KRONIKA KINNI 14

14
Akitiyan Dafidi ní Jerusalẹmu
(2Sam 5:11-16)
1Hiramu, ọba Tire kó àwọn òṣìṣẹ́ ranṣẹ sí Dafidi, pẹlu igi kedari ati àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà láti bá a kọ́ ilé rẹ̀. 2Dafidi ṣe akiyesi pé Ọlọrun ti fi ìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Israẹli, ati pé Ọlọrun ti gbé ìjọba òun ga nítorí àwọn ọmọ Israẹli eniyan rẹ̀.
3Dafidi tún fẹ́ àwọn iyawo mìíràn ní Jerusalẹmu, ó sì bí àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin sí i. 4Àwọn tí ó bí ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua, Ṣobabu, Natani, ati Solomoni; 5Ibihari, Eliṣua, ati Elipeleti; 6Noga, Nefegi, ati Jafia; 7Eliṣama, Beeliada, ati Elifeleti.
Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Filistia
(2Sam 5:17-25)
8Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi òróró yan Dafidi lọ́ba lórí Israẹli, gbogbo wọn wá gbógun ti Dafidi. Nígbà tí Dafidi gbọ́, òun náà múra láti lọ gbógun tì wọ́n. 9Àwọn ará Filistia ti dé sí àfonífojì Refaimu, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rú. 10Dafidi bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun, ó ní: “Ṣé kí n lọ bá àwọn ará Filistia jà? Ṣé o óo jẹ́ kí n ṣẹgun wọn?”
Ọlọrun dá a lóhùn pé, “Lọ bá wọn jà, n óo jẹ́ kí o ṣẹgun wọn.”
11Dafidi bá lọ kọlù wọ́n ní Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun wọn, ó ní, “Ọlọrun ti lò mí láti kọlu àwọn ọ̀tá mi bí ìkún omi.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu. 12Àwọn ará Filistia fi oriṣa wọn sílẹ̀ nígbà tí wọn ń sá lọ, Dafidi sì pàṣẹ pé kí wọ́n sun wọ́n níná.
13Láìpẹ́, àwọn ará Filistia tún wá gbógun ti àwọn tí wọ́n wà ní àfonífojì, wọ́n sì kó wọn lẹ́rú. 14Dafidi bá tún lọ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun. Ọlọrun sì dá a lóhùn pé, “Má ṣe bá wọn jà níhìn-ín, ṣugbọn yípo lọ sẹ́yìn wọn kí o kọlù wọ́n ní òdìkejì àwọn igi balisamu. 15Nígbà tí o bá ń gbọ́ ìró ẹsẹ̀ lórí àwọn igi balisamu ni kí o kọlù wọ́n, nítorí pé n óo ṣáájú rẹ lọ láti kọlu ogun Filistini.” 16Dafidi ṣe ohun tí Ọlọrun pa láṣẹ fún un, wọ́n pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Gibeoni títí dé Gasa. 17Òkìkí Dafidi kàn káàkiri, OLUWA sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ̀ máa ba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KINNI 14: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