I. Kro 13:1-14

I. Kro 13:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

DAFIDI si ba awọn olori ogun ẹgbẹgbẹrun ati ọrọrun ati olukuluku olori gbèro. Dafidi si wi fun gbogbo ijọ Israeli pe, Bi o ba dara loju nyin, bi o ba si ti ọwọ Oluwa Ọlọrun wa wá, jẹ ki a ranṣẹ kiri sọdọ awọn arakunrin wa ni ibi gbogbo, ti o kù ni gbogbo ilẹ Israeli, ati pẹlu wọn si alufa ati awọn ọmọ Lefi ti mbẹ ni ilu agbegbe wọn, ki nwọn ki o le ko ara wọn jọ sọdọ wa: Ẹ jẹ ki a si tun mu apoti ẹri Ọlọrun wa wa si ọdọ wa: nitoriti awa kò ṣafẹri rẹ̀ li ọjọ Saulu. Gbogbo ijọ na si wipe, ẹ jẹ ki a ṣe bẹ̃: nitori ti nkan na tọ loju gbogbo enia. Bẹ̃ni Dafidi ko gbogbo Israeli jọ lati odò Egipti ani titi de Hemati, lati mu apoti ẹri Ọlọrun lati Kirjat-jearimu wá. Dafidi si gòke ati gbogbo Israeli si Baala, si Kirjat-jearimu, ti iṣe ti Juda, lati mu apoti ẹ̀ri Ọlọrun Oluwa gòke lati ibẹ wá, ti ngbe arin Kerubimu, nibiti a npe orukọ Ọlọrun. Nwọn si gbé apoti ẹri Ọlọrun ka kẹkẹ́ titun lati inu ile Abinadabu wá, ati Ussa ati Ahio ntọ́ kẹkẹ́ na. Ati Dafidi ati gbogbo Israeli fi gbogbo agbara wọn ṣire niwaju Ọlọrun, pẹlu orin, ati pẹlu duru, ati pẹlu psalteri, ati pẹlu timbreli, ati pẹlu simbali, ati pẹlu ipè. Nigbati nwọn si de ilẹ ipaka Kidroni, Ussa nà ọwọ rẹ̀ lati di apoti ẹri na mu; nitoriti awọn malu kọsẹ. Ibinu Oluwa si ru si Ussa, o si lù, nibẹ li o si kú niwaju Ọlọrun. Dafidi si binu nitori ti Oluwa ké Ussa kuro: nitorina ni a ṣe pè ibẹ na ni Peres-Ussa titi di oni. Dafidi si bẹ̀ru Ọlọrun li ọjọ na wipe, Emi o ha ṣe mu apoti ẹri Ọlọrun wá sọdọ mi? Bẹ̃ni Dafidi kò mu apoti ẹri na bọ̀ si ọdọ ara rẹ̀ si ilu Dafidi, ṣugbọn o gbé e ya si ile Obed-Edomu ara Gitti. Apoti ẹri Ọlọrun si ba awọn ara ile Obed-Edomu gbe ni ile rẹ̀ li oṣu mẹta. Oluwa si bukún ile Obed-Edomu ati ohun gbogbo ti o ni.

