I. Kro 15:25-29
I. Kro 15:25-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni Dafidi ati awọn agbagba Israeli, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun, lọ lati gbe apoti ẹri majẹmu Oluwa jade ti ile Obed-Edomu gòke wá pẹlu ayọ̀. O si ṣe, nigbati Ọlọrun ràn awọn ọmọ Lefi lọwọ ti o rù apoti ẹri majẹmu Oluwa, ni nwọn fi malu meje ati àgbo meje rubọ. Dafidi si wọ̀ aṣọ igunwa ọ̀gbọ daradara, ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti nrù apoti ẹri na, ati awọn akọrin, ati Kenaniah olori orin pẹlu awọn akọrin: efodu ọ̀gbọ si wà lara Dafidi. Bayi ni gbogbo Israeli gbé apoti ẹri majẹmu Oluwa gòke wá pẹlu iho ayọ̀, ati iró fère, ati pẹlu ipè, ati kimbali, psalteri ati duru si ndún kikankikan. O si ṣe bi apoti ẹri majẹmu Oluwa na ti de ilu Dafidi ni Mikali ọmọ Saulu obinrin yọju wode ni fèrese, o ri Dafidi ọba njó, o si nṣire; o si kẹgan rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.
I. Kro 15:25-29 Yoruba Bible (YCE)
Dafidi ati àwọn àgbààgbà Israẹli ati àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun bá lọ sí ilé Obedi Edomu, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ayọ̀. Nítorí pé Ọlọrun ran àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA lọ́wọ́, wọ́n fi mààlúù meje ati àgbò meje rúbọ. Dafidi ati gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu, ati àwọn akọrin ati Kenanaya, olórí àwọn akọrin wọ aṣọ funfun tí ń dán, Dafidi sì wọ efodu funfun. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli ṣe gbé Àpótí Majẹmu OLUWA pẹlu ìró orin ayọ̀, tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí ohun èlò orin bíi ipè, fèrè, aro, hapu ati dùùrù kọ. Bí wọ́n ti ń gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wọ ìlú Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu yọjú láti ojú fèrèsé, ó rí Dafidi tí ń jó, tí ń fò sókè tayọ̀tayọ̀, ó sì pẹ̀gàn rẹ̀ ninu ara rẹ̀.
I. Kro 15:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn àgbàgbà Israẹli àti àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ láti gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú OLúWA láti ilé Obedi-Edomu, pẹ̀lú inú dídùn. Nítorí Ọlọ́run tì ràn wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Lefi ẹni tí ó gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú OLúWA, akọ màlúù méje pẹ̀lú àgbò méje láti fi ṣé ìrúbọ. Dafidi sì wọ efodu; aṣọ ìgúnwà ọ̀gbọ̀ dáradára, àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ń ru àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn akọrin, àti Kenaniah olórí pẹ̀lú àwọn akọrin. Dafidi sì wọ aṣọ ìgúnwà funfun. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli gbé àpótí ẹ̀rí àti májẹ̀mú OLúWA gòkè wá pẹ̀lú ariwo, pẹ̀lú àyíká ìhó ayọ̀ àti láti fọn fèrè ti ìpè, àti kimbali, àti láti ta ohun èlò orin olókùn àti dùùrù olóhùn gooro. Bí àpótí ẹ̀rí OLúWA ti ń wọ ìlú ńlá Dafidi, Mikali ọmọbìnrin Saulu ń wò láti ojú fèrèsé nígbà tí ó sì rí ọba Dafidi ń jó, ó sì ń ṣe àjọyọ̀, ó sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.