Bẹ̃ni Dafidi ati awọn agbagba Israeli, ati awọn olori ẹgbẹgbẹrun, lọ lati gbe apoti ẹri majẹmu Oluwa jade ti ile Obed-Edomu gòke wá pẹlu ayọ̀. O si ṣe, nigbati Ọlọrun ràn awọn ọmọ Lefi lọwọ ti o rù apoti ẹri majẹmu Oluwa, ni nwọn fi malu meje ati àgbo meje rubọ. Dafidi si wọ̀ aṣọ igunwa ọ̀gbọ daradara, ati gbogbo awọn ọmọ Lefi ti nrù apoti ẹri na, ati awọn akọrin, ati Kenaniah olori orin pẹlu awọn akọrin: efodu ọ̀gbọ si wà lara Dafidi. Bayi ni gbogbo Israeli gbé apoti ẹri majẹmu Oluwa gòke wá pẹlu iho ayọ̀, ati iró fère, ati pẹlu ipè, ati kimbali, psalteri ati duru si ndún kikankikan. O si ṣe bi apoti ẹri majẹmu Oluwa na ti de ilu Dafidi ni Mikali ọmọ Saulu obinrin yọju wode ni fèrese, o ri Dafidi ọba njó, o si nṣire; o si kẹgan rẹ̀ li ọkàn rẹ̀.
Kà I. Kro 15
Feti si I. Kro 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: I. Kro 15:25-29
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò