I. Kro 14:1-17

I. Kro 14:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

HIRAMU ọba Tire si ran onṣẹ si Dafidi, ati igi Kedari, pẹlu awọn ọmọle ati gbẹnagbẹna, lati kọ́le fun u. Dafidi si woye pe, Oluwa ti fi idi on joko li ọba lori Israeli, nitori a gbé ijọba rẹ̀ ga nitori ti awọn enia rẹ̀, Israeli. Dafidi si mu awọn aya si i ni Jerusalemu: Dafidi si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin si i. Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ti o ni ni Jerusalemu; Ṣammua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni, Ati Ibhari, ati Eliṣua, ati Elpaleti, Ati Noga, ati Nefegi, ati Jafia, Ati Eliṣama, ati Beeliada, ati Elifaleti. Nigbati awọn ara Filistia si gbọ́ pe, a fi ororo yan Dafidi li ọba lori gbogbo Israeli, gbogbo awọn ara Filistia gòke lọ iwá Dafidi: Dafidi si gbọ́, o si jade tọ̀ wọn. Awọn ara Filistia si wá, nwọn si tẹ ara wọn ni afonifoji Refaimu. Dafidi si bere lọdọ Ọlọrun wipe, Ki emi ki o gòke tọ awọn ara Filistia lọ? Iwọ o ha fi wọn le mi lọwọ? Oluwa si wi fun u pe, Gòke lọ, emi o si fi wọn le ọ lọwọ. Bẹ̃ni nwọn gòke lọ si Baal-perasimu; Dafidi si kọlù wọn nibẹ. Dafidi si wipe, Ọlọrun ti ti ọwọ mi yà lu awọn ọta mi bi yiya omi: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ na ni Baal-perasimu. Nwọn si fi awọn orisa wọn silẹ nibẹ, Dafidi si wipe, ki a fi iná sun wọn. Awọn ara Filistia si tun tẹ ara wọn kakiri ni afonifoji. Nitorina ni Dafidi tun bère lọwọ Ọlọrun: Ọlọrun si wi fun u pe, Máṣe gòke tọ̀ wọn; yipada kuro lọdọ wọn, ki o si ja lu wọn niwaju igi mulberi. Yio si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lòke igi mulberi, nigbana ni ki iwọ ki o gbogun jade: nitori Ọlọrun jade ṣaju rẹ lọ lati kọlù ogun awọn ara Filistia. Dafidi si ṣe gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun u: nwọn si kọlù ogun awọn ara Filistia lati Gibeoni titi de Gaseri. Okiki Dafidi si kan yi gbogbo ilẹ ka. Oluwa si mu ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o ba gbogbo orilẹ-ède.

I. Kro 14:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Hiramu, ọba Tire kó àwọn òṣìṣẹ́ ranṣẹ sí Dafidi, pẹlu igi kedari ati àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti bá a kọ́ ilé rẹ̀. Dafidi ṣe akiyesi pé Ọlọrun ti fi ìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Israẹli, ati pé Ọlọrun ti gbé ìjọba òun ga nítorí àwọn ọmọ Israẹli eniyan rẹ̀. Dafidi tún fẹ́ àwọn iyawo mìíràn ní Jerusalẹmu, ó sì bí àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin sí i. Àwọn tí ó bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua, Ṣobabu, Natani, ati Solomoni; Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti; Noga, Nefegi, ati Jafia; Eliṣama, Beeliada, ati Elifeleti. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi òróró yan Dafidi lọ́ba lórí Israẹli, gbogbo wọn wá gbógun ti Dafidi. Nígbà tí Dafidi gbọ́, òun náà múra láti lọ gbógun tì wọ́n. Àwọn ará Filistia ti dé sí àfonífojì Refaimu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rú. Dafidi bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní: “Ṣé kí n lọ bá àwọn ará Filistia jà? Ṣé o óo jẹ́ kí n ṣẹgun wọn?” Ọlọrun dá a lóhùn pé, “Lọ bá wọn jà, n óo jẹ́ kí o ṣẹgun wọn.” Dafidi bá lọ kọlù wọ́n ní Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun wọn, ó ní, “Ọlọrun ti lò mí láti kọlu àwọn ọ̀tá mi bí ìkún omi.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu. Àwọn ará Filistia fi oriṣa wọn sílẹ̀ nígbà tí wọn ń sá lọ, Dafidi sì pàṣẹ pé kí wọ́n sun wọ́n níná. Láìpẹ́, àwọn ará Filistia tún wá gbógun ti àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, wọ́n sì kó wọn lẹ́rú. Dafidi bá tún lọ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun. Ọlọrun sì dá a lóhùn pé, “Má ṣe bá wọn jà níhìn-ín, ṣugbọn yípo lọ sẹ́yìn wọn kí o kọlù wọ́n ní òdìkejì àwọn igi balisamu. Nígbà tí o bá ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi balisamu ni kí o kọlù wọ́n, nítorí pé n óo ṣáájú rẹ lọ láti kọlu ogun Filistini.” Dafidi ṣe ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún un, wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Gibeoni títí dé Gasa. Òkìkí Dafidi kàn káàkiri, OLUWA sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ̀ máa ba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