I. Kro 13:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Dafidi jíròrò pẹlu àwọn ọ̀gágun ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati àwọn ti ọgọọgọrun-un, ati gbogbo àwọn olórí. Lẹ́yìn náà ó sọ fún gbogbo ìjọ Israẹli pé, “Bí ó bá dára lójú yín, tí ó sì jẹ́ ìfẹ́ OLUWA Ọlọrun wa, ẹ jẹ́ kí á ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa tí wọ́n ṣẹ́kù ní ilé Israẹli, ati àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ní àwọn ìlú tí wọ́n ní pápá oko, kí wọ́n wá darapọ̀ mọ́ wa. Kí á sì lọ sí ibi tí Àpótí Majẹmu Ọlọrun, tí a ti patì láti ayé Saulu wà, kí á gbé e pada wá sọ́dọ̀ wa.” Gbogbo ìjọ eniyan sì gbà bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó dára lójú wọn. Nítorí náà Dafidi kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti Ṣihori ní Ijipti títí dé ẹnubodè Hamati láti lọ gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun láti Kiriati Jearimu lọ sí Jerusalẹmu. Dafidi ati gbogbo ọmọ Israẹli lọ sí ìlú Baala, tí à ń pè ní Kiriati Jearimu, ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda, wọ́n lọ gbé Àpótí Majẹmu tí à ń fi orúkọ OLUWA pè, OLUWA tí ó jókòó, tí ó fi àwọn Kerubu ṣe ìtẹ́. Wọ́n gbé Àpótí Majẹmu náà jáde láti ilé Abinadabu, wọ́n gbé e lé orí kẹ̀kẹ́ titun. Usa ati Ahio sì ń wa kẹ̀kẹ́ náà. Dafidi ati àwọn eniyan ń fi tagbára-tagbára jó níwájú Ọlọrun, pẹlu orin ati àwọn ohun èlò orin: dùùrù, hapu, ìlù, Kimbali ati fèrè. Bí wọ́n ti dé ibi ìpakà Kidoni, àwọn mààlúù tí wọn ń fa kẹ̀kẹ́ náà kọsẹ̀, Usa bá di Àpótí Majẹmu náà mú kí ó má baà ṣubú. Ṣugbọn inú bí Ọlọrun sí Usa, ó sì lù ú pa, nítorí pé ó fi ọwọ́ kan Àpótí Majẹmu, ó sì kú níwájú Ọlọrun. Inú bí Dafidi nítorí pé Ọlọrun lu Usa pa, láti ọjọ́ náà ni a ti ń pe ibẹ̀ ní Peresi Usa títí di òní. Ẹ̀rù Ọlọrun ba Dafidi ní ọjọ́ náà, ó ní, “Báwo ni mo ṣe lè gbé Àpótí Majẹmu Ọlọrun sọ́dọ̀?” Nítorí náà, Dafidi kò gbé Àpótí Majẹmu sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi, kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbé e yà sí ilé Obedi Edomu, ará Giti. Àpótí Majẹmu Ọlọrun náà wà ní ilé Obedi Edomu yìí fún oṣù mẹta, OLUWA sì bukun ilé Obedi Edomu ati gbogbo ohun tí ó ní.

I. Kro 13:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Dafidi sì gbèrò pẹ̀lú olúkúlùkù àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn aláṣẹ ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn aláṣẹ ọgọ́rùn-ún Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Israẹli pé, Tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ OLúWA Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jíjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tókù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Israẹli àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọ pọ̀ sọ́dọ̀ wa. Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí OLúWA padà sọ́dọ̀ wa, nítorí wí pé àwa kò ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ ní àsìkò ìjọba Saulu. Gbogbo ìjọ náà sì gbà láti ṣe èyí nítorí ó dàbí wí pé ó tọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣihori ní Ejibiti lọ sí Lebo ní ọ̀nà à bá wọ Hamati, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati-Jearimu. Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí Baalahi ti Juda (Kiriati-Jearimu) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run OLúWA tí a fi orúkọ rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrín kérúbù—gòkè wá. Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Abinadabu lórí kẹ̀kẹ́ tuntun, Ussa àti Ahio ń ṣọ́ ọ. Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn, tambori, kimbali pẹ̀lú ìpè. Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Kidoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ síta láti di àpótí ẹ̀rí OLúWA mú, nítorí màlúù kọsẹ̀. Ìbínú OLúWA, sì ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ rẹ̀ lórí àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run. Nígbà náà Dafidi sì bínú nítorí ìbínú OLúWA ké jáde lórí Ussa, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Pereṣi-Uṣa. Dafidi sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì béèrè pé, Báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ mi? Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará rẹ̀ ní ìlú ti Dafidi dípò èyí, ó sì gbé e yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti. Àpótí ẹ̀rí OLúWA sì wà lọ́dọ̀ àwọn ará ilé Obedi-Edomu ní ilé rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, OLúWA sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní.