I. Kro 16:1-7
I. Kro 16:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
BẸ̀NI nwọn mu apoti ẹri Ọlọrun wá, nwọn si fi si arin agọ na ti Dafidi pa fun u: nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju Ọlọrun, Nigbati Dafidi si ti pari riru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia tan, o sure fun awọn enia li orukọ Oluwa. O si fi fun gbogbo enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin fun olukulùku iṣu akara kan, ati ekiri ẹran kan, ati akara didùn kan. O si yan ninu awọn ọmọ Lefi lati ma jọsin niwaju apoti ẹri Oluwa, ati lati ṣe iranti, ati lati dupẹ, ati lati yìn Oluwa Ọlọrun Israeli: Asafu ni olori, ati atẹle rẹ̀ ni Sekariah, Jeieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Mattitiah, ati Eliabu, ati Benaiah, ati Obed-Edomu: ati Jeieli pẹlu psalteri ati pẹlu duru; ṣugbọn Asafu li o nlù kimbali kikan; Benaiah pẹlu ati Jahasieli awọn alufa pẹlu ipè nigbagbogbo niwaju apoti ẹri ti majẹmu Ọlọrun. Li ọjọ na ni Dafidi kọ́ fi orin mimọ́ yi le Asafu lọwọ lati dupẹ lọwọ Oluwa.
I. Kro 16:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun kalẹ̀ ninu àgọ́ tí Dafidi ti tọ́jú sílẹ̀ fún un, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú Ọlọrun. Nígbà tí Dafidi rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA, ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, atọkunrin atobinrin, ní burẹdi kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran yíyan kọ̀ọ̀kan ati àkàrà èso resini. Ó sì yan àwọn ọmọ Lefi kan láti máa ṣe ètò ìsìn níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA: láti máa gbadura, láti máa dúpẹ́, ati láti máa yin OLUWA Ọlọrun Israẹli. Asafu ni olórí, àwọn tí ipò wọn tún tẹ̀lé tirẹ̀ ni: Sakaraya, Jeieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Matitaya, Eliabu, Bẹnaya, Obedi Edomu ati Jeieli àwọn tí wọ́n ń ta hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù. Asafu ni ó ń lu aro. Bẹnaya ati Jahasieli, tí wọ́n jẹ́ alufaa, ni wọ́n ń fọn fèrè nígbà gbogbo níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun. Ní ọjọ́ náà, àṣẹ àkọ́kọ́ tí Dafidi pa ni pé kí Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ máa kọ orin ìyìn sí OLUWA.
I. Kro 16:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ OLúWA. Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan. Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan. Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run. Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí OLúWA