I. Kro 16:1-36

I. Kro 16:1-36 Bibeli Mimọ (YBCV)

BẸ̀NI nwọn mu apoti ẹri Ọlọrun wá, nwọn si fi si arin agọ na ti Dafidi pa fun u: nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju Ọlọrun, Nigbati Dafidi si ti pari riru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia tan, o sure fun awọn enia li orukọ Oluwa. O si fi fun gbogbo enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin fun olukulùku iṣu akara kan, ati ekiri ẹran kan, ati akara didùn kan. O si yan ninu awọn ọmọ Lefi lati ma jọsin niwaju apoti ẹri Oluwa, ati lati ṣe iranti, ati lati dupẹ, ati lati yìn Oluwa Ọlọrun Israeli: Asafu ni olori, ati atẹle rẹ̀ ni Sekariah, Jeieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Mattitiah, ati Eliabu, ati Benaiah, ati Obed-Edomu: ati Jeieli pẹlu psalteri ati pẹlu duru; ṣugbọn Asafu li o nlù kimbali kikan; Benaiah pẹlu ati Jahasieli awọn alufa pẹlu ipè nigbagbogbo niwaju apoti ẹri ti majẹmu Ọlọrun. Li ọjọ na ni Dafidi kọ́ fi orin mimọ́ yi le Asafu lọwọ lati dupẹ lọwọ Oluwa. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, ẹ pè orukọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. Ẹ kọrin si i, ẹ kọ́ orin mimọ́ si i, ẹ ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ̀. Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki ọkàn awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀. Ẹ ma wá Oluwa, ati ipa rẹ̀, ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo. Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe, iṣẹ àmi rẹ̀, ati idajọ ẹnu rẹ̀; Ẹnyin iru-ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu ayanfẹ rẹ̀. On ni Oluwa Ọlọrun wa, idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye. Ẹ ma ṣe iranti majẹmu rẹ̀ titi lai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran; Majẹmu ti o ba Abrahamu da, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki; A si tẹnumọ eyi li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye: Wipe, Iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin. Nigbati ẹnyin wà ni kiun ni iye, ani diẹ kiun, ati atipo ninu rẹ̀. Nwọn si nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, ati lati ijọba kan de ọdọ enia miran; On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni ìwọsi, nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn, Wipe, Ẹ má ṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi, ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi. Ẹ kọrin titun si Oluwa gbogbo aiye; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ. Ẹ sọ̀rọ ogo rẹ̀ ninu awọn keferi; ati iṣẹ-iyanu rẹ̀ ninu gbogbo enia. Nitori titobi li Oluwa, o si ni iyìn gidigidi: on li o si ni ibẹ̀ru jù gbogbo oriṣa lọ. Nitori pe gbogbo oriṣa awọn enia, ere ni nwọ́n: ṣugbọn Oluwa li o da awọn ọrun. Ogo on ọlá wà niwaju rẹ̀; agbara ati ayọ̀ mbẹ ni ipò rẹ̀. Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipa fun Oluwa. Ẹ fi ogo fun Oluwa ti o yẹ fun orukọ rẹ̀: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá siwaju rẹ̀: ẹ sin Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́. Ẹ warìri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye, aiye pẹlu si fi idi mulẹ ti kì o fi le yi. Jẹ ki awọn ọrun ki o yọ̀, si jẹ ki inu aiye ki o dùn; si jẹ ki a wi ninu awọn orilẹ-ède pe, Oluwa jọba. Jẹ ki okun ki o ma ho, ati ẹkún rẹ̀: jẹ ki papa-oko tùtu ki o yọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀. Nigbana ni awọn igi igbo yio ma ho niwaju Oluwa, nitori ti o mbọ wá ṣe idajọ aiye. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ki ẹ si wipe, Gbà wa Ọlọrun igbala wa, si gbá wa jọ, ki o si gbà wa lọwọ awọn keferi, ki awa ki o le ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ mimọ́, ki a si le ma ṣogo ninu iyin rẹ. Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli lai ati lailai. Gbogbo awọn enia si wipe, Amin, nwọn si yìn Oluwa.

