I. Kro 16:23-31
I. Kro 16:23-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ kọrin titun si Oluwa gbogbo aiye; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ. Ẹ sọ̀rọ ogo rẹ̀ ninu awọn keferi; ati iṣẹ-iyanu rẹ̀ ninu gbogbo enia. Nitori titobi li Oluwa, o si ni iyìn gidigidi: on li o si ni ibẹ̀ru jù gbogbo oriṣa lọ. Nitori pe gbogbo oriṣa awọn enia, ere ni nwọ́n: ṣugbọn Oluwa li o da awọn ọrun. Ogo on ọlá wà niwaju rẹ̀; agbara ati ayọ̀ mbẹ ni ipò rẹ̀. Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipa fun Oluwa. Ẹ fi ogo fun Oluwa ti o yẹ fun orukọ rẹ̀: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá siwaju rẹ̀: ẹ sin Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́. Ẹ warìri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye, aiye pẹlu si fi idi mulẹ ti kì o fi le yi. Jẹ ki awọn ọrun ki o yọ̀, si jẹ ki inu aiye ki o dùn; si jẹ ki a wi ninu awọn orilẹ-ède pe, Oluwa jọba.
I. Kro 16:23-31 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kọrin sí OLUWA, gbogbo ayé! Ẹ máa kéde ìgbàlà rẹ̀ lojoojumọ. Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan! OLUWA tóbi, ìyìn tọ́ sí i lọpọlọpọ ó sì yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún un ju gbogbo àwọn oriṣa lọ. Nítorí pé ère lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù sọ di ọlọrun, ṣugbọn OLUWA ló dá ọ̀run. Ògo ati agbára yí i ká, ayọ̀ ati ìyìn sì kún Tẹmpili rẹ̀. Ẹ fi ògo fún OLUWA, gbogbo ayé, ẹ gbé ògo ati agbára wọ̀ ọ́! Ẹ fi ògo tí ó yẹ orúkọ OLUWA fún un, ẹ mú ọrẹ wá sí iwájú rẹ̀! Ẹ sin OLUWA pẹlu ẹwà mímọ́, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé, ó fi ìdí ayé múlẹ̀ gbọningbọnin kò sì lè yẹ̀ lae. Kí inú ọ̀run kí ó dùn, kí ayé kí ó yọ̀, kí wọ́n sọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé “OLUWA jọba!”
I. Kro 16:23-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọrin sí OLúWA gbogbo ayé; ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́. Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn. Nítorí títóbi ni OLúWA òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ; òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ. Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà, ṣùgbọ́n OLúWA dá àwọn ọ̀run. Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀; agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀. Fi fún OLúWA, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ fi ògo àti ipá fún OLúWA. Fún OLúWA ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀; gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀. Sìn OLúWA nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀. Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé! Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i. Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn; Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “OLúWA jẹ ọba!”