I. Kro 14:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nísinsin yìí Hiramu àti ọba Tire rán oníṣẹ́ sí Dafidi, àti pẹ̀lú igi kedari pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀lé àti gbẹ́nàgbẹ́nà láti kọ́ ààfin fún un. Dafidi sì mọ Israẹli àti pé OLúWA ti fi òun ṣe ọba lórí Israẹli àti pé ìjọba rẹ̀ ga jùlọ nítorí ti àwọn ènìyàn rẹ̀. Ní Jerusalẹmu Dafidi mú ọ̀pọ̀ ìyàwó ó sì di baba àwọn ọmọ ọkùnrin púpọ̀ àti ọmọbìnrin. Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ náà tí wọ́n bí fún un níbẹ̀: Ṣammua, Ṣobabu, Natani, Solomoni, Ibhari, Eliṣua, Elifeleti, Noga, Nefegi, Jafia, Eliṣama, Beeliada, àti Elifeleti. Nígbà tí àwọn ará Filistini gbọ́ pé a ti fi ààmì òróró yàn Dafidi ní ọba lórí gbogbo Israẹli, wọ́n sì lọ sókè pẹ̀lú ipá láti wá a rí, ṣùgbọ́n Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀ ó sì jáde lọ láti pàdé wọn. Nísinsin yìí àwọn ará Filistini ti wá láti gbógun ti Àfonífojì Refaimu; Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run wí pé: “Kí èmi kí ó gòkè tọ àwọn ará Filistini lọ bí? Ìwọ ó ha fi wọ́n lé mi lọ́wọ́?” OLúWA sì wí fún un pé, “Gòkè lọ èmi ó sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gòkè lọ sí Baali-Perasimu, níbẹ̀ ó sì kọlù wọ́n. Ó sí wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí omi tí ya jáde, Ọlọ́run ti ya Dafidi lórí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀lú ọwọ́ mi.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń pè ibẹ̀ ní Baali-Perasimu. Àwọn ará Filistini sì ti fi àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀. Dafidi sì pa á láṣẹ láti jó wọn nínú iná. Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn ará Filistini gbógun wọ́n sì fọ́nká àfonífojì, Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì tún béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run sì dalóhùn pé, Má ṣe gòkè tààrà, ṣùgbọ́n ẹ yí wọn ká kí ẹ sì mú wọn níwájú igi muliberi. Tí ó bá sì ṣe, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ìró ẹsẹ̀ ní orí òkè igi muliberi, ẹ jáde fún ogun, nítorí èyí yóò fihàn pé Ọlọ́run ti jáde níwájú rẹ láti kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe ohun tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì kọlu àwọn ọmọ-ogun Filistini láti gbogbo ọ̀nà Gibeoni lọ sí Geseri. Bẹ́ẹ̀ ni òkìkí Dafidi tàn ká gbogbo ilẹ̀ káàkiri, OLúWA sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè bẹ̀rù rẹ̀.