I. Kro 16:1-36 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun kalẹ̀ ninu àgọ́ tí Dafidi ti tọ́jú sílẹ̀ fún un, wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú Ọlọrun. Nígbà tí Dafidi rú ẹbọ tán, ó súre fún àwọn eniyan ní orúkọ OLUWA, ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, atọkunrin atobinrin, ní burẹdi kọ̀ọ̀kan, ati ègé ẹran yíyan kọ̀ọ̀kan ati àkàrà èso resini. Ó sì yan àwọn ọmọ Lefi kan láti máa ṣe ètò ìsìn níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA: láti máa gbadura, láti máa dúpẹ́, ati láti máa yin OLUWA Ọlọrun Israẹli. Asafu ni olórí, àwọn tí ipò wọn tún tẹ̀lé tirẹ̀ ni: Sakaraya, Jeieli, Ṣemiramotu, Jehieli, Matitaya, Eliabu, Bẹnaya, Obedi Edomu ati Jeieli àwọn tí wọ́n ń ta hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù. Asafu ni ó ń lu aro. Bẹnaya ati Jahasieli, tí wọ́n jẹ́ alufaa, ni wọ́n ń fọn fèrè nígbà gbogbo níwájú Àpótí Majẹmu Ọlọrun. Ní ọjọ́ náà, àṣẹ àkọ́kọ́ tí Dafidi pa ni pé kí Asafu ati àwọn arakunrin rẹ̀ máa kọ orin ìyìn sí OLUWA. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA, ẹ képe orúkọ rẹ̀, ẹ kéde ohun tí ó ti ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn sí i, ẹ sọ nípa àwọn ohun ìyanu tí ó ṣe! Ẹ máa fi orúkọ rẹ̀ ṣògo, kí ọkàn àwọn tí wọn ń sin OLUWA kún fún ayọ̀. OLUWA ni kí ẹ máa tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́, Ẹ máa sìn ín nígbà gbogbo. Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, gbogbo nǹkan ìyanu tí ó ṣe, ati gbogbo ìdájọ́ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀. Òun ni OLUWA Ọlọrun wa, ìdájọ́ rẹ̀ ká gbogbo ayé. Kò ní í gbàgbé majẹmu rẹ̀ títí lae, àní àwọn ohun tí ó ti pa láṣẹ láti ṣe fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran, majẹmu tí ó bá Abrahamu dá, ìlérí tí ó ti ṣe fún Isaaki, tí ó sì ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pẹlu Jakọbu, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ohun tí yóo wà títí lae, ó ní, “Ẹ̀yin ni n óo fún ní ilẹ̀ Kenaani, bí ohun ìní yín, tí ẹ óo jogún.” Nígbà tí wọn kò tíì pọ̀ pupọ, tí wọn kò sì jẹ́ nǹkan, tí wọ́n jẹ́ àjèjì níbẹ̀, tí wọn ń lọ káàkiri láti orílẹ̀-èdè kan dé ekeji, láti ìjọba kan sí òmíràn, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ni wọ́n lára, ó bá àwọn ọba wí nítorí wọn. Ó ní, “Ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan àwọn ẹni àmì òróró mi, ẹ má sì pa àwọn wolii mi lára!” Ẹ kọrin sí OLUWA, gbogbo ayé! Ẹ máa kéde ìgbàlà rẹ̀ lojoojumọ. Ẹ kéde ògo rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan! OLUWA tóbi, ìyìn tọ́ sí i lọpọlọpọ ó sì yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún un ju gbogbo àwọn oriṣa lọ. Nítorí pé ère lásán ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù sọ di ọlọrun, ṣugbọn OLUWA ló dá ọ̀run. Ògo ati agbára yí i ká, ayọ̀ ati ìyìn sì kún Tẹmpili rẹ̀. Ẹ fi ògo fún OLUWA, gbogbo ayé, ẹ gbé ògo ati agbára wọ̀ ọ́! Ẹ fi ògo tí ó yẹ orúkọ OLUWA fún un, ẹ mú ọrẹ wá sí iwájú rẹ̀! Ẹ sin OLUWA pẹlu ẹwà mímọ́, ẹ wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé, ó fi ìdí ayé múlẹ̀ gbọningbọnin kò sì lè yẹ̀ lae. Kí inú ọ̀run kí ó dùn, kí ayé kí ó yọ̀, kí wọ́n sọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè pé “OLUWA jọba!” Kí òkun ati ohun gbogbo tó wà ninu rẹ̀ hó yèè, kí pápá oko búsáyọ̀, ati gbogbo ẹ̀dá tó wà ninu rẹ̀. Àwọn igi igbó yóo kọrin ayọ̀ níwájú OLUWA, nítorí ó wá láti ṣe ìdájọ́ ayé. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA nítorí pé ó ṣeun, ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ sì wà títí lae! Ẹ kígbe pé, “Gbà wá, Ọlọrun, olùgbàlà wa, kó wa jọ, sì gbà wá láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, kí á lè máa dúpẹ́, kí á máa yin orúkọ mímọ́ rẹ, kí á sì máa ṣògo ninu ìyìn rẹ. Ẹni ìyìn ni OLUWA, Ọlọrun Israẹli, lae ati laelae!” Gbogbo àwọn eniyan sì dáhùn pe, “Amin”, wọ́n sì yin OLUWA.

