I. Kro 22:11-13
I. Kro 22:11-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ ọmọ mi, ki Oluwa ki o pẹlu rẹ; iwọ si ma pọ̀ si i, ki o si kọ́ ile Oluwa Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ nipa tirẹ. Kiki ki Oluwa ki o fun ọ li ọgbọ́n ati oye, ki o si fun ọ li aṣẹ niti Israeli, ki iwọ ki o le pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ́. Nigbana ni iwọ o ma pọ̀ si i, bi iwọ ba ṣe akiyesi lati mu aṣẹ ati idajọ ti Oluwa pa fun Mose ṣẹ niti Israeli: mura giri ki o si ṣe onigboya, má bẹ̀ru bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò ọ.
I. Kro 22:11-13 Yoruba Bible (YCE)
“Nisinsinyii, ìwọ ọmọ mi, OLUWA yóo wà pẹlu rẹ, kí o lè kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun rẹ fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. Kí OLUWA fún ọ ní ọgbọ́n ati làákàyè kí o lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́ nígbà tí ó bá fi ọ́ jọba lórí Israẹli. Bí o bá pa gbogbo òfin tí Ọlọrun fún Israẹli láti ọwọ́ Mose mọ́, o óo ṣe rere. Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, má bẹ̀rù, má sì ṣe jẹ́ kí àyà fò ọ́.
I. Kro 22:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nísinsin yìí, ọmọ mi, kí OLúWA wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé OLúWA Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. Kí OLúWA kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin OLúWA Ọlọ́run mọ́. Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti OLúWA ti fi fún Mose fun Israẹli ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́.