ọba. Àwọn ni wọ́n ń ṣọ́ àgọ́ àwọn ọmọ Lefi tẹ́lẹ̀. Ṣalumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora ati àwọn ará ilé baba rẹ̀. Gbogbo ìdílé Kora ni alabojuto iṣẹ́ ìsìn ninu tẹmpili ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé àgọ́, gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti jẹ́ alabojuto Àgọ́ OLUWA ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀. Finehasi, ọmọ Eleasari ni olórí wọn tẹ́lẹ̀ rí, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀. Sakaraya, ọmọ Meṣelemaya ni olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Gbogbo àwọn olùṣọ́nà tí wọ́n yàn láti máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé jẹ́ igba ó lé mejila (212). A kọ orúkọ wọn sinu ìwé gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní agbègbè wọn. Dafidi ati Samuẹli aríran, ni wọ́n fi wọ́n sí ipò pataki náà. Nítorí náà, àwọn ati àwọn ọmọ wọn ni wọ́n ń ṣe alabojuto ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, àwọn ni wọ́n fi ṣe olùṣọ́ Àgọ́ Àjọ. Ọ̀gá aṣọ́nà kọ̀ọ̀kan wà ní ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin: ní ìhà ìlà oòrùn, ati ìwọ̀ oòrùn, ati àríwá, ati gúsù; àwọn eniyan wọn tí wọn ń gbé àwọn ìletò a máa wá ní ọjọ́ meje meje, láti ìgbà dé ìgbà, láti wà pẹlu àwọn olórí ọ̀gá aṣọ́nà mẹrin náà. Nítorí àwọn olórí mẹrin wọnyi, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, ni wọ́n tún ń ṣe alabojuto àwọn yàrá tẹmpili ati àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé Ọlọrun. Wọ́n ń gbé àyíká ilé Ọlọrun, nítorí iṣẹ́ wọn ni láti máa bojútó o, ati láti máa ṣí ìlẹ̀kùn rẹ̀ ní àràárọ̀. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ Lefi ni alabojuto àwọn ohun èlò ìjọ́sìn, iṣẹ́ wọn ni láti máa fún àwọn tí wọ́n ń lò wọ́n, ati láti gbà wọ́n pada sí ipò wọn, kí wọ́n sì kà wọ́n kí wọ́n rí i pé wọ́n pé. Iṣẹ́ àwọn mìíràn ninu wọn ni láti máa tọ́jú ohun ọ̀ṣọ́ tẹmpili ati ohun èlò mímọ́, ati ìyẹ̀fun ọkà, waini, òróró, turari, ati òjíá. Àwọn ọmọ alufaa yòókù ni wọ́n ń po turari, Matitaya, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi tí ó jẹ́ àkọ́bí Ṣalumu ará Kora níí máa ń ṣe àkàrà ìrúbọ. Bákan náà, àwọn kan ninu àwọn ọmọ Kohati, ni wọ́n máa ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn ní ọjọọjọ́ ìsinmi. Àwọn ọmọ Lefi kan wà fún orin kíkọ ninu tẹmpili, wọ́n jẹ́ baálé baálé ninu ẹ̀yà Lefi, ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu tẹmpili ni àwọn ń gbé, wọn kì í bá àwọn yòókù ṣiṣẹ́ mìíràn ninu tẹmpili, nítorí pé iṣẹ́ tiwọn ni orin kíkọ tọ̀sán-tòru. Baálé baálé ni àwọn tí a ti dárúkọ wọnyi ninu ìdílé wọn, olórí ni wọ́n ninu ẹ̀yà Lefi, wọ́n ń gbé Jerusalẹmu. Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ìlú Gibeoni, iyawo rẹ̀ ń jẹ́ Maaka, Abidoni ni àkọ́bí rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó bí: Suri, Kiṣi, Baali, Neri, ati Nadabu; Gedori, Ahio, Sakaraya, ati Mikilotu