I. Kro 16:1-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wá sínú àgọ́ ti Dafidi ti pèsè fún un, wọ́n sì gbé ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀ kalẹ̀ níwájú Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Dafidi parí ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, ó bùkún àwọn ènìyàn ní orúkọ OLúWA. Nígbà náà ó fún olúkúlùkù ọkùnrin àti obìnrin ọmọ Israẹli ní ìṣù àkàrà kan, àkàrà dídùn ti àkókò kan àti àkàrà dídùn ti èso àjàrà kan. Ó yan díẹ̀ lára àwọn ará Lefi láti máa jọ́sìn níwájú àpótí ẹ̀rí OLúWA, àti láti ṣe ìrántí àti dúpẹ́ àti láti yin OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Asafu ni olóyè, àtẹ̀lé rẹ ni Sekariah, Jehieli, Ṣemiramotu, Asieli, Mattitiah, Eliabu, Benaiah, Obedi-Edomu àti Jeieli, àwọn ni yóò lu ohun èlò orin olókùn àti dùùrù haapu. Asafu ni yóò lu símbálì kíkan. Àti Benaiah àti Jahasieli àwọn àlùfáà ni yóò fọn ìpè nígbà gbogbo níwájú àpótí ẹ̀rí májẹ̀mú ti Ọlọ́run. Ní ọjọ́ náà Dafidi kọ́kọ́ fi lé Asafu àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ orin Dafidi ti ọpẹ́ sí OLúWA: Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nínú àwọn ènìyàn fún ohun tí ó ṣe Ẹ kọrin sí i, ẹ kọrin ìyìn, sí i, Ẹ sọ ti gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ Ìyìn nínú orúkọ rẹ̀ mímọ́; jẹ kí ọkàn àwọn tí ó yin OLúWA kí ó yọ̀. Ẹ wá OLúWA àti agbára rẹ̀; E wá ojú rẹ̀ nígbà gbogbo. Rántí àwọn ìyanu tí Ó ti ṣe, iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àti ìdájọ́ tí Ó ti sọ. A! ẹ̀yin ìran ọmọ Israẹli ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọmọ Jakọbu, ẹ̀yin tí ó ti yàn. Òun ni OLúWA Ọlọ́run wa; ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé. Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé, ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran, májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu, ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki. Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé: “Sí ọ, ni Èmi yóò fún ní ilẹ̀ Kenaani. Gẹ́gẹ́ bí ààyè tí ìwọ yóò jogún.” Nígbà tí wọn kéré ní iye, wọ́n kéré gidigidi, wọ́n sì jẹ́ àlejò níbẹ̀, wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè láti ìjọba kan sí èkejì. Kò gba ọkùnrin kankan láyè láti pọ́n wọn lójú; nítorí tiwọn, ó bá àwọn ọba wí. “Má ṣe fọwọ́ kan àwọn ẹni ààmì òróró mi; Má ṣe pa àwọn wòlíì mi lára.” Kọrin sí OLúWA gbogbo ayé; ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́. Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn. Nítorí títóbi ni OLúWA òun sì ni ìyìn yẹ Jùlọ; òun ni kí a bẹ̀rù ju gbogbo àwọn Ọlọ́run lọ. Nítorí gbogbo àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè jẹ́ àwọn òrìṣà, ṣùgbọ́n OLúWA dá àwọn ọ̀run. Dídán àti ọláńlá ni ó wà níwájú rẹ̀; agbára àti ayọ̀ ni ó wà ní ibi ibùgbé rẹ̀. Fi fún OLúWA, ẹ̀yin ìdílé àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ fi ògo àti ipá fún OLúWA. Fún OLúWA ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀; gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀. Sìn OLúWA nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀. Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé! Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i. Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn; Jẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “OLúWA jẹ ọba!” Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀; Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀! Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin, Wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú OLúWA, nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé. Fi ọpẹ́ fún OLúWA, nítorí tí ó dára; ìfẹ́ ẹ rẹ̀ dúró títí láé. Ké lóhùn rara, “Gbà wá, Ọlọ́run Olùgbàlà a wa; kó wa jọ kí o sì gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, kí àwa kí ó lè fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ, kí àwa kí ó lè yọ̀ nínú ìyìn rẹ̀.” Olùbùkún ni OLúWA, Ọlọ́run Israẹli, láé àti láéláé. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn ènìyàn wí pé “Àmín,” wọ́n sì “Yin OLúWA